Kunle Ologundudu: Ìdájọ́ òdodo nìkan ni mò ń bèèrè fún lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesa

Oríṣun àwòrán, @Kunle Ologundudu
Gbajugbaja akewi sọ̀rọ̀ sawon asebajẹ lawujọ paapaa awọn Oloselu ni, Kunle Ologundudu ti ni iku ko si loju oun bayii.
O ni asiko onikaluku yatọ ati pe asiko ti oun ko tii to rara.
Awọn ọmọ Naijiria ti n bẹnu atẹ lu awọn to gbe iroyin ẹlẹjẹ pe gbajugbaja akewi ilẹ Yoruba, Kunle Ologundudu ti kagbako iku lọwọ awọn agbebọn.
Kunle Ologundudu gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ padanu ẹmi rẹ lọwọ awọn agbebọn niwaju ile rẹ nilu Eko.
Ẹni to kọkọ ke gbajare lori iroyin ofege yi ni ẹni ti ọrọ naa kan-Kunle Ologundudu.
- Àwọn ọlọ́pàá máa ń yọ Baba Ijesha jáde látimọ́lé lálaalẹ́ - Princess
- Bí àwọn gbajúmọ̀ ṣe pín rèé lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá
- Àjọ NYSC kò gbèrò rírán àwọn àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun- Àjọ NYSC
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
Ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tí mo dá sí ló mú kí àwọn tó ń bá a jà ro ikú sí mi- Ologundudu
Kí ló pa Ologundudu àti Baba Ijesha pọ̀ débi pé ìròyìn ikú rẹ̀ gborí ayélujára?
Ninu fọnran fidio kan, o ṣalaye pe ṣadede loun bẹrẹ si ni gba ipe lorisirisi tawọn eeyan si fẹ mọ pe boya lootọ lo kagbako iku.
O ṣalaye pe ọrọ naa ko ṣẹyin bi oun ti ṣe dasi ọrọ awuyewuye to niṣe pẹlu oṣere tiata Yoruba Olanrewaju James taa mọ si Baba Ijesha.
'' Nkan to ṣẹlẹ ni pe ọrọ baba Ijesha ti mo da si lo jẹ ki awọn to n ba ja fẹ maa gbe 'rumours' kiri nipa mi''

Oríṣun àwòrán, Facebook Screenshot/Femi Salako
O ni idi ti wọn fi n ṣe bẹ ni ki irẹwẹsi ọkan le de ba oun lati le ma ja fun ifi idajọ ododo lelẹ.
Ologundudu sọ pe awọn to gbe iroyin yi kaakiri lero wi pe Eko loun wa ṣugbọn oun ko si ni Eko rara.

Ologundudu ni: ''O yẹ ki a yọju sile ẹjọ lori ọrọ Baba Ijesha ṣugbọn mi o raye. Ife ni mo wa.
O ni koda, Ife ni mo wa titi di bi a ṣe n sọrọ yi''
Ninu awọn to kọ ọrọ tako iroyin yi ni Babafemi Ojudu to jẹ oludamọran pataki si aarẹ Buhari lori ọrọ oṣelu.
- O kú ogun àjàyé Tope Alabi, odò Jodani lo ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjà yìí o! Àmọ́ rántí pé ... - Mike Bamiloye
- Bìlísì míì wáyé n‘Ibadan, ọmọ ìṣọta kọlu OPC, ẹ̀mí bọ́
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND
Ojudu bẹnu atẹ lu iwa yi to si ni iru iṣẹ iroyin kikọ bayi ko bojumu rara.
''Mo ji lowurọ oni lati ka nipa iroyin kan pe Kunle Ologundudu ti ku.Nigba ti maa fi kan si, o ni kokoko lara oun le ati pe lati ago meji oru lawọn eeyan ti n pe oun lori ago''.
Ojudu sọ pe awọn akọroyin ti ko kọṣẹ iroyin yi ti n da wahala sil plu agbelẹkọ iroyin wọn.
Ojudu ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi alaburu ẹda ti wn fẹ maa da wahala silẹ lawujọ.
Lakotan, o sọ pe pẹlu nkan to n ṣẹlẹ yi, oun ti wa gba wi pe o yẹ ki wọn fofin de iroyin ayelujara.
''O yẹ ki wọn ṣagbekal ilana bibẹẹkọ, iroyin ayederu le dana sun orileede wa''
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
- Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Muhammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án tí àwọn èèyàn ń mu
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Ìjọ RCCG kìí ṣe tí Nàíjíríà níkan, ìjọba kò lè dá wa dúró láti lo Twitter- Pásítọ̀ E. A. Adeboye
- À ń ṣe ara wa ni Bí a bá kọ̀ láti máa lo egbòogi igbó ní Naijiria - Akeredolu














