Kemi Adeosun NYSC Certificate: Iléẹjọ́ ní Kemi Adeosun kò nílò sabuké láti jẹ mínísítà ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Minisita tẹlẹri fun eto isuna ni Naijiria, Kemi Adeosun ti fesi si aṣẹ ileẹjọ to ni ko jẹbi ẹsun lilo ayederu sabuke ti wọn fi kan an ni ọdun 2018.
Kemi Adeosun ni gbogbo awọn ti wọn tẹ aṣọ oun mẹrẹ pẹlu ẹsun ti wọn fi kan oun ni wọn yoo gburo oun patapata.
Ninu idajọ ile ẹjọ giga ni ilu Abuja ni adajọ ti sọ wi pe ko pọn dandan fun Kemi Adeosun lati sin ilu rẹ fun ọdun kan labẹ asia NYSC, nitori ko yẹ fun ipe naa.
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- 'A sinmi ìwádìí lóri Kemi Adeosun'
- Gbajúmọ̀ òṣèré Bollywood ní India, Dilip Kumar, jáde láyé
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
- Àwọn alátìlẹyìn Sunday Igboho ṣe ìwọ́de ní Ibadan, wọ́n tọrọ nkan márùn-ún lọ́wọ́ Olubadan
Adajọ Taiwo Taiwo ni Adeosun kii ṣe ọmọ Naijiria nigba to ṣetan ni ile iwe giga, to si pe ẹni ọgbọn ọdun, nitori naa ko nilo sabuke.
Bakan naa ni adajọ naa fikun pe ko nilo lati fi sabuke NYSC han ko to le gba ipo minisita lorilẹede Naijiria.
Ọdun 2018 ni Kemi Adeosun fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi minisita fun eto iṣuna lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe ayederu sabuke lo lo fun NYSC rẹ.
Ninu atẹjade ti Adeosun fi sita oun yoo gbe gbogbo igbeṣẹ to yẹ ni abẹ ofin lati ri wi pe oun ja fun orukọ oun ti wọn bajẹ.
''Mo ti gbọ lati ọdọ awọn agbẹjọro mi pe mi o nilo lati ṣe NYSC ki n to di minisita ni Naijiria, eleyii si ni mo ti n ja fun lati ọjọ yii, amọ mo dupẹ pe ọrọ naa ti ni ojutu.''
''Idajọ naa fihan pe emi lo leke ẹsun ti wọn fi kan mi, eleyii to da ẹru si mi lara fun ọdun mẹta.''
- Ẹ wo obìnrin tó pàdé ọkọ́ lẹ́ni ọdún 47 , tó sì bímọ lẹ́ni àádọ́tá ọdún
- Gbanjo! $500 ni tíkẹ́ẹ̀tì ìjọba ọ̀run, ẹ bò ó wìtìwìtì - Pásítọ̀
- Ọlọ́pàá ní Aiye Confraternity rugi oyin tó bá ṣ'ayẹyẹ "7/7" l'Eko
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àwọn olólùfẹ́ Baba Ìjèsà gbé ìgbà Gofund Me láti ràn án lọ́wọ́ sàn owó tí yóò fí ṣé ẹjọ́
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
''Aṣeyọri nla ni eleyii jẹ fun mi ati fun awọn ọmọ Naijiria to wa ni oke okun ti wọn n gbero lati wa ṣiṣẹ ilu amọ ti wọn ko ni sabuke NYSC''
Ileẹjọ giga ni ilu Abuja ni Kemi Adeosun ko jẹbi pẹlu ipo to dimu gẹgẹ bi minisita fun ọrọ iṣuna nigba naa nitori ko ṣe NYSC.












