Nnamdi Kanu: Sunday Igboho ní mímú aṣaájú IPOB kò lè dí ìwọ́de Yoruba Nation Eko lọ́wọ́

aworan igboho ati kanu

Oríṣun àwòrán, other

Ọkan gboogi lara awọn to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti sọ pe bi ọwọ ijọba ṣe tẹ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Biafra, Mazi Nnamdi Kanu, ko ni idiwọ kankan fun ohun ti oun n ja fun.

Lọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe ọwọ ijọba ti tẹ Nnamdi Kanu, ti wọn si ti fi si ahamọ lẹyin ti wọn foju rẹ ba ileẹjọ giga apapọ nilu Abuja.

Eyi mu ki ọpọ awọn ololufẹ Sunday Igboho o maa ko aya soke pe, o ṣeeṣe ki ijọba maa gbiyanju ati fi ṣikun ofin gbe Igboho pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa, Igboho Ooṣa, gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e sọ pe, ẹru ko ba oun o ati pe eyi ko ni idiwọ kankan lati ṣe fun iwọde ipe fun 'Yoruba Nation".

Sunday Igboho lo fi ọrọ yii lede lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Koda, o ni iwọde naa ti wọn ti seto pe yoo waye ni ilu Eko lọjọ Satide, ọjọ kẹta oṣu Keje ọdun 2021, yoo lọ, gẹgẹ bo se wa ni akọsilẹ.

Bakan naa lo fi kun un pe, gba-gba-gba loun wa lẹyin Nnamdi Kanu ati pe atilẹyin oun ko yẹ gẹrẹ ninu atilẹyin oun fun ipe fun orilẹede Biafra.

N ko lagbara lati ba ijọ̀ba ja:

Bakan naa ni Igboho ti kede ninu fidio kan to n ja lori ayelujara pe oun ko ni agbara kankan lati ba ijọba apapọ ja tabi ijọba ibilẹ lasan.

O ni Ọlọrun ni yoo ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation ati iran Yoruba lapapọ, ki wọn le ya kuro lara Naijiria.

O ni oun ko gbagbọ pe ẹnikẹni n dunkoko lati di awọn ajija gbara naa lọwọ lati wa silu Eko fun iwọde lọjọ Satide to n bọ.

Ọrọ ti Sunday Igboho sọ

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki/Facebook

O ni ti eyi ba jẹ otitọ, ki ẹni naa se fidio ara rẹ sita, ko si sọ awọn ọrọ naa, eyi ti yoo jẹ kawọn ri otitọ ọrọ dimu.

Igboho fikun pe awọn ara Eko ti n foju sọna lati gbalejo ikọ Yoruba Nation lọjọ Satide, ti iwọde naa yoo si lọ wọọrọ wọ.

Wayi, Sunday Igboho ti wa rawọ ẹbẹ si ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Eko lati pese eto aabo to peye fawọn oluwọde naa nitori gbogbo ọmọ Yoruba lo n fẹ ki iwọde naa waye.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ