Laduni Idowu Giwa-Osagie: Ọ̀rẹ́ Laduni sọ pe ìwúrí ni bí ọ̀rẹ́ òun ṣe di ọlọ́mọ láyé

Oríṣun àwòrán, Punchng
Iho ayọ ati idunnu sọ ni ile arabinrin Ladunni Idowu Giwa-Osagie, lẹyin ti itan aye rẹ ja si pe bi ẹkun pe di alẹ, ayọ nbọ ni owurọ.
Itan Ladunni ti jẹ ki ọpọlọpọ obinrin lori ẹrọ ayelujara, to ṣi n woju Ọlọrun fun ọkọ tabi Ọmọ ati awọn ohun ayọ miran ni igbẹkẹle pe, ko si ohun ti o ṣoro ṣe, ati pe asiko eniyan ko ni kọja rẹ.
Gege bi iroyin to wa loju opo Facebook, Ladun lo pade ọkọ rẹ, Aigbovo-Giwa-Osagie ni ọdun mẹtadinlaadọta o le diẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
- Àwọn alátìlẹyìn Sunday Igboho ṣe ìwọ́de ní Ibadan, wọ́n tọrọ nkan márùn-ún lọ́wọ́ Olubadan
- Ọlọ́pàá ní Aiye Confraternity rugi oyin tó bá ṣ'ayẹyẹ "7/7" l'Eko
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àwọn olólùfẹ́ Baba Ìjèsà gbé ìgbà Gofund Me láti ràn án lọ́wọ́ sàn owó tí yóò fí ṣé ẹjọ́
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Láéláé! A ò faramọ́ àbá àwọn Gómìnà Gúúsù pé ààrẹ Nàìjíríà gbọdọ̀ wá láti ẹkùn wọn lọ́dún 2023 - Ẹgbẹ́ Arewa
Ladun ati ọkọ rẹ ṣe igbeyawo lẹyin ọdun kan ti wọn pade ara wọn, eleyii to mu ki arabinrin naa ti di ẹni ọdun mejidinlaadọta.

Oríṣun àwòrán, Punchng
Ko pẹ to ṣe igbeyawo, to ni oyun ni ẹni ọdun mọkandinlaadọta, to si bi ọmọ naa ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ki o to pe ẹni aadọta ọdun.
Ọmọ tuntun jojolo naa wa ni alaafia pẹlu iya rẹ, ti wọn si sọ orukọ rẹ ni Osarumuwese Oluwaseyitanfunmi Nosakhare.
Ọrẹ Ladunni to fi iroyin naa si oju opo ikansiraẹni Facebook rẹ ni, ọpọlọpọ eniyan lo pejọ si ibi isọmọlorukọ ọmọ tuntun jojolo naa, to waye ni agbegbe Ikẹja, ni ilu Eko.
Ọrẹ Ladunni ni arabinrin naa jẹ ẹni to ni igbagbọ ninu Ọlọrun, to si fi gbogbo ọkan ati adura ni ireti pe asiko tirẹ ṣi n bọ.
O ni Ladunni ni ifẹ awọn eniyan pupọ, to si ma n fi ọrọ iyanju ati itunu bọ awọn to ba sun mọ.
Ọrẹ Ladunni wa gba awọn eniyan to n woju Ọlọrun fun ohun ayọ bi eleyii lati maṣe mikan, ki wọn ni igbagbọ ninu Ọlọrun to le ṣe ohun gbogbo ni asiko to yẹ.
















