Bethel Baptist Kidnap Rev. Israel Akanji: Àdúrà wa láì sinmi ló dá sí títú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Bethel Baptist nígbèkùn ajínígbé

Orílẹ̀-èdè 146 ló ń gba àdúrà fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Bethel Baptist nígbèkùn ajínígbé- Ààrẹ Baptist

Oríṣun àwòrán, NIGERIA BAPTIST CONVENTION

Ààrẹ apapọ ijọ Onitẹbomi ni Naijiria (Nigeria Baptist Convention), Israel Akanji ni ìjọ Baptist jákejádò orílẹ̀-èdè mẹ́rìndíláàdọ́jọ ló ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ tí àwọn ajínígbé jí lásìkò tí wọ́n wà ni ìgbèkùn.

Ààrẹ náà ní àdúrà láì simi yìí ló ṣe àwárí àwọn èyí tó padà wálé.

Akanji sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòtọ́ ni àwọn ń gbé òunjẹ lọ fun wọ́n ní àwọn ibi ti wọ́n bá pa láṣẹ pé kí àwọn gbé òunjẹ wá gẹ́gẹ́ bí wọ́n ba ṣe paa láṣẹ.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

O ní ìjọ Baptist kò san owó ìtúsílẹ̀ gún àwọn ajínigbé sùgbọ́n òun kò le sọ nǹkan ti àwọn òbí àti àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kan ṣe.

Ọmọ mọkanlélọ́gọ́fà ni wọ́n jí gbé lóòtọ́ ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n tú àwọn méjìdílọ́gbọ̀n kalẹ̀, wọ́n tún padà fí àwọn mẹ́rìn mííràn sílẹ̀.

"Gbogbo ọmọ tí a ti ri báyìí ti pé méjìdínlógójì nítorí yàtọ̀ sí àwọn ọmọ yìí a tún rí àwọn ènìyàn mẹ́rin mííràn tí wọ́n fi sílẹ̀.

Ní báyìí ó ku ọmọ mẹ́tàlélọ́gọ́rin ló kù láhàmọ̀ àwọn ajínigbé"A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pe kò sí ọmọ tí wọ́n fi ipá bá lòpọ̀ nínú wọn nítorí pé olórí wọn ti kìlọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan énikẹni ninu àwọn ọmọ náà.Ẹ̀wẹ̀, ààrẹ náà ní láti ọjọ́ tí wọ́n ti jí àwọn ọmọ náà gbé, wọn kò wẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò pààrọ̀ asọ wọn, bákan náà ni wọ́n gbàwọn laáyè láti máa ṣe ìpàdé àdúrà wọn láràrọ́ọ̀.

A sì ń kó ìròyìn yìí jọ lọ́wọ́