BB Naija 2021: Ọkọ olukopa BB Naija, Tega gbéjà ìyàwó rẹ̀ tí ọkùnrin míì nílé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà

Tega

Oríṣun àwòrán, BB Naija

Ọkọ ọkan lára àwọn obìnrin tó ń kopa nílé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ Big Brother Nigeria to ń lọ́wọ́ ti gbe lẹyin iyawo rẹ Tega lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn da ẹnu boo pé ó kopa ninu ère idaraya kan tó ní ṣe pẹlu kí obìnrin àti ọkùnrin máa lọ mọ ara wọn.

Abala eto agbelewo náà tí ọdun yìí ni wón pé àkọlé pàtàkì rẹ ni "Shine yà Eye housemate". Ìyẹn ni pé kí àwọn akopa la ojú wọn dáadáa.

Lalẹ ọjọ Aiku ni gbogbo wọn ti kopa ninu ère idaraya kan tí wọn ṣe àpèjúwe rẹ pẹlu sọ òótọ́ tàbí kí ó dán mi wò. Nínú èyí sì ni Tega tó jẹ́ obìnrin ìyàwó ilé tó kọ́kọ́ kopa ninu eto naa si k'ara bo ere idaraya náà dáadáa.

Nínú eré náà, àfi tí wọn ní kí Sàga, ọkùnrin kan lára wọn fi ẹnu rẹ kan ìdí Tega fún isẹju aaya marun-un, ní ọ̀rọ̀ yìí bá di ranto àti rẹpẹtẹ lórí ayélujára káàkiri ìlú.

Àwọn èèyàn fọn soju òpó Twitter tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ si wa ègúná ọ̀rọ̀ sì Tega lára, tó jẹ́ pé abiyamo, ìyá ọlọmọ kan pé ó ṣe lè kopa ninu irú ère idaraya bẹẹ.

Ọkàn lára ọ̀rọ̀ tí èèyàn kan, @tosteedaniels sọ lórí Twitter tí àwọn oniroyin gbé ní pe "Ṣe ìyàwó ilé sì ni Tega lóòótọ́ ṣá? Ṣé Saga jọ ọmọ rẹ ni tó ń fún un lọyan mú?".

@Onimicee_ ni tirẹ sọ pé "Abi mi ò rii dáadáa ní, ohun tí Saga ṣe sí ìyàwó èèyàn kan, ṣe Tega ti ṣe ìyàwó ṣá?".

Tega ni aaye láti ṣe ìpinnu ohunkóhun tó bá wu ú, àmọ́ ṣe é rí èyí tó ṣe lana yẹn, háà, irọ, irọ ", @ted_thek sọ bẹẹ.

Nigba ti ọkọ rẹ máa dá sí ọrọ náà, pẹlu orúkọ rẹ lórí Instagram, @ajmoney001 fi ọ̀rọ̀ síta pé "Òṣèré ni ìyàwó mi. Tó bá jẹ́ inú ère fún àpẹẹrẹ, yóò ṣe ju ohun tí ẹ rí yẹn lọ. Ẹ jẹ ká gbìyànjú láti máa wò show max, ohun tí mo ń ṣiṣẹ́ fún nìyẹn". Ló bá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé "ẹ tún máa retí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo nifẹ rẹ "baby".

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún