Indian girl killed: Bí àwọn ẹbí ọmọdébìnrin yìí ṣe nàá títí tó fi gbé ẹ̀mí mì

Neha Paswan

Oríṣun àwòrán, Rajesh arya

Iya ọmọbinrin naa, Shakuntala Devi Paswan sọ fun ileeṣẹ BBC pe wọn na ọmọbinrin ọhun lẹyin ti awuyewuye waye lori aṣọ to wọ lati ṣe isin.

Iroyin bi awọn mọlẹbi ni orilẹede indian ṣe n fiya jẹ awọn ara ile wọn ti gba ori gbogbo iwe iroyin kan lẹnu ọjọ mẹta yii.

Iroyin naa ti jẹ ki awọn eniyan ri bi awọn ọmọdebinrin ṣe n jiya laarin ẹbi wọn.

Ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin ni awọn ẹbi kan ni Ariwa ilu Uttar Pradesh, lorilẹede India na arabinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun,Neha titi to fi gbe ẹmi mi nitori o wọ ṣokoto.

Iya ọmọbinrin naa, Shakuntala Devi Paswan sọ fun ileeṣẹ BBC pe wọn na ọmọbinrin naa lẹyin ti awuyewuye waye lori aṣọ to wọ lati ṣe isin.

Àkọlé fídíò, 'N10 la ṣì ń ta Ọṣẹ Aboke látayédáyé! Òòṣà ni àrùn ìgbóná, gbogbo yín lẹ sì níi lára, èèwọ̀ rẹ̀ rèé o'

''Ati owurọ ni ọmọ naa ti n gba awẹ, to si di irọlẹ to wọ ṣokoto Jeans ati ẹwu lati ṣe irubọ. Amọ nigba ti awọn iya ati baba agba ri i, won koro oju si aṣọ to wọ, amọ Neha ni aṣọ naa wa fun wiwọ ni, ti ko si si ẹni to le ni ki oun bọ aṣọ naa.''

''Ọrọ naa da ija, ti o si da wahala silẹ lẹyin ti ọmọ naa sun silẹ gbalaja, ki awọn ẹbi to gbe lọ si ileewosan''

''Wọn ko gba ki n tẹle ọmọ mi,ti mo si ran awọn mọlẹbi mi lọ si ileewosan, amọ wọn ko ri nibẹ.''

Shakuntala Devi

Oríṣun àwòrán, Rajesh arya

Àkọlé àwòrán, Shakuntala Devi (right) still dey try to make sense of why dem kill her daughter

Ni ọjọ keji ni wọn ri oku ọdọbinrin kan nibi to so rọ si ni ẹgbẹ omi ni ilu naa, ti wọn si ri pe Neha ni.

Iya ọmọ naa ni ko ye oun idi ti wọn fi pa ọmọ oun, amọ igba akọkọ kọ ni yii ti wọn ti n fi tipatipa mu omo naa lati ma a wọ aṣọ ibilẹ ilẹ India.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi panpẹ ọba mu lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan, ti wọn si n wa awọn to ku.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -