Igboho Aides Verdict: Afẹnifẹre gbóṣùbà fáwọn Adájọ́ Nàìjíríà lórí ìdájọ́ méjì tó kan Sunday Igboho

Igboho ati aworan afẹnifẹre

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ idagbasoke ọmọ Yoruba ni Naijiria Afenifere ti gboṣuba kaare fun awọn adajọ meji to gbe idajọ kalẹ lori awọn amugbalẹgb Sunday Igboho.

Lọjọru yi ni awọn amugbalẹgbẹ naa gba itusilẹ nile ẹjọ giga Abuja eyi ti adajọ Obiora Egwaatu gbe kalẹ.

Bakan naa ni adajọ Akintola ni ilu Ibadan paṣẹ ki ajọ ọtẹlmuyẹ Naijiria DSS ma ṣe dunkoko mọ Sunday Igboho tabi ki ijọba gbẹsẹ le akoto owo rẹ.

Awọn idajọ mejeeji yi paapa fun awọn alatilẹyin Igboho ati awọn to n ja fun ominira ilẹ Yoruba dabi aṣeyọri nla.

Ninu atẹjade kan ti agbodegba ẹgbẹ naa Comrade Jare Ajayi fi sita, o ni idajọ ti adajọ Oladiran Akintola ati Obiora Egwaatu gbe kalẹ tunbọ ṣafihan ireti wa ninu ẹka idajọ Naijiria''

Jare Ajayi ni idajọ wọn yi waye lasiko tawọn araalu n ro pe ijọba apapọ n gbero lati mu Sunday Igboho to n koju igbẹjọ lọwọ ni Cotonou.

Afẹnifẹre gboriyin fun adajọ Egwaatu to sọ pe dandan ni ki ajọ DSS ko gbogbo awọn amugbalẹgbẹ Igboho wa si ile ẹjọ.

O ni adajọ yi mu ọkan akin pẹlu bo ṣe paṣẹ ki wọn gba beeli wọn ni ibamu plu ofin orileede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Yatọ si ti adajọ to gba beeli awọn amugbalẹgbẹ Igboho,Afẹnifẹre sọ pe idajo mejeeji tawọn ri yi fẹsẹ igbagbọ awọn rinlẹ pe ile ẹjọ nikan laraalu ti le gba idajọ to peye ti wọn ba tẹ oju ẹtọ wọn mọlẹ.

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...