Sunday Igboho: DSS kò jẹ́ ki mọ̀lẹ́bí tàbí agbẹjọ́rò rí àwọn èèyàn tí wọn ko nílé mi

Oríṣun àwòrán, DSS
Iroyin to n jade lati igun gbajugbaja ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti sisọ loju rẹ nipa ipo ti awọn eeyan ti DSS ko nile rẹ wa.
Agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki lo sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan to ka sita fun araye loju opo Instagram rẹ.
Gẹgẹ bi Koiki ti wi, awọn eeyan mẹwa ti awọn osisẹ DSS ko nile Igboho nilo eto ilera kiamọsa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irọ́ pátápátá ni pé mo gba 50milion nairà látí ṣe alátakò Sunday Igboho - Olubadan
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun
- Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ba orúkọ mi jẹ́ tórí sabuké NYSC mi, mò ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò - Kemi Adeosun
O ni meji ninu wọn nilo ki wọn de ile iwosan fun itọju nitori ipo ailera to lewu ti wọn wa.
Gẹgẹ bi aworan to si wa loju ayelujara gẹgẹ bi DSS se se afihan rẹ, ọkan lara awọn eeyan ti wọn ko nile Igboho ni ọgbẹ ọta ibọn wa nibi orukun rẹ, eyi to we bandeji mọ.
Agbẹnusọ fun Igboho ni ikọ agbẹjọro fun Sunday Igboho ti yọju si ọọfisi DSS nilu Abuja amọ ti awọn osisẹ agbofinro naa kọ lati jẹ ki wọn ri awọn eeyan to wa ni ahamọ naa.
"Eyi ni lati ke si gbogbo awujọ agbaye nipa bi awọn DSS ko se gba awọn eeyan ti wọn ko nile Sunday Igboho laaye lati ri agbẹjọro wọn.
Eyi tako ẹtọ awọn eeyan ti wọn ba mu si ahamọ tori oselu, ti wọn ko si jẹ ki mọlẹbi ati amofin ri wọn.
Koda, awọn lẹta tawọn agbofin wa fi silẹ ni ọọfisi DSS ni wọn ko sisẹ le lori ti wọn si ni asẹ lati oke wa ni.
Meji ninu awọn eeyan yii lo nilo itọju kiakia, paapaa julẹ, obinrin to maa n seto lori ayelujara ti ọpọ mọ si Lady K."
O tẹsiwaju pe awọn agbofinro yii mọ ipo ailera ti obinrin naa wa, eyi to nilo itọju kiakia amọ wọn kọ eti ikun si.
Agbẹnusọ fun Sunday Igboho wa n ke si gbogbo agbaye pe awọn osisẹ DSS lati oke de isalẹ ni ki wn mu bi ohunkohun ba sẹlẹ si ọkankan ninu awọn to wa ni ahamọ naa.
O ni bi awọn osisẹ DSS yii ko se gba awn eeyan naa laaye lati maa jiroro pẹlu awọn agbẹjọro wọn, ti mu ki awọn agbofinro yii gbe igbesẹ kọja agbara ti ofin gbe le wọn lọwọ.
"A wa n kesi DSS lati tun ero wọn pa lori bi wọn se n jẹ gaba le awọn eeyan to wa ni ahamọ wọn lori tabi fiya jẹ wọn nitori eyi tako ofin ilẹ wa ti wọn jẹjẹ lati daabo bo."
O wa koro oju si bi wọn se kọlu ile naa ati bi wọn se mu awọn eeyan naa nile Sunday Igboho.
Bẹẹ ba gbagbe, mọlẹbi awọn eeyan ti DSS ko yii se iwọde ni Ọjọru lati fi ẹhonu han lori bi awọn agbofinro naa ko se ko wọn da si ahamọ lai tu wọn si.





















