Ajaawa Mayhem: Alága Káńsù ní ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀, amọ tí ààrin wọn dàrú, ni wọn wá mú lọ́gànjọ́ òru.

Otitọ ọrọ ti n foju han sita nipa bi isẹlẹ ipaniyan to waye nilu Ajaawa, nijọba ibilẹ Ogo Oluwa nipinlẹ Oyo se waye.
Alaga ijọba ibilẹ Ogo Oluwa, to kalẹ si Ajaawa, Hon Oluwaseun Ojo lo salaye ohun to sokunfa isẹlẹ naa lasiko to n ba BBC Yoruba.
Gẹgẹ bi Ojo se wi, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ade Master ni a gbọ pe awọn ọlọpa wa sinu ilu Ajaawa, ti wọ̀n si ni ọga ọlọpa pata nilu Abuja lo fẹ ri.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá tẹ Kayode Esuleke, olórí Eléégún l‘Osogbo
- Sunday Igboho ní digbí lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu àti ìdásílẹ̀ Biafra
- TAMPAN bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn igun tó ń bínú, ọ̀rọ̀ yóò yanjú láìpẹ́ - Femi Adebayo
- Ta ló fẹ́ jí Auxilliary gbé ní Ibadan?
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Èèmọ́ wọ̀lú, ta ló yìnbon pá Babalawo àti ẹlòmíì, tí ọ̀pọ̀ sì fara pa ní Ajaawa?
- Bíṣọ́ọ̀bù Enugu ní obìnrin ni wọ́n fi mú Nnamdi Kanu
Ojo ni ọga ọlọpa ni Ajaawa lo fi ọrọ naa to oun leti, to si ni awọn osisẹ ọlọpaa yii ti kọkọ lọ yọju si Kọmisana ọlọpaa ni Ibadan ati ọga ọlọpaa ni ẹkun naa.
O ni deede aago kan oru ni ibọn to n dun lakọ-lakọ sadeede ji gbogbo ilu naa silẹ, ti awọn si ri pe awọn ọlọpaa lati Abuja naa lo n yinbọn kiri.
"Wọn ni Ade Master ni wọn wa mu lati Abuja, pe ọga agba ọlọpaa ni ki wọn gbe wa. Bẹẹ ni ọkọ olowo iyebiye nlanla ni ọkunrin naa maa n lo lai se isẹ kankan.
Koda, awọn ọlọpaa gan ko ẹsọ meji fun to maa n tẹle lẹyin, ti wọn si tun fun ni nọmba ọkọ pataki to so mọ ara ọkọ rẹ.
Ade Master yii lo tun n lo ọkọ yafunyafun bii gomina kaakiri, tawọn ẹsọ ẹyin rẹ si maa n yinbọn kaakiri bo se wu wọn.
A ko wa mọ ohun to se fun awọn ọlọpaa, ti wọn ko fi se atilẹyin fun mọ ati idi to se jẹ pe aajin oru ni wọn wa mu."
Alaga ijọba ibilẹ Ogo Oluwa ni se ni awọn ọlọpaa naa kọkọ lọ si ibujoko ijọba ibilẹ naa lori, ti wọn si n yinbọn kiri, ki wọn to mọ pe ọọfisi ni awọn wa.
O fikun pe lẹyin eyi ni wọn wa lọ sile kan, ti wọn si n yinbọn mọ ibẹ, eeyan meji lo ku, ti ọpọlọpọ miran si fara pa.
Ojo salaye pe pẹlu ibẹrubojo ni awọn eeyan ilu naa n gbe bayii, ti ọpọ si ti n sa kuro ninu ilu naa nitoi ọkan wọn ti ko balẹ.
"Mo bi ọga ọlọpaa ni Ajaawa pe ki lo de ti wọn fi wa laarin oru lati wa mu afurasi kan, amọ o ni oun ko le dahun ibeere yẹn, amọ o ni ki n lọ bi Kọmisana ọlọpaa.
Ohun gbogbo lo ti doju de laarin ilu, awọn akẹkọọ ko le lọ sile ẹkọ mọ, ti inu fu, aya fu si gbalẹ kan."
Amọ ibeere ti alaga naa sa n beere ni pe, o se jẹ aarin oru ni ọlọpaa wa mu afurasi, to si n yinbọn laibikita, eyi to pa ọpọ eeyan.
Ileesẹ ọlọpaa sekilọ fawọn ọdọ ni Ajaawa lati ma se ikọlu si osisẹ awọn:
Wayi o, ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti tabuku isẹlẹ to waye sawọn osisẹ rẹ eyi ti awọn ọdọ ilu Ajaawa se.
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita, pẹlu afikun pe isẹ iwadi ni awọn ọlọpaa naa lọ se lori isẹlẹ ipaniyan to waye ni Ajaawa, amọ ti awọn ọdọ gbe oju agan si wọn.
Koda, o ni wọn gba awọn irinsẹ ati ohun ija ti awọn ọlọpaa naa ko lọwọ, to si n kọminu lori fifi ẹhonu han sawọn osisẹ ọlọpaa to n sisẹ wọn labẹ ofin.
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa leri leka pe gbogbo awọn eeyan ti aje iwa idaluru naa ba si mọ lori ni yoo jiya to tọ labẹ ofin.

Èèmọ́ wọ̀lú, ta ló yìnbon pá Babalawo àti ẹlòmíì, tí ọ̀pọ̀ sì fara pa ní Ajaawa?

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency
Se ni ilu Ajaawa gbona jainjain laarọ ọjọ isegun nigba ti awọn eeyan kan ti wọn fura si bii ọlọpaa sadede rọjo ibọn si ile kan.
Eeyan meji lo ti padanu ẹmi wọn tawọn mẹwaa mii si farapa nigba tawọn ọlọpaa kan yabo Ajaawa ni ijọba ibilẹ Ogo Oluwa lọjọ Aje ni ipinlẹ Oyo.
Ko daju ibi tawọn ikọ ọlọpaa yii ti wa ṣugbọn awọn kan ni lati ọọfisi ọga agba Ọlọpaa ni Abuja ni wọn ti wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Bíṣọ́ọ̀bù Enugu ní obìnrin ni wọ́n fi mú Nnamdi Kanu
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Interpol ṣèrànwọ́ fún ìjọba àpapọ̀ láti mú Nnamdi Kanu
- Orí àgbá ẹ̀tù láwọn èèyàn Ibarapa jókòó lé, wàhálà ń bọ̀ - OPC mẹ́ta tó gba ìdáǹdè
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
Gẹgẹ bi ohun taa gbọ, awọn eeyan sọ pe nise ni awọn ọlọpaa naa wọ ilu ni nkan bi ago kan oru ninu ọkọ Sienna mẹta ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn lu awọn ile kan.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọjọ Iṣẹgun, alaga ijọba ibilẹ Ogo Oluwa, ti ibujoko rẹ wa ni Ajaawa, Arakunrin Seun Ojo ni awọn ọlọpaa to wa ṣiṣẹ forukọ silẹ lagọ ọlọpaa to wa ni Ajaawa ati ni ọdọ ọga agba ọlọpaa agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Alaga iba ibilẹ Ajaawa n bawọn akọroyin sọrọ
Eyi jẹ ki a ribi fidi ọrọ mulẹ pe lootọ awọn ọlọpaa lo wa nidi ikọlu yii.
Ninu awọn ti Ojo sọ pe o farakasa iṣẹlẹ yii ni Babalawo Onifa ilu naa Ifaleye Jaiyeola.
O ni awọn ọlọpaa naa gbe oku rẹ, iyawo rẹ ati awakọ rẹ lọwọ lọ.
Ojo ṣalaye pe " Laarin oru ni nkan bi ago kan ni a ṣadede gbọ ariwo ẹ gba wa lọdọ awọn araalu Ajaawa latari iro ibọn kikan kikan to gbode lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa''
"Lẹyin ti a ṣe iwaadi, a ribi fidi ọrọ mulẹ pe awọn ọlọpaa doju ibọn kọ awọn ile kan ni Ajaawa lai ni idi kan pato''
O ni ''nkan ti wọn sọ fun wa ni pe lati ọọfisi ọga agba ọlọpaa ni wọn ti ran awọn ikọ to wa ṣiṣẹ yi wa.
Wọn forukọ silẹ ni agọ ọlọpaa ati lọdọ ọga ọlọpaa agbegbe naa, ti eyi si jẹ aridaju fun wa pe ọlọpaa ni wọn''
O tẹsiwaju pe ''o jẹ eemọ fun wa idi tawọn ọlọpaa yoo se ṣigun wọ ilu, ti wọn yoo si maa da ibẹrubojo si ọkan ara ilu lai nidi debi pe ẹmi yoo ṣofo ninu iṣẹlẹ naa''
''Baa ṣe n ba yin sọrọ yii, ati fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji ti ku, ti eeyan mẹwaa si farapa''
O ka ọrọ rẹ nilẹ pe awọn ṣi n ṣe akojọ iye eeyan to farapa nitori pe oun ni lati sare wa jabọ nkan to ṣẹlẹ ni Ibadan naa.
Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati gbọ ti ẹnu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lori isẹlẹ yii, lo ja si pabo nitori agbẹnusọ fun ọlọpa ipinlẹ Oyo ko gbe aago ipe wa.




















