Sunday Igboho: Ariwò tí ẹ̀ ń pa, kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò le è sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́ - Oba Adekunle Oyelude

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Ọba Olowu ti Kuta, nipinlẹ Osun, Hammed Adekunle Oyelude Makama ti ni ijiroro nikan lo le e gba Sunday Igboho silẹ ni ọwọ ijọba orilẹede Naijiria.
Ọba Makama to sọ eyi lasiko to n ṣe ijiroro pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC ni ko si ijọba to le gbe ẹnu dakẹ ti awọn ajijagbara to fẹ da ilu ru bii Sunday Igboho ba dide.
O ni ẹnikẹni ti ijọba ba ti sọ pe awọn n wa, dandan ni ọwọ wọn yoo ba a.
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- Irọ́ pátápátá ni pé mo gba 50milion nairà látí ṣe alátakò Sunday Igboho - Olubadan
- Ẹ wo bí ìṣìnkú TB Joshua ṣe ńlọ ní Arigidi Àkókó lónìí tí yóò wọlẹ̀ sùn!
''Ko si ẹnikẹni to n fi ipa gba ijọba lori ori ẹrọ ayelujara, awọn eniyan gbọdọ parapọ lati jiroro lori ohun ti wọn fẹ.''
''Gbogbo ariwo ti ẹ n pa lori ayelujara ko le doola ẹmi Sunday Igboho, ko si ẹni to le sa mọ ijọba lọwọ''
Bakan naa ni Ọba Olowu toi Kuta naa ni kii ṣe igba akọkọ ni yii ti ijọba ma n ṣekọlu si awọn ọta wọn ni oru.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn adajọ ni ilu Abuja ti ijọba ṣekọlu si, oru ni wọn ṣe e
Awọn orilẹede lagbaye naa n lọ kaakiri lọru lati mu awn eniyan ti wọn ba n lepa, tabi ẹni ti wọn ba fẹ ṣe ikọlu si.''
Ninu ọrọ tirẹ, ọba ni oun ko fẹ Yoruba Natiopn nitori Niajiria dara papọ , amọ atunto Naijiria ni ọna abayọ si iṣoro to n koju orilẹede Naijiria.
Ọba Olowu ti Kuta, nipinlẹ Osun, Hammed Adekunle Oyelude Makama fikun wi pe Ọjọgbọn Banji Akintoye nikan niu oju mimọ to wa lẹyin Yoruba Nation, nitori Ẹgbẹ Afẹnifẹre to sọ gbogbo ọmọ Naijiria papọ sọ wi pe awọn ko fẹ iyapa lorilẹede Naijiria, yatọ si atunto.














