Ibadan Hoodlums Fracas: Ẹ̀mí OPC méjì bọ́, ọ̀kan wà ní ‘Coma’, wọn jó ọ̀pọ̀ dúkìá

Awọn ọmọ isọta to n fa wahala

Oríṣun àwòrán, Sikiru Adeyemo

Lẹyin ọjọ kansoso pere ti wahala waye ladugbo Iwo Road nilu Ibadan, eyi to mu ẹmi lọ, rogbodiyan miran tun ti bẹ silẹ nilu naa loru mọju ọjọ Ẹti.

Awọn ọmọ isọta kan ati awọn ọmọ ẹgbẹ OPC la gbọ pe wọn fija pẹẹta nidaji ọjọ Ẹti naa ladugbo inalende si Oopo Yeosa nilu Ibadan.

Koda rogbodiyan yii lo mu ẹmi lọ, ti wọn si jo awọn dukia kan nina pẹlu.

Koda, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olawale Osifeso ti fidi isẹlẹ naa mulẹ, amọ ko le sọ iye ẹmi to ba laasigbo naa rin.

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba, ọlọ́pàá, ológun, Amotekun ò bá le gbà wá, àwa mú Wakili láti gba ìran Yorùbá sílẹ̀ ni - OPC

Bawo ni isẹlẹ yii se waye:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori rogbodiyan naa, oludari ẹgbẹ OPC nipinlẹ Oyo, igun ti Gani Adams, Rotimi Olumo salaye pe ni bii deede aago mejila oru ni awọn ọmọ isọta wa ka awọn mọ ọọfisi awọn.

O ni tẹlẹ tẹlẹ ni awọn ọmọ isọta naa ti maa n ja awọn eeyan lole ladugbo naa pẹlu ọbẹ, ti alẹ ba ti lẹ ni deede aago mẹwa, ti wọn yoo ja owo gba, to fi mọ foonu ati dukia mii lọwọ awọn eeyan to n rin lọ.

"Ẹni to jẹ olori OPC nibẹ ti lọ fi ẹjọ awọn ọmọ isọta yii sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Mokola amọ ohun to fa isẹlẹ akọtun yii ni pe awọn ọmọ isọta naa lọ ji ọkada gbe loru mọju ọjọbọ.

Nigba ti ọkada naa taku lasiko ti wọn n gbe lọ, ti igbiyanju wọn lati mu ko sisẹ si ja si pabo, ni wọn ba sọ ina si, ti wọn si fi silẹ lọ.

Amọ nigba to di idaji ni wọn pada wa lati wa gbe ajoku ọkada naa, ti ọkan lara ọmọ ẹgbẹ OPC si jade si wọn pe ko fi ẹri silẹ pe ẹni to fẹ gbe ọkada naa lo ni."

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Olumọ ni bi wahala se bẹrẹ ree o nirọlẹ Ọjọbọ, amọ awọn ọlọpaa ati Operation Burst doola isẹlẹ naa, ti ko fi di wahala.

Amọ o ni nigba to di alẹ, awọn ọmọ isọta naa pada wa lọgọọrọ, ti wọn si wa kọlu ọọfisi OPC to wa nibẹ.

"Se ni wọn n yinbọn lakọlakọ mọ awọn eeyan wa, ti wọn si se wọn lese, ẹmi ọmọ ẹgbẹ wa meji lo bọ ninu laasigbo naa."

Bakan naa lo ni ẹni kẹta ti wọn se lese wa lori yooku, yoo ye, ti ko si mọ boya aye ni oun wa, abi ọrun nile iwosan ti wọn gbe lọ.

Olumọ fikun pe awọn ọmọ isọta naa tun jo ọkada kan nina, ti wọn si tun jo odidi ile kan kalẹ lasiko ti wahala naa fọn ina soju.

"Omọ isọta to lewaju awọn ọmọ isọta wa si agbegbe Oopo ni Dare Jalaruru, orukọ awọn ọmọ OPC ti wọn pa ni Akin Aluko, ti ekeji si n jẹ Quassim Omitola.

Ẹnikẹta ti wọn sa lada yanna yanna to wa ni Koma nile iwosan lo n jẹ Opeyemi.

Bakan naa ni wọn sun ile Olodo to jẹ ọmọ ẹgbẹ wa, se ni o raye sa asala fun ẹmi rẹ, bi bẹẹ kọ, ẹmi tiẹ naa ko ba ba isẹlẹ naa rin.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Se lootọ ni pe OPC yoo gbẹsan isẹlẹ yii?

Nigba to n dahun isẹlẹ yii, Rotimi Olumo ni oun ti n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oun sọrọ pe ki wọn jẹ ki ijọba gba akoso ọrọ naa.

"Emi ati ọga ọlọpaa ti sọrọ, o si ni ki n jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ wa kuro nibẹ yẹn. Pẹlu idanilẹkọ taa ti fun wọn ti wọn si jẹ ọmọ ẹgbẹ to n gbọ ọrọ si ọga rẹ lẹnu.

O daju pe wọn ko ni pinnu lati gba ẹsan lori ọrọ naa amọ bi awọn ọmọ isọta yii ba tun wa pada kọlu wọn, awọn naa yoo fẹ daabo bo ara wọn.

Mo wa n rọ awọn ọlọpaa lati lọ gba akoso agbegbe naa, ki eruku wahala ma tun pada ru lẹẹkan si."

Olumo fikun pe titi di akoko to n ba BBC Yoruba sọrọ̀, awọn ko tii ri gbọ pe ọwọ ọlọpa tẹ ẹnikẹni lori isẹlẹ yii.