Sọọsi Zimbabwe: Ọmọbinrin kan ku lasiko ijẹri

Aworan ile ijọsin kan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ijẹri si isẹ Oluwa wọpọ lawọn ile ijọsin

Onidiri kan ti jade laye ninu ile ijọsin Universal Church of God lẹyin to jẹri si isẹ iyanu ti Ọlọrun se ninu aye rẹ, niwaju awọn olujọsin.

Ọmọbinrin to jalaisi naa, ti wọn mọ si Mpofu jẹ olujọsin nile ijọsin to wa lagbeegbe Bulawayo, lorilẹede Zimbabwe, nibi to ti sọ nipa isẹ iyanu tọlọrun se ninu aye rẹ.

Gẹgẹbi iroyin naa ti wi, Mpofu subu lulẹ lẹyin to se ijẹri naa tan, to si ku sile ijọsin naa.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Ibatan obinrin naa, ti ko fẹ ki wọn darukọ ohun, sọ wipe kayeefi lo jẹ fun oun lori bi obinrin naa se ku, ati wipe ko ye awọn idi ti obinrin naa fi ku lẹyin to sọ ijẹri rẹ tan.

Gbogbo igbesẹ lati mọ bi isẹlẹ naa se waye latọdọ ile ijọsin naa si lo ja si pabo.