Kaduna Bethel Baptist School Kidnap: Ìjọ Onítẹ̀bọmi gbé ìgbésẹ̀ ní ti ẹ̀mí fáwọn ọmọ tí wọ́n jígbé

Oríṣun àwòrán, AFP
Lẹyin ikọlu ti wọn ti ji awọn akẹkọ mọkànlélọ́gọ́fà ni ile ẹkọ Baptist High School ipinlẹ Kaduna, ẹgbẹ awọn oludari ati ọmọ ijọ Onitẹbọmi (Baptist Convention) ti ni awọn n ṣeto lati ṣe ipade adura ni gbogbo ijọ Onitẹbọmi ni Naijiria ati loke okun.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Alufa Israel Akanji ba iwe iroyon kan sọrọ lọjọ Ẹti pe awọn orilẹede to wa ninu apapọ ẹgbẹ ijọ Onitbọmi jẹ mẹtadinlaadoje ti wọn si jọ ṣe ipade lori ẹrọ ayelujara Zoom.
Alufa naa sọ ninu eto ipade ti orilẹede Brazil dari rẹ pe awọn ti sọ iroyin yii fun gbogbo orilẹede to darapọ di ẹgbẹ yii nipa awọn ọmọ ti wọn jigbe.
Nigba ti wọn bi wọn pe akitiyan wo ni ijọ Baptist ti n ṣe latigba ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, Alufa Akanji ni "ṣe ẹ mọ pe ijọ ni wa, taa ba si ti wa ninu wahala kan, ibi akọkọ ti a maa n gba lọ ni ọdọ Ọlọrun ninu adura. Nitorinaa, a tin ṣe ipade adura kaakiri gbogbo ijọ Onitẹbọmi ni Naijria ati loke okun.

O ni iṣẹlẹ yii kii ṣe ohun to pamọ, gbogbo Naijiria lo ti gbọ sii ni gbogbo ipinlẹ bẹẹ si apapọ ẹgbẹ awọn ijọ Onitẹbọmi naa si mọ.
Pẹlu ijinigbe yii sibẹ, Akanji ni ijọ Baptist ko ni gbọjẹgẹ to si ni pe ijọ yoo tẹsiwaju lati pese eto ẹkọ to ye koro tori o ni o ti le ni ọgọjọ ọdun ti ijọ Baptist ti n da ile ẹkọ silẹ ni Naijiria.
"Ni bayii, ninu itan wa, igba akọkọ niyii fun ọdun mẹrindinlaadọsan ti ti wọn yoo ṣe ikọlu si ile ẹkọ Baptist ti wọn si ji awọn akẹkọọ gbe. Torinaa a gbagbọ ninu agbara itan wa nipa kikepe Ọlọrun alagbara, awọn akọkọ wa yoo si pada wa ba wa".

O ni fun idi eyi, o tọ si ijọ Onitbọmi pẹlu itan to ti wa nilẹ yii ki awọn akẹkọ awọn gba idalare.
Nigba ti wọn bi Alufa lere boya ijọ Baptist yoo bẹ Afaa ẹsin Islam Sheikh Gumi to ti n ba awọn ajinigbe sọrọ tubi nnubi ni Naijiria lọwẹ ko ba wọn ba awọn ajinigbe ọhun sọrọ, Akanji ni ijọ ko lee da awn obi duro ki wọn ma bẹ Gumi lọwẹ bi wọn ba fẹ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
















