Abba Kyari: Ẹ jáwé lọrọ́ọ́kún nílé fún Abba Kyari torí ẹ̀sùn tó fi ba Naijiria lórúkọ jẹ́ ní wọ́n fí kàn án - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abba Kyari
Apapọ awọn agbẹjọro lorilẹede Naijiria ti kesi ọga ọlọpaa lorilẹede naa lati jẹ ki Abba Kyari lo rọkun nile fun igba diẹ titi iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti orilẹede Amerika fi kan an.
Ọkan lara awọn agbẹjọro naa, Pelumi Olajengbesi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ẹsun kekere kọ ni wọn fi kan Abba Kyari.
Ọlajengbesi ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ko gbọdọ fi ọrọ naa ṣere rara nitori yoo tunbọ ba orukọ Naijiria jẹ si, ti wọn ko ba mura si ọrọ naa ni kiakia.
- Àwọn ohun mẹ́rin tó yẹ kí ẹ ko mọ nípa Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- Ẹ wo Ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta míì tí FBI Amẹ́ríkà tún ti mú báyìí tó ń bá Hushpuppi ṣiṣẹ́ òlè àgbáyé tó ń jà
- 'Ẹ yọ Ọgá Ọlọ́pàá Abba Kyari tí US fẹ̀sùn kàn lórí ọ̀rọ̀ Hushpuppi kúrò nípò kíá!'
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
Wọn rọ ọga ọlọpaa lati tu aṣiri gbogbo nkan to ṣokunkun si awọn ọmọ Naijiria, ki wọn si jẹ ki gbogbo aye ri.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abba Kyari
Ọlajengbesi ni awọn agbẹjọro lo ko ara wọn jọ ti wọn woye pe ki Abba Kyari lọ sinmi ni ile fun saa diẹ titi iwadii yoo fi pari lori iwadii naa.
''Awọn ẹsun ti wọn fi kan an lagbara nitori ẹsun ibanijẹ to le ba orukọ Naijiria jẹ ni wọn fi kan an.
''Nitori naa,a ko le jẹ ko ba orukọ Naijiria jẹ si''
- Ìròyìn Yàjóyàjó - Ṣé lóòtọ̀ ni gbajúgbajà òṣèré, Racheal Oniga ti jáde láyé?
- Èyí ni àlàyé lórí ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín
- 'Hàá, irú ikú tí ọmọ mí kú kò tọ́ síi, aláànú mí ní'
- Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu
- Ìrètí Nàìjíríà bọ́ sómi! Ògùn olóró líló mú kí AIU lé Blessing Okagbare kúrò ní Tokyo 2020 Olympics
- Kí ni àwọn ẹ̀sun tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna tún gbé dìde tako Ibrahim El-zakzaky?
- Ikú Tope AjogbaJesu, ohun tí a mọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ nìyí
- 'Lábẹ́ òfin àjọ ECOWAS, kó ṣééṣe kí Benin Republic jọ́wọ́ Sunday Igboho fún Nàìjíríà'
Bakan naa ni iroyin gbe e pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI ti ṣepade pẹlu ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti wọn si beere fun pe ki wọn jẹ ki Abba Kyari wa si orilẹede Amẹrika lati wa jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ni ibaṣepọ pẹlu Hushpuppi pẹlu atẹjisẹ laarin wọn, eleyii to fihan pe o ṣeeṣẹ ko mọ nipa iṣẹ jibiti ti Hushpuppi n ṣẹ.
'Ẹ yọ Ọgá Ọlọ́pàá Abba Kyari tí US fẹ̀sùn kàn lórí ọ̀rọ̀ Hushpuppi kúrò nípò kíá!'
Abba Kyari ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, nitori lootọ ni Hushpuppi kan si oun amọ gbogbo ibaṣepọ awọn lori iṣẹ ni.
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ti kesi Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria lati jọwọ Abba Kyari fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Amẹrika, FBI lati ṣewadii rẹ finifini.

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi
Eyi ko ṣẹyin bi FBI se gbe orukọ Abba Kyari jade gẹgẹ bi awọn ti yoo fi oju wina ofin lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan Hushpuppi lorilẹede Amerika.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ati awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si ni sọrọ lẹyin ti iroyin naa jade be alabaṣiṣẹpọ Hushpuppi ni Abba Kyari, ti yoo si jọju si ileẹjọ.
Amọ Abba Kyari ni irọ ni ẹsun naa patapata.
Adari eto iroyin fun ẹka idajọ lorilẹede Amẹrika, Thom Mrodek ni lootọ ni awọn pe fun ifi panpẹ mu Abba Kyari ati awọn meji miran ti wọn ran Hushpuppi lọwọ ninu iṣẹ jibiti to n ṣe.
- 'Lábẹ́ òfin àjọ ECOWAS, kó ṣééṣe kí Benin Republic jọ́wọ́ Sunday Igboho fún Nàìjíríà'
- Ẹ wo Ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta míì tí FBI Amẹ́ríkà tún ti mú báyìí tó ń bá Hushpuppi ṣiṣẹ́ òlè àgbáyé tó ń jà
- 'Ẹgbẹ́ APC ẹ funra, "Oríyọmí" lásán ni Akeredolu fí na Jegede mọ́lẹ̀ ní iléẹjó tó gajù lọ'
- Evangelist/Dókítà/Oníròyìn Kemi Olunloyo sọ nípa ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun, ESABO, Jide Kosoko àti Iyabo Ojo
- Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle
Ẹgbẹ oselu PDP ni ki ijọba Buhari ma fi ọrọ naa pamọ nitori ibaṣepọ to wa laarin Abba Kyari ati awọn adari ni ẹgbẹ oṣelu APC.
''Ti wọn ko ba mojuto ọrọ Kyari ri, yoo ta epo si ala ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ati ni agbaye.''
''Ẹgbẹ oṣelu PDP wa rọ aarẹ Buhari lati kesi Ọga Agba Ọlọpaa ki wọn fi ọrọ wa Abba Kyari lẹnu wo, ti o ba jẹbi ẹsun naa, ki wọn fi ṣọwọ si Ajọ FBI.''
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria fi atẹjade sita pe awọn n ṣewadii ẹsun ti FBI fi kan Abba Kyari lọwọ.
Kini awọn ọmọ Naijiria nsọ lori ẹsun Abba Kyari ati Hushpuppi
Ero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọtọ lati igba ti iroyin ti jade be Abba Kyari niiṣe pẹlu ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ti wọn fi kan Hushpuppi.
Awọn miran n sọ wi pe igbesẹ nla ti yoo fi idi otitọ mulẹ ni bi FBI ṣe pe fun ki wọn fi panpẹ mu Abba Kyari, amọ awọn miran ni Abba Kyari ti ṣiṣẹ takuntakun gẹgẹ bi ọtẹlẹmuyẹ nitori naa ki wọn ṣewadii ẹsun naa daadaa.
Lara awọn ti wọn sọrọ naa ni Femi Fani Kayode to jẹ minisita fun ọrọ irinna ofurufu tẹlẹ ni Naijiria, to ni pe Abba Kyari jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa ti oun gboriyin fun ni Naijiria, nitori naa oun ko gba ẹsun naa gbọ afi ti wọn ba fi idi iroyin naa mulẹ.
Abba Kyari ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun,nitori lootọ ni Hushpuppi kan si oun amọ gbogbo ibaṣepọ awọn lori iṣẹ ni.
Wo nkan to yẹ ki ẹ mọ nipa Abba Kyari

•DCP Abba Kyari wa lati ẹya Kanuri ni ipinḷ Borno, to wa ni Ila Ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si bi ni Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹta, Ọdun 1975.
•Ọga Abba Kyari ka iwe gba oye ninu imọ Geography ko to di pe o darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria gẹgẹ bi Cadet ni ọdun 2000 ḷyin to kuro ni ileẹkọ awọn ọlọpaa, Police Academy ni Wudil, ni ipinlẹ Kano.
•Ọkan lara awọn iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to ṣe ti okiki rẹ fi kan ni bi o ṣe fi panpẹ ọlọpaa mu ogbontagiri ole, ti wọn pe orukọ rẹ ni Ndagi, ti inagijẹ rẹ si n jẹ Spirit.
•Spirit lo ti ko ilu Numan ni papamọra ni ipinlẸ Anambra fun ọpọlọpọ ọdun, ki ọwọ to tẹ ẹ.
•Ọdun 2005 lo darapọ mọ awọn ọlopaa ko gbere gbe, ti wọn si gbe wa si ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni ipinlẹ Eko.
•Kyari ni ọga ọlọpaa keji ninu awọn adari awọn ọlọpaa kogberegbe Special Anti-Robbery Squad (SARS) - to n gbogun ti iwa ijinigbe, ipaniyan, awọn ẹlẹgbẹ okunkun to fi mọ awọn ọdaran lori ẹrọ ayelujara.
•Amọ ọdun 2020 ni wọn tu SARS ka lori ẹsun ipaniyan ati fifi ẹtọ awọn ọmo Naijiria dun wọn paapaa awọn afurasi.
•Ọdun marun un lo fi wa pẹlu SARS ki wọn to tuwọnka.
•G̣ẹgẹ bi otẹlẹmuyẹ, o ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ moriwu lorilẹede Naijiria ati ni oke okun fun iṣẹ takuntakun to ṣe ni ẹka ọlọpaa.
A ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹsun ti US fi kan Abba Kyari, Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti pàṣẹ
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹsùn ti àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ ilẹ̀ Amerika (FBI) fi kan ọ̀kàn nínú òṣìṣẹ́ àwọn DCP Abba Kyari.
Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde ti agbẹnusọ ọlọ́pàá Nàìjíríà fi síta, Frank Mba lo ti ṣàlàyé pé, ọ̀gá àgbà pàtàpátá fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá (IGP) Usman Alkali Baba ti ní kí wọ́n ṣe àtúgbéyẹwo ẹ̀sùn.
Bákan náà ni àtẹjade naa fi kun pé ilé iṣẹ́ ọlọ́paàá Nàìjíríà ṣetán láti lépa ìdájọ́ òdodo àti láti mu ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́ran wà láàrín FBI àti àwọn alábáṣepọ̀ mííràn lókè òkun.
Àtẹ̀jáde yìí wá lẹ́yìn ti éka ìdájọ́ lórílẹ̀ -èdè Amẹrika pàṣẹ ki wọn mú ìgbákeji kọ́mísọnà ọlọ́pàá ni Nàìjírià Abba Kyari.
Adarí ètò ìròyìn ní ẹka ìdájọ́ US Thom Mrozek to fidi aṣẹ gbígbé Abba Kyari fun BBC sọ pé àwọn ti ránṣẹ pé kí wọ́n fi ọwọ́ òfin mú àwọn ọ̀daran méjì tí ó kù tí wọ́n ran Ramon Abass lọ́wọ́ núnú ìwà jìbìtì tó ń hù.
Wọ́n ni àwọn gbàgbọ́ pé ilẹ̀ Afíríkà ni wọ́n wà.
Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyi ń jẹyọ lẹ́yìn ti Hushpuppi ṣe àdéhùn pé òun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn méjì ti ilé ẹjọ́ US fi kan .
Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n fi ẹsùn náà kan gẹ́gẹ́ bi ẹni to lọ́wọ́ níbẹ̀ ni, igbákeji Komisọna ọlọpaa tótún jẹ́ ọ̀gá IRT gbogbo ọlọ́pàá.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gá ẹka ìròyìn náà ni òun ko ti le sọ bóya orílẹ̀-èdè Amẹríka ṣetan láti wá gbé Abba Krari ni Nàìjíríà bi o ṣe jẹ́ pé Washington ni wọ́n ti ń ṣe ẹjọ́.
Ẹ̀wẹ̀, lójú òpó Facebook ọ̀gá Abba Kyari lo ti kọ síbẹ̀ pé òun kò mọ nǹkan nípa ìlujìbìtì mílíọ̀nù kan dọ́là ti Hushpuppi ń koju lorilede Amerika, àti pé funfun nẹnẹ ni ọwọ́ òun mọ́.


















