Sunday Igboho: Adájọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ dí Ọjọ́ Kẹrin, oṣù yíì

Sunday Igboho

Adajọ Obiora Egwuatu ti ileẹjọ giga ni ilu Abuja ti sun igbẹjọ si Ọjọ Kẹrin, Osu yii lẹyin ti ajọ DSS ṣafihan awọn olubaṣiṣẹ Igboho mẹjọ ninu mejila ti wọn mu ni ile rẹ lasiko ti wọn ṣe ikọlu si ile Sunday Igboho.

Agbẹjọro awọn ọmọ Sunday Igboho, Pelumi Olajengbesi ni ajọ DSS n tẹ oju ofin mọlẹ pẹlu bi wọn ko ṣe mu awọn mejila naa wa si ile ẹjọ.

Sunday Igboho

Olajengbesi ni orukọ awọn mẹjọ ti wọn ko wa naa ko ba ara wọn mu lasiko ti wọn n pe orukọ wọn ni ileẹjọ lasiko ti Adajo Obiora n ṣe ayẹwọ orukọ wọn.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Iroyin ni wọn ti gba beeli awọn kan, amọ agbẹjọro wọn ni ko si ohun to jọ ọ, ati wi pe eniyan mẹrin ninu wọn ni DSS jẹ ki wọn ri lasiko ti awọn lọ si ihamọ ti wọn wa.

Adajọ Obiora wa paṣẹ fun ikọ DSS lati pada lọ ṣe ifilọlẹ orukọ wọn silẹ daradara, ki wọn si ri pe awọn mejila naa ni wọn ko wa si ileẹjọ ni Ọjọọru, ọṣẹ yii ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.

Sunday Igboho

Ọjọ Kini, Osu Keje ọdun 2021 ni DSS sekọlu si ile Igboho, ti wọn si ko wọn lọ si ahamọ lati igba naa.

Agbẹjọro Olajẹngbesi ni dandan ni ikọ DSS gbọdọ foju wina ofin fun bi wọn ṣe tẹ ẹtọ awọn eniyan Igboho mejila ti wọn mu naa, ati wi pe wọn gbọdọ ko wọn wa si ileẹjọ ni Ọjọ Kẹrin, Osu yii ki igbẹjọ le tẹsiwaju.

Òní lòní ńjẹ́! Adájọ́ dé sí iléẹjọ́ látí gbẹ́jọ̀ àwọn ọmọ Sunday Igboho 12 tó wà ní àhámọ́ DSS

Agbẹjọro awọn mejila ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ko ni ile ajafẹtọ ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ti ni ooni Ọjọ Aje ni adajọ paṣẹ fun ajọ DSS lati pada wa pẹlu awọn mejila to wa ni ahamọ wọn.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Agbẹjọro wọn, Pelumi Olajẹngbesi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni awọn mejila lo wa ni ahamọ DSS, amọ mẹrin ni awọn ri ba sọrọ ninu wọn nitori DSS ko fẹ ki wọn ri gbogbo wọn

Lori ohun ti wọn fẹ ki ileẹjọ ṣe fun wọn, agbẹjọro naa ni awọn fẹ ki ileẹjọ fi awọn mejila naa silẹ nitori DSS ko fi ẹsun kankan kan wọn, ti wọn si ti wọn mọle.

''Labẹ ofin, DSS ko laṣẹ lati ti ẹnikẹni mọlẹ kọja wakati mẹrinlelogun lai gbe wọn lọ si ileẹjọ''

''Amọ DSS ko fi ẹsun kankan kan wọn, wọn si n fi iya jẹ wọn nibi ti wọn fi wọn pamọ si''

''Ọrọ ofin kii ṣe ohun ti DSS le yipada tabi ẹnikẹni le fi ọwọ rọ ṣẹyin''

Bakan naa naa lo fikun pe o da awọn loju pe adajọ yyo gba wọn silẹ ni ahamọ nitori wọn ko fi ẹsun kanakn kan wọn.

Agbejọro Pelumi Olajengbesi ni lẹyin igbẹjọ yii, awn yoo tun gbe DSS lọ si ile ẹjọ lori ẹsun ifiyajẹni ti wọn fi jẹ awọn mejila naa.