Yoruba Nation: Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè ní títìpa ṣì ní ẹnu bodè Idi Iroko wà

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Se ni ibẹru bojo gba ilẹ kan ni agbegbe Idi Iroko nigba ti awọn ọdọ to n beere fun Yoruba Nation ya bo ẹnu Ibode Naijiria si Cotonou to wa nibẹ.
Awọn ọdọ yii ti wọn pọ niye ninu isẹlẹ naa to waye lọjọ Satide, gẹgẹ bi fidio kan to lu oju opo ayelujara ti safihan rẹ, ni wọn n pariwo pe awọn n fẹ idasilẹ Yoruba Nation.
Bakan naa ni wọ̀n si tun n beere pe awọn n fẹ kijọba si ẹnu ibode to ti ti pa silẹ lati ọdun 2019.
- Tó bá dá Gani Adams lójú, kó dárúkọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ inú Yoruba Nation - OPC New Era
- Ẹ̀yin aṣaájú APC, ẹ́ kábáàmọ̀ ìpinnu tẹ ṣe lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation - Akitoye
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- Ó ń rúgbó bọ̀ o! Àwọn ajìjàngbara Yorùbá Nation fipá ṣí bọ́dà Idiroko, àmọ́...
- Ẹ wo àwọ́n lọ́balọ́ba tó ti ṣàtìlẹ́yìn jíjá fún Oduduwa Nation ní ilẹ̀ Yorùbá
- Àìgbọ́ra ẹni yé ẹ̀yà Yoruba ló ń ṣe ìdíwọ́ fún òmìnira wa - Àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ Yoruba l'àgbáyé
Awọn ọdọ to n fi ẹhonu han naa, lo gbe oniruuru akọle lọwọ, lara ohun ti wọn kọ sinu akọle naa ni pe "O to gẹẹ, iya yii ti pọ ju, A ko fẹ duro ni Naijiria mọ."
Bakan naa ni wọn ni Orilẹede Oduduwa ni awọn n fẹ, ti wọn si n to lọwọọwọ lọ si eti ibode Naijiria si Benin, ti wọn si fi agbara si ẹnu geeti to wa nibẹ.
Ninu fidio naa ti ko ju ogun isẹju lọ, ni wọn ti ja ibọn gba lọwọ osisẹ asọbode kan to wọ asọ alawọ yẹlo, to n ta ibọn soju afẹfẹ.
Oniruuru ohun lo n jade sita ninu fidio naa, ti wọn si n ke si awọn osisẹ ologun atawọn agbofinro mii lati jade sita wa yin ibọn mọ awọn.
Awọn ọdọ naa ba ẹnu geeti bode naa jẹ, ti wọn si n pariwo pe "A ti si ẹnu bode Idi Iroko, ẹyin eeyan, ẹ maa wa ba ọrọ aje yin lọ lẹnu bode naa."
Lasiko rogbodiyan ọhun, wọn lu ọkunrin kan to n tiraka lati fi foonu rẹ ya isẹlẹ naa.
Titipa si ni ẹnu ibode Idi Iroko wa - Ileesẹ Asọbode
Ileesẹ asọbode ilẹ wa ti wa fesi pe titipa si ni ẹnu bode Idi Iroko wa, bi o tilẹ jẹ pe lootọ lawọn ọdọ kan gbiyanju lati ja geeti ibẹ.
Agbẹnusọ fun ileesẹ asọbode fun ẹkun kinni, Hammed Oloyede ni nibamu pẹlu asẹ ijọba, ko si ẹni to le si ẹnu ibode naa.
"Lootọ ni awọn ọdọ kan to pe ara wọn ni ajijagbara fun Yoruba Nation wa wa si ẹnu bode Idi Iroko lalẹ Satide amọ ọwọ ka wọn, ti wọn ko si ri bọda naa si.
Ohun gbogbo ti pada bọ sipo bayii, ko si wahala kankan mọ, awọn osisẹ wa si wa lẹnu isẹ wọn wamu-wamu,"




















