Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Ó wu Olorun lo fi fàmí sínú ìgbàgbọ́- Tunde Bakare ọmọ Lemomu Sani Anibijuwọn nile Kewu.

Gbajugbaja agbẹjọrọ to di ojiṣẹ Olorun ni, Tunde Bakare gba BBC Yoruba lalejo.

O sọrọ nipa irinajo aye rẹ lati igba kekere rẹ ko to di bi o ṣe di yii.

Bakare

Oríṣun àwòrán, @Bakare

Bawo ni irinajo Tunde Bakare se bẹrẹ ni Islam di Onigbagbọ?

Tunde Bakre slaye fun BBC Yoruba pe oun bẹrẹ ile kewu lati ẹni ọdun mẹrin ki oun to ṣe wolimọ lọdun 1967.

O sọ irinajo rẹ lati ibẹrẹ ninu Islam gẹgẹ bi ọmọ ọmọ Lemọmu akọkọ ni Sodeke ni Abeokuta nipinlẹ Ogun.

O salaye nipa bi oun ṣe bẹrẹ iṣẹ fọto yiya ti oun si lọ ya ni ṣọọsi kan ti oun fi ba Jesu pade.

Lẹyin ibapade Jesu yii ni wọn le oun kuro nile ni 1974 ti oun si n sun nile epo ki oun to ri Sọọsi kan maa fori pamọ si.

Bakare

Oríṣun àwòrán, others

Irinajo Bakare, Obasanjo àti Gani Fawehinmi:

Tunde Bakare sọ nipa bi oun ṣe jiṣẹ jiya lẹyin ti oun gba Jesu ti oun n ṣe iṣẹ agbafọ kaakiri Adugbo ki Oba Oke to gbọ adura ré.

O ni lẹyin eyi ni oun di osisẹ banki ti oun fi lọ ka iwe si i di Amofin pẹlu iranlọwọ awọn eeyan kan.

Omọ Sanni Bakre Anibijuwon nile Kewu ni oun tun fọ abọ nile itura lalẹ ti o n ṣiṣẹ ni ọdọ ajijangbara Gani Fawehinmi ogbontarigi Amofin lọsan.

Bakare ni nitori pe Olusegun Obasanjọ gba Sunday lọwọ wọn to gbe Satide le wọn lọwọ lo jẹ ki araba oun lọ tunra mu.

Tunde Bakare fa aaya fun BBC Yoruba, o sọ bi oun ṣe pada lu aluyọ ninu iṣẹ agbẹjọrọ ki Oluwa to pe e si iṣẹ rẹ ni kikun.

O mẹnuba ipenija ṣiṣẹ iṣẹ Oluwa ni kikun laifi nakn mii kun un.

O ni: Iyawo mi ni 'lawyer'ni oun fé kii ṣe 'Pastor'lẹyin ti Oluwa pe mi, iya mi bu sẹkun ni.

Bakare dupẹ ibi ti Olouwa sin in de bayii pẹlu igbagbọ lori ọjọ iwaju rẹ,

Ẹ̀yin ọdọ, ẹ fi ara yin jin fun Oluwa, ẹ tẹpa mọṣẹ, ẹ ma ṣe ọlẹ. ọjọ iwjau yin a dara nitori ibẹrẹ kọ ni oniṣẹ.