Oluwo Olakunle Deeper Life Herbalist: Ìyá mi àtàwọn Pásítọ ṣe “deliverance” fún mi, kò ràn an, wọ́n padà kọ̀ mí l'ọ́mọ torí ifá
"Mo maa n mọ lara mi pe ẹmi mii (Eṣu) maa n ba le mi ti mo ba wa n'ile ifa".
Inu ẹsin igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi koda inu ijọ Deeper Life ni wọn bi Oluwo Olakunle si amọ to sọ irinajo rẹ wọ inu didi Onifa ati ogbontarigi Babalawo fun BBC Yoruba.
"Mo ti ba Eṣu rin, mo ti ba Eṣu jẹ, mo ti ba Eṣu mu, mo si rii wipe olootọ aye yii ni Eṣu. Kò sí ọrọ tí wọn ń sọ ní Ṣọọṣì tó ń wọ etí mi mọ, mo kàn lọ sí ilé ìjọsìn torí àwọn òbí mi ni".
- Àwọn tó ní "passport" orílẹ̀èdè mìí, Igboho àti Kanu ló fẹ́ da Nàìjíríà rú, ẹ má tẹ̀lé wọn o! - Kemi Olunloyo
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Wọ́n tí lọ́ ẹ̀sùn míì mọ́ Sunday Igboho lẹ́sẹ̀ ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Ẹ gbé Sunday Igboho kúrò láhàmọ́ ọlọ́pàá wá sí ibi ìpamọ́ mìí ní Cotonou títí tí... - Adájọ́
- Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Benin níbi ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho nìyí
- Wo àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó Sunday Igboho ní Cotonou
- Kí ló mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fẹ́ kí adájọ́ fòfin de Yomi Fabiyi nílé ẹjọ́?
- Àwọn olùwọ́de 48 Yoruba Nation dèrò ilé-ẹjọ́ tórí a ká ìbọn àti àkéé mọ́ wọn lọ́wọ́- Ọlọ́pàá
- Mo fi sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mecca àti Medina búra pé Sunday Igboho kò sí nínú ewu níbí - Èèyan Igboho ní Cotonou
Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni Babalwawo to mọ iṣẹ doju rẹ doju ami yii bo tilẹ jẹ pe o sọ fun wa pe awọn obi oun jẹ ọmọ ijọ onigbagbọ Deeper Life pọnbele ti wọn n ṣe ẹsin igbagbọ tọkantọkan.
Ki wa lo de, ba wo lo ṣe rin in to gbe igba Babalawo sori?
Oluwo Olawole Olakunle ni awọn ẹlẹsin ifa kan lo jẹ iwuri fun oun ti ẹsin naa fi wu u. Wọn n gbe lẹgbẹ ile wọn.
"Mi ò kí ń ṣe Oníṣègùn, ògbólógbòó Babaláwo akẹyọ ni mí, Onífá ni mí, Ẹlẹbọ ni mí".
Oluwo yii ni awọn obi oun kọ oun lọmọ nigba to yan ọna ẹsin ifa. O ni ipa ati erongba oun gẹgẹ bi ọdọ Babalawo ni lati ran awọn ọdọ atawọn iran to ṣẹṣẹ n bọ lati pada si ọna ipilẹ aṣa ati iṣẹṣe awọn baba nla baba wọn gẹgẹ bi ọmọ Afirika.
O ni iṣẹ Babalawo jẹ eyi to bu iyi kun eeyan to wuu ki gbogbo eeyan koda to fi mọ awọn obi oun mọ ki wọn si gba eyi gbọ lọjọ kan.



