Osun Masquerade attack: Ìdìtẹ̀, ìpànìyàn, ìfìyàjẹni wà lára ẹ̀sùn tí wọn fi kan àwọn afurasí náà

Oríṣun àwòrán, Esuleke
Ile ẹjọ majisireti kan nilu Osogbo ti pasẹ ni Ọjọbọ pe ki wọn fi Olori Eleegun, Fashola Esuleke ati Imaamu agba, Kazeem Yunus pẹlu eeyan marun miran si ahamọ.
Eyi ko sẹyin isẹlẹ ikọlu kan to waye ni Mọsalasi Kamarudeen nilu Osogbo laarin awọn Eleegun ati Musulumi, eyi to mu ẹmi olujọsin kan lọ, ti mẹrinla miran si farapa.
Ọjọ Ẹti to kọja, eyiun ọjọ Keji osu Keji ọdun 2021 ni awọn ọlọpaa ti kọkọ fẹ fi oju awọn afurasi naa ba ile ẹjọ amọ Olori Eleegun, Esuleke lo sadede subu, ti wọn ko si le ko wọn lọ sile ẹjọ mọ.
- Ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá tẹ Kayode Esuleke, olórí Eléégún l‘Osogbo
- Ọdún méjì, wàhálà méjì lójúbọ Osun Osogbo,
- Olólùfẹ́ mi ṣèèsì fi ọkọ́ gbá mi sí gọ́tà, mo rò pé ọlọ́jọ́ dé ni - Iya Osogbo
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Egúngún bá òṣèrébìnrin lòpọ̀ nínú eré, àwọn Eléégún yarí
Amọ ni Ọjọbọ ni ileesẹ ọlọpaa wọ awọn olujẹjọ meje, eyiun Fashola Esuleke, Kola Adeosun, Idowu Abimbola, Kazeem Yunus, Salawu Jimoh, Alarape Sulaimon Akanbi ati Raimi Saheed lọ sile ẹjọ.
Ẹsun ti wọn si fi kan wọn ni iditẹ, ipaniyan, ifiyajẹni, biba dukia jẹ ati dida alaafia ilu ru.
Ọlọpaa agbefọba, Taiwo Adegoke lo kede pe awọn afurasi naa wa nile ẹjọ, ti amofin lati ileesẹ eto idajọ, Moses Faremi si n soju fun ijọba.
Lẹyin eyi ni Adegoke wa bẹ ile ẹjọ pe ko fun oun di la lati gba faili ẹjọ awọn afurasi naa, ki oun si se asaro lori rẹ, ki wọn to tun ko wọn pada wa sile ẹjọ.
O salaye pe "Fashola Esuleke, Kola Adeosun ati Idowu Abimbola ni wọn fi ẹsun apaayan kan nigba ti wọn fi ẹsun ifiyajẹni kan Kazeem Yunus, Salawu Jimoh, Alarape Sulaimon Akanbi ati Raimi Saheed."
Agbẹjọro fun Imaamu agba, Kazeem Odedeji wa rọ ile ẹjọ lati gba Kazeem Yunus, Salawu Jimoh, Alarape Sulaimon Akanbi ati Raimi Saheed lati gbadun oniduro wọn ti agọ ọlọpaa fun wọn.
Amọ agbẹjọro fun awọn Eleegun, Kehinde Abioye ni ile ẹjọ nikan lo le sọ nipa oniduro wọn boya ki wọn si wa ni ahamọ ọlọpaa ni tabi ọgba ẹwọn Ilesa.
Adajọ Majisireti to n gbọ naa, Asimiyu Adebayo wa pasẹ pe ki wọn fi awọn olujẹjọ mejeeje si ahamọ ọlọpaa, to si sun igbẹjọ wọn si ọjọ Aje, ọjọ Kejila osu Keje ọdun 2021.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- Wo bí ètò ìsìnkú TB Joshua ṣe n wáyé ní ìlú abínibí rẹ̀
- Irọ́ pátápátá ni pé mo gba 50milion nairà látí ṣe alátakò Sunday Igboho - Olubadan
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun






















