Emir Taraba 30 day Ultimatum: Àwọn olórí Fulani bèèrè àsìkò díẹ̀ síi lórí gbèǹdéke láti lé àwọn ọ̀daràn kúrò nínú igbó

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn olori fulani darandaran ni ipinlẹ Taraba ti rawọ ẹbẹ si Emir ilu Muri to fi gbedeke lelẹ pe ki awọn ọdaran Fulani kuro ninu igbo bibẹ kọ oun yoo foju wọn ri mọbo.
Emir Abbas Tafida sọ lọjọ ọdun ileya pe awọn ọdaran yi ni ọgbọn ọjọ lati kuro ninu igbo lai se bẹ awọn ṣetan lati pa ẹnikẹni to ba sapamọ ninu wọn.
Awọn olori fulani lati ijọba ibilẹ mẹrinla ninu mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ naa lo ṣepade pẹlu Emir yi ni aafin rẹ ni Jalingo lọjọ Iṣẹgun.
- Emir ìlú Taraba fún àwọn Fulani Darandaran ní gbèńdéke ọjọ́ 30 láti kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ òun
- Ojú afurasí oníjìbìtì àti ajínigbé tí Gani Adams pariwo wọn síta l‘Oke Ogun rèé
- Àwọn ọmọ Sunday Igboho mẹ́jọ̀ nínú méjìlá níkan ní DSS gbé wá sí iléẹ̀jọ́ - Agbẹjọrò
- Taní Wolí rẹ̀? Èmí ti jèrè ''Minister''; Woli Joshua Iginla fí ọkọ̀ ńla ta mí lọ́rẹ- Alaseyori tó kọ orin Oniduromi
- Ìjọba Amẹ́ríkà ti kó abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin fún Nàìjíríà
Nibi ipade naa wọn beere fun oṣu marun un dipo ọgbọn ọjọ to fi lelẹ kawọn ọdaran Fulani wọnyi kuro ninu igbo.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Naijiria Punch ṣe jabọ, olori awọn darandaran Fulani ni ipinlẹ naa Alhaji Sahabi Mahmud lo lewaju awọn to lọ rawọ ẹbẹ si Emir naa.
Nibi ipade naa la gbọ pe oludamọran si Gomina Darius Ishaku,ọgagun fẹyinti Angyu Agbu wa ati awọn aṣoju ikọ alaabo miran ni ipinlẹ ọhun.
Ninu atẹjade ti awọn olori Fulani fi sita, wọn ni ''awọn to ba yi iwa pada a o kọ orukọ wọn silẹ,awan to ba si kọ, a o fa wọn le agbofinro lọwọ''
''A ti pinu lati ma se faaye gba awọn ọdaran koda bi wọn ba jẹ ọmọ bibi inu wa.A ti bura lati tu aṣiri wọn ka si fi awọn to n ṣe agbatẹru wọn laibikita ipo wọn lawujọ''
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Rògbòdìyàn yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin Naijiria àti Benin tí wọ́n bá fi Sunday Igboho sílẹ̀ báyìí- Agbẹjọ́rò
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
Emir Tafida lasiko ipade naa sọ pe lati le fi koju awọn ọdaran ni aṣẹ toun pa.
O ni''Gẹgẹ bi olori to duro lori ododo, mi o ni faaye gba aiṣeede ati didaabo bo awọn ọdaran.''
Bi a ko ba gbagbe,ni ogunjọ oṣu Keje tii ṣe ọjọ ọdun Ileya awọn musulumi ni Emir yi fibinu sa pe o to gẹ pẹlu bi awọn ọdaran Fulani ṣe n da awọn eeyan rẹ laamu.
O ni oun fun wọn ni gbedeke ọgbọn ọjọ lati fi inu igbo silẹ bi bẹẹ kọ awan yoo pa ẹnikẹni tawọn ba ba ninu igbo ninu wọn.
- Ṣé lóòtọ́ọ́ láwọn Fulani tún ṣá aráàlú Igangan méjì ládàá nígbà tí wọ́n ń sùn?
- Ẹ̀yin tẹ́ẹ tako àgbékalẹ̀ àgọ́ Fulani, ìkórira ló ń yọ yín lẹ́nu - Ìjọba àpapọ̀
- Àyè wà fún àwọn Fulani tí kíì ṣe ọ̀daràn láti wá fi ilú Iwo ṣebùgbé - Oluwo
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
Emir yi to sọrọ lede Hausa ni awọn faaye gba awọn Fulani darandaran lati wa si ipinlẹ awọn ṣugbọn niṣe ni wọn ji awọn eeyan gbe ti wọn si n fipa ba awọn obinrin lo pọ.
Lẹnu lọọlọ yi, awọn araalu kaakiri Naijiria lo ti n kesi ijọba la ti wa nkan ṣe si awọn ọdaran Fulani to n da wahala silẹ nipa ijingbe,ipaniyan ati awọn iwa ọdaran mi.














