Sunday Igboho: Agbekoya ní wàhálà yóò ṣẹlẹ̀ tí Buhari bá mú Igboho, Gani Adams àti Akitoye

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Yoruba, Agbekoya, ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu tawọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe si ile ajafẹtọ ati ajijagbara, Sunday Igboho lagbegbe Soka niluu Ibadan.
Ẹgbẹ Agbekoya wa rọ ijọba apapọ lati semẹdọ lori igbesẹ rẹ lati fi ọwọ ofin mu Igboho at'awọn mii nitori wọn n pe fun iyapapa ẹya Yoruba lara orilẹede Naijiria.
Ẹgbẹ naa ṣe ikilọ yii ninu atẹjade kan to fi sita eleyii ti Jagunmolu Agbekoya ilẹ Yoruba, Kunle Adelakun ti ọpọ mọ si Eruobodo, buwọlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo ti yọ'wọ́ lọ́rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà, tẹ́ẹ bá ń gbọ́ pé Obasanjo dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, "ẹyẹ mi kọ́"!
- Ẹ fi Sunday Ìgbòho sílẹ, ǹkan tí ìjọba Nàìjíríà bàjẹ́ ló ń gbìyànjú àti túnṣé; Ìjọba àpapọ̀ ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ - Wole Soyinka
- Ẹ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìsínkù Wòlí TB Joshua, àyẹ̀wò ṣọ́ọ̀ṣì yín tí a ṣe dáńgájíá- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
- Ó tún ti ṣẹlẹ̀! Agbébọn tún jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Baptist kan gbé
- Àwọn ọmọ ìkókó níléèwòsàn kàgbákò agbébọn! Wọ́n jí wọn gbé pẹ̀lú nọ́ọ̀sì
- Àwọn gómìnà ní Gúúsù Naijiria ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko
Ẹgbẹ Agbekoya ni ohun ti wọn n ja fun wa ni ibamu pẹlu ofin, ati pe ajọ iṣọkan agbaaye, UN gan an fọwọ sii.
"Ijọba gbọdọ tun ero rẹ pa lori igbesẹ lati mu Igboho, Ọjọgbọn Banji Akintoye, Aarẹ Gani Adams ati awọn ti wọn n ja fun Yoruba Nation.
Bi bẹẹ kọọ, rogbodiyan ni ọmọ ti iru igbesẹ bayii maa n bi.
Agbekoya kii gbe ibọn, a o si ni ìbọn AK-47 pẹlu tori a ko ni igbagbọ ninu rẹ.
Ọgbọn ati imọ ti Eledumare fún wa ni agbara wa.
Amọran wà fún Aarẹ Muhammadu Buhari ni pe ki o fi ọgbọn yanju ọrọ to wa nilẹ yii.
Nkan ko tii buru to bayii ri ninu itan Naijiria lati ọdun 1914 ti awọn oyinbo ti da wa pọ.
Awọn araalu lẹtọọ lati sọ ẹdun ọkan wọn tàbí ohun ti wọn n fẹ labẹ ijọba awaarawa.
Sí ẹyin olori ẹya Yoruba lagbo oṣelu bíi Asiwaju Bola Tinubu, Oloye Bisi Akande, Ajagun fẹhinti Alani Akinrinade, Oloye Olusegun Obasanjo ati Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo, ẹ tun ero yin pa.
Awa ẹgbẹ Agbekoya ko ni ṣalai duro gbọingbọin lẹyin araalu.
Yoruba gbọdọ fi imọ ṣọkan, ati pe ko si ohun to buru ninu ki eeyan maa pe fún idasilẹ Yoruba Nation," Agbekoya ṣalaye.




















