Former NFF president dies: Ààrẹ NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya jáde láyé lẹ́ni ọdún 73

Oloogbe Domnic Oneya

Oríṣun àwòrán, Google

Ààrẹ ajo ere boolu NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya ti ku lẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin.

Ààrẹ ajọ ere bọọlu nigba kan ri ogagun feyinti Dominic Oneya ti jẹ Olorun nipe bi gbogbo iroyin se n gbe e jade.

Oneya ti a bi ni ọjọ kẹrindilọgbọn, oṣu karun ọdun 1948, a bii ni ilu Agbarho ni Ughellli ni iroyin kan pe o ku ni owurọ ọjọbọ ni ile rẹ ni Effurun nijọba ibilẹ Uvwie nipinlẹ Delta.

Aarẹ NFF lọwọ bayii Amaju Pinnick fi idi rẹ mulẹ fun awọn oniroyin pe lootọ ni Oneya ku.

"Lootọ ni o ti ku" idahun rẹ ree fun awọn oniroyin.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Odun 1999 si 2002 ni Oneya fi jẹ aare NFF.

O ṣíṣẹ́ ni oniruuru aaye ninu igbimọ tẹẹkoto fun CAF ti o si je olori igbimọ ka ti minisita fi lọlẹ lati tun ere bọọlu ṣe ni Naijiria

Bakan naa lo jẹ́ Gomina ologun ipinlẹ Kano laarin ọdun 1996 si 1998.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'
Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..