Sunday Igboho: Olugbon ní ìjọba gbọdọ̀ sọ ẹni tó wà ní ìdí ìkọlù ilé Sunday Igboho

Olugbọn ti Orile Igbọn, to tun jẹ igbakeji alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo, Oba Francis Olusola Alao, ti rọ Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lati se mẹdọ na, lori iwọde idasilẹ Yoruba Nation ọjọ Satide niluu Eko.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kabiyesi Olugbọn ṣalaye pe Igboho atawọn eeyan rẹ gbọdọ sun iwọde naa siwaju pẹlu bi awọn agbebọn ṣe kọlu ile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.
Olugbọn rọ Igboho lati bu omi suuru mu diẹ, lati wo ohun to n ṣẹlẹ pẹlu bi wọn ti kọlu ile rẹ nidaji ọjọbọ, ki wọn to tun tẹ siwaju pẹlu iwọde to n bọ niluu Eko.
- Ẹ̀jẹ̀ kúnlẹ̀ nílé Sunday Igboho, ẹ̀mí méjì bọ́ lásìkò tí afurasí Sọ́jà kọlu ilé rẹ̀
- Afurasí ‘Sọ́jà’ kọlu ilé Sunday Igboho lóru mọ́jú, òkú ṣùn, dúkìá bàjẹ́
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá tẹ Kayode Esuleke, olórí Eléégún l‘Osogbo
- Sunday Igboho ní digbí lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu àti ìdásílẹ̀ Biafra
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Jẹ́jẹ́ ni Iyabo Ojo jókòó, èmi ni mo pèé sí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Lola Alao fún Bukky Black lésì
Ṣugbọn Olugbon ni oun ko sọ pe ki Igboho ma ṣe iwọde tori ṣiṣe ifẹhonuhan ko tapa si ofin orilẹede Naijiria.
Olugbon ni Igboho ko ba ijọba ja pẹlu ifẹhonuhan fun idasilẹ Yoruba ti o n ṣe agbatẹru rẹ.
Kabiyesi Olugbon ni ''a gbọdọ kọkọ ṣe iwadii iṣẹlẹ yii bo ya awọn sọja lo ṣe e tabi awọn kọ. To ba jẹ awọn sọja lo ṣee, ẹnikẹni to wu ko le ṣee, ohun to buru jai ni.
Nitori ofin ko sọ fun wa pe Igboho tabi ọmọ Naijiria ko lẹtọ lati ṣe iwọde, ijọba gbọdọ wa idi ohun to ṣẹlẹ yii, ohun ti a n sọ niyẹn pe ko si abo niluu.
Ijọba gbọdọ ṣalaye lati sọ awọn to wa nidi iṣẹlẹ laabi yi, ki wọn si wa nkan ṣe si ọrọ eto aabo to mẹhẹ yii.

Ohun to n ṣẹlẹ yii ko ye mi mọ o, Naijiria ti wa di oju ni alakan fi n ṣọri bayii,'' Olugbon lo woye bẹẹ.
Ninu fidio ti agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki fi soju opo Facebook rẹ, o ni awọn afurasi sọja lo yabo ile ajijagbara nibi to ti sọ pe wọn ṣekupa eeyan meji.
Bakan naa lo ni wọn ba dukia atawọn ọkọ Oloye Igboho jẹ, ti wọn si tun gbe awọn eeyan to wa ninu ile lọ.


















