Pangolin and Elephant tusk siezed: Kí ni ìwúlò Ẹran Akíka àti ìwo Erin tí wọn gbà tó fi lè mọ́ ìjọba Nàìjíríà to yìí?

Àwọn aláṣẹ orileede Naijiria ti kede pé àwọn fofin gba ọpọlọpọ ailonka ẹran ara ẹranko inú igbó, èékánná àti ìwo Erin àti ipẹpẹ ara ẹran Akika.

Wọn gbà àwọn nkan wọnyìí lasiko ti ajọ ẹsọ aṣọ́bodè n ṣe iṣẹ́ òde wọn kiri ní agbègbè ibudo kárakára kan ni Lekki, Ìpínlẹ̀ Eko lẹ́yìn ti èèyàn kan ta wọn lolobo nipa rẹ.

Ọga àgbà ilé isẹ àwọn ẹsọ aṣọ́bodè ni Naijiria, Hammered Ali sọ fún àwọn oniroyin nilu Eko l'Ọjọru pé àwọn rí àwọn nkan naa ti wọn ko pamọ sínú àpò tó fẹrẹ̀ẹ́ tó igba ni kika.

Iroyin náà je wípé wọn fura pé àwọn eeyan kan ló ko o lọ́nà aitọ láti orileede Central Africa Republic tí wọn sì ń ko o lọ sí apá Gúúsù iwọ-Oorun Asia tó wà jẹ pe orileede Naijiria ni ọna ti wọn n gba kọja lọ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Ogbeni Hamed ni àwọn eru náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínlógún kilogram tí iye owó orí wọn sì tó bilionu méjìlélógún.

Ọwọ́ ti wá tẹ èèyàn mẹta fún isẹ fayawọ tí wọn yóò sì tó gbà ọjọ ti wọn ò farahàn nílé ẹjọ́ gẹgẹ bí àjọ ẹsọ aṣọ́bodè ṣe ni àwọn ko ni pá ohunkohun ti lórí ọrọ yìí rárá.

Bákan náà lo ni ileese awọn ń ṣiṣẹ́ pọ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Britain, Germany àtàwọn àjọ agbaye mii láti gbógun ti isẹ fayawọ.

Ó ní irẹpọ yìí gan lọ jẹ ki awọn rí àwọn ẹrù fayawo yìí gbà lágbègbè Lekki, Eko.

Iwo Erin

Oríṣun àwòrán, Nigeria Customs Service

Wọn ni èyí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ kí wọn máa fi Naijiria ṣe ọna pasiparọ Ẹran Akíka lọ sí Asia wọn sì ni ai dáàbò bo ẹnu ibodè dáadáa lọ ń fà èyí.

Kódà, àkọsílẹ̀ àjọ UN náà fihan pe wọn tí fofin gba ipẹpẹ ẹran Akika toonu marunlelẹgbẹsan tí wọn sì ti ní láti pá ẹranko irínwó ó dín ọgbọn. Àjọ UNODC lọ sọ bẹẹ.

Iroyin taa gbó sọ pé ṣe ni wọn máa ń lo irú àwọn ẹran ara báyìí fi ṣe oogun ìbílẹ̀ làwọn orileede ilẹ̀ Asia.

Ìgbàgbọ́ wọn tún ní pe ẹranko Akíka (Pangolin) ni ẹranko tí wọn tí fi ẹ̀mí rẹ wewu ju nínú gbogbo ẹranko lagbaye.

Kí ni o ni lati mọ nípa ẹranko Akíka (Pangolin)?

Akika

Oríṣun àwòrán, others

Ẹran Akíka jẹ ọkan lára àwọn ẹranko to wọ́pọ̀ nilẹ Afirika àti Asia èyí tó jẹ́ pé ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipẹpẹ to p'ọwọ lè ara wọn. Ó ni ori kékeré àti imu ati enu gígùn, wọn tun máa ń ní ahọn bíi gọọmu to lee tètè mu kòkòrò àti ikan bẹẹ si ni wọn ní iru gígùn.

Ipẹpẹ ara Akíka yìí ló bù ju ni gbogbo ara rẹ tí kò ju randu lọ. Kii ni ẹyin, ikùn ni wọn fi ń run oúnjẹ jẹ.

Akíka máa ń lọ ipẹpẹ ara rẹ fún ààbò ara rẹ.

Ọ̀pọ̀ máa ń d'ọdẹ ẹran yìí fún jíjẹ bẹẹ si jí wọn ń loo fi ṣe àwọn oogun ìbílẹ̀, wọn tún ń fi ṣe ọṣọ ara pàápàá ni China àti ní Vietnam.

Bí wọn ṣe sọ pípa àwọn ẹranko Akíka yìí di ọrọ aje tí ń mú a dinku bá agbo ẹranko Akíka.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..
Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún