Hushpuppi vs Abba Kyari: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò Ọlọpaa, Abba Kyari tí wọn kó pò mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?

Hushpuppi and Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ramoni Igbalode "Hushpuppi" Abbas ati Abba Kyari si n tesiwaju ninu igbejo wọn lori ẹ̀sùn jìbìtì ati jiji owo ilu ti wọn fi kan Hushpuppi to si ti lọọ mo Oga Ọlọpaa, Abba Kyari ati awọn eekan mii ni Naijiria léṣe.

Bẹẹ si ni ileesẹ Olopaa Naijiria ti kan lu agbami iwadii ti wọn n se lori ki lo pa Ọ̀gá agba kan lara wọn pọ pẹ̀lú afurasi ọ̀daràn ti orileede Amerika gba mu.

Si eyi, ọ̀pọ̀ lo ti n beere pe ki ni yoo teyin iwadii wọn jade paapaa bi wọn ba rii pe Abba Kyari jẹbi ẹ̀sùn ti won fi kan an.

Eyi si lo mu ki ileese iroyin BBC kan si osisefeyinti Komisona Olopaa Muhammad Wakil lati ṣàlàyé Ohun ti yoo sẹlẹ ni Ilana òfin ileese Olopaa Naijiria.

Wakil to feyinti lodun to koja lẹ́yìn to je Komisona Olopaa ipinle Kano sọ pe esi ti iwadii olofintoto wọn ba gbe jade ni yoo sọ ohun ti yoo sẹlẹ si Abba Kyari.

"Bi iwadii ko ba sọ pe o jebi, yoo kan tesiwaju isẹ rẹ ni àmọ́ bi wọn ba rii pe o jebi, ìjìyà rẹ náà yoo da lori bi ẹsẹ rẹ bá ṣe po si.

Fún àpẹẹrẹ, ó ní àwọn ẹsẹ kan to jẹ pe idaduro lẹ́nu isẹ janto ni, àwọn míì, ifeyinti tipa-tipa, omii, ijawale kúrò ní ipò gíga àtàwọn míì tó jẹ́ pé óò ní gba igbega lenu isẹ nígbà tó bá yẹ. Torí náà gbogbo ohun tó wà lókè yìí ló seese.

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, Other

Ọjọgbọn kan, Usman Zannuraini jẹ Ọjọgbọn ni Fáṣítì Bayero ti Kano ó sì sọ fún BBC pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdéhùn gbígbé èèyàn wa lati orileede kan si omii láti wá jẹjọ wa laarin Naijiria ati Amẹ́ríkà, igbese tí ileese Ọlọpaa wọn lóhùn yóò gbé kí wọn tó lè rí Abba Kyari gbé lọ yóò gùn gbọọna gbọọna.

"Kii se nkan tó rọrùn láti dédé fi òfin gbé eeyan lọ sí orileede míì lọ jẹjọ torí ọrọ ilẹ̀ ẹjọ́ yóò wà nibẹ awọn sì ni yóò padà sọ bóyá yóò lè sẹlẹ tàbí kó ni sẹlẹ pẹlu dídá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀.

Bawo ni gbogbo ọ̀rọ̀ Abba Kyari/Hushpuppi ṣe bẹ̀rẹ̀?

Gbajugba orí Instagram to je ọmọ Naijiria, Ramon Abass tí ọ̀pọ̀ mọ sì Hushpuppi bèbè pé òun kò jebi esun kejì nínú gbogbo èyí ti wọn fi kan an ni ile ejo Amerika èyí tó ní ṣe pelu Jìjì owó.

Lára ohun tó tún wà nínú ìwé aridaju ẹri tó wà níwájú ilé ejò ni pé Abbas fún Oga Olopaa Naijiria kan ni owo abetele. Ló bá di wí pé Igbakeji Oga Olopaa Abba Kyari ni.

Ní báyìí pelu bí ejò ṣe ń lọ, ó seese kí Hushpuppi fi ẹ̀wọ̀n ogún ọdún gbàrà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìwé ilé ẹjọ́.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ohun tó jẹ́ kí ọwọ́ àwọn agbófinró tètè tẹ Hushpuppi rèé - Mompha

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, hushpuppi

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi onijibiti ori ayelujara, Abbas Ramoni Igbalode, ti ọpọ mọ si Huspuppi.

Afurasi naa si ti jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe ohun ti wọn fi ẹsun rẹ kan oun.

Ṣugbọn lati igba ti Hushpuppi ti dero atimọle ni awọn eeyan ti bẹrẹ si n sọrọ si awọn eeyan kan ti wọn ti ri pẹlu afurasi naa ri.

Lara awọn eeyan naa ni Daddy Freez, Mompha, Dino Melaye, atawọn gbajumọ mii ni Naijiria.

Wayi o, Ismail Mustapha ti ọpọ mọ si Mompha ti ṣalaye ohun to jẹ ki ọwọ tẹ Hushpuppi ninu iwoye tirẹ.

Mompha ni agidi ọkan Hushapuppi lo jẹ ki aṣiri rẹ tete tu sita pe iṣẹ gbajuaẹ ori ayelujara lo fi n ṣọla.

Mompha lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu Daddy Freez loju opo Instagram rẹ.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

O ni "Ohun to ṣakoba fun Hushpuppi ni pe kii gbọ imọran."

Agidi ọkan rẹ lo ṣakoba fun nitori bo ṣe kọ eti ikun si gbogbo imọran ti mo fun un."

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, hushpuppi

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ṣeeṣẹ ki ọwọ ma tii tẹ Hushpuppi to ba jẹ pe o tẹti si awọn imọran ti oun maa n fun.

Mompha sọ siwaju si pe ọpọ eeyan lo pe ẹrọ ilewọ oun lọjọ ti FBI fi ṣikun ofin mu afurasi ọhun pe oun loun ṣe akoba fun.

O tẹsiwaju si pe oun yọ aworan oun oun kuro loju opo ibaraẹni dọrẹ oun lẹyin ti wọn mu Hushpuppi tan, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC lo ni ki oun da awọran naa pada ko ma baa jọ bi pe ara n ti oun.

Ni ti ohun to pa M<ompha ati EFCC pọ, o ni "Ẹni kan lo ro pe oun le fiya jẹ eeyan nla bii iru mi lo jẹ ko bẹ EFCC lọwẹ lori ọrọ mi."

Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb

"Kii ṣe ẹbi mi pe mo jade lati ile ọlọrọ, ṣugbọn ti eeyan ba ti le fi ọla rẹ han lori ayelujara bayii awọn ọmọ Naijiria yoo ni iṣẹ gbajuẹ ni irufẹ ẹni bẹẹ n ṣe."

Oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni wọn fi ṣikun ofin mu Hushpuppi nilẹ United Arab Emirates pẹlu awọn afurasi mọkanla mii lori ẹsun to jọ mọ lilu jibiti ori ayelujara.