Sunday Igboho: Olubadan ní ọmọ òun ni Sunday Igboho bí ò tilẹ̀ kí ń ṣe ọmọ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ti ni ko si otitọ ninu ọrọ wi pe oun gba owo gọbọi lati fi ṣe alatako Sunday Igboho.
Ni asiko ti awọn alatilẹyin Sunday Igboho ṣe iwọde lọ si aafin ni agbẹnusọ fun Olubadan ti sọ ọrọ naa. Bẹẹ si ni Kabiyesi naa ba awọn oluwọde sọrọ.
Ninu ọrọ ti agbẹnusọ Olubadan ba awọn oluwọde naa sọ, o ni irọ patapata ni pe oun (kabiesi) gba 50 million lọwọ ẹnikẹni lori Igboho.
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Láéláé! A ò faramọ́ àbá àwọn Gómìnà Gúúsù pé ààrẹ Nàìjíríà gbọdọ̀ wá láti ẹkùn wọn lọ́dún 2023 - Ẹgbẹ́ Arewa
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
Kabiyesi sọ pe kini oun fẹ fi iru owo bẹẹ ṣe ni ọjọ ori oun.
O ni ọmọ Olubadan ni Igboho, bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ọmọ Ibadan.
O ni ẹni to ba n ṣe daadaa, eeyan o le gbowo lori rẹ, nitori pe ayọ aye eeyan ko ṣe e diye le.
Àwọn alátìlẹyìn Sunday Igboho ṣe ìwọ́de ní Ibadan, wọ́n tọrọ nkan márùn-ún lọ́wọ́ Olubadan

Ogunlọgọ awọn alatilẹyin Sunday Igboho, ati idasilẹ Yoruba Nation ti ṣe iwọde nilu Ibadan.
Ile Sunday Igboho to wa ni adugbo Soka ni awọn oluwọde naa ti kọkọ bẹrẹ iwọde wọn ni owurọ Ọjọru, ki wọn o to o lọ si aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji.
Wọn kọkọ fẹ ẹ yan eeyan mẹfa lati wọle ri kabiesi, amọ eto naa ko niyanju nitori bi ọpọ eeyan ṣe n sọ pe ki kabiesi jade sita ba awọn sọrọ ni.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Awọn nkan ti awọn oluwọde fẹ ki Olubadan ṣe
Ẹni to gba ẹnu awọn oluwọde naa sọ pe awọn mọ pe ọba ni aṣẹ lati yanju isoro awọn ni awọn ṣe wa si aafin.
O si ka nkan marun-un silẹ fun Olubadan, Ọba Saliu Adetunji.
- Wọn ni ki kabiesi sọ fun ijọba ki wọn o yọnda awọn eeyan ti wọn ko nile Igboho. Wọ ni awọn ko ni owo tabi agbẹjọro lati doola wọn.
- Ki idajọ ododo waye lori awọn meji ti wọn pa nile rẹ.
- Ki wọn o san owo gba mabinu fun Igboho lori awọn dukia rẹ ti DSS bajẹ
- Ki wọn o ma pe Igboho ni 'wanted' mọ. Ki wọn o yi awọn ọrọ ti wọn sọ nipa rẹ pada
Olubadan da wọn lohun pe ọmọ Olubadan ni Sunday Igboho ati pe gbogbo awọn to yẹ ki kabiesi pe lori ọrọ naa ni yoo pe.

















