Yoruba Nation: Gani Adams tẹnumọ pé àwọn àjìjàgbara kan tí gba owó lọ́wọ́ olóṣèlú

Yoruba nation

Ẹgbẹ OPC, igun ti New Era ti ni ki Aarẹ Ọna Kakanfo, Iba Gani Adams darukọ awọn to fẹsun kan pe wọn ti dalẹ ijijagbara fun Yoruba Nation, lara awọn ti wọn jọ korapọ.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ OPC New Era ni orilẹede Naijiria, Shina Akinpelu lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba sọrọ ni Gani Adams ko kan le e fi ẹsun kan awọn eniyan lai darukọ wọn.

Akinpelu ni yoo jasi pe irọ n parọ fun irọ ni ọrọ Gani Adams nitori ẹni ti ọrọ ba da loju yoo sọ otitọ, ki wọn le fi oju awọn ẹni ibi han laarin wọn.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn naa mọ wi pe kii se gbogbo awọn to n ba awọn rin, lo n ja fun ẹtọ awọn Yoruba nitori awọn oloṣelu naa wa ni aarin awọn.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Elites Media

''Ọga mi ni aarẹ ọna Kakanfọ ni nkan bi ọdun diẹ ṣẹyin, ki n to pada lẹyin rẹ, amọ aarẹ ọna kakanfo mi ni bayii''

''Nitori naa ko si ija laarin Sunday Igboho ati Gani Adams , nkan kan naa ni wọn n ja fun''

''Awọn oloṣelu ati awọn oniroyin ofege lo fẹ da ija silẹ laarin awọn mejeeji, ifẹ ara ilu ni wọn n ja fun ati ki ilẹ Yoruba le e ni ilọsiwaju''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni agbẹnusọ ẹgbẹ OPC naa kilọ fun awọn oloṣelu wi pe, ti wọn ko ba fẹ ijijagbara fun Yoruba Nation, ki wọn fi owo wọn pamọ.

O ni ko yẹ ki wọn fi owo da awọn ajijagbara lẹkun, nitori idajọ n bọ ni ori wọn.

Yoruba nation

Shina Akinpelu ni o ti han gbangba pe sasa ni awọn eniyan to fẹran ilẹ Yoruba denudenu, amọ nkan ti wọn fẹ jẹ, ni ko jẹ ki wọn gbadun.

O wa kesi awọn ajijagbara lati tẹsiwaju nitori ọjọ ọla a dara fun ilẹ Yoruba, ti ọwọ wọn yoo si tẹ gbogbo nkan ti wọn ba n wa, to fi mọ ''Oodua Nation''.

Amin iyasọtọ kan

Ẹri to daju wa pe awọn ajijagbara kan ti gba owo lọwọ awọn oloṣelu lati tabuku ''Oodua Nation'' - Gani Adams

Agbẹnusọ fun Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Ọgbẹni Kehinde ti sọ fun BBC Yoruba pe Aarẹ Gani Adams ko ni ko ọrọ rẹ jẹ.

Kehinde ni lootọ lo daju pe awọn ẹni ibi ti wọ aarin awọn ajijagbara fun Yoruba Nation.

O fikun pe Gani Adams ni ẹri to daju nilẹ, ki o to fi ẹsun naa sita lati pe akiyesi awọn eniyan si bo ṣe nlọ.

Bakan naa lo fikun pe, awọn oloṣelu to fẹ du ipo ni ọdun 2023 ni wọn ti bẹrẹ si ni fun awọn eniyan lowo, lati tẹnbẹlu ijijagbara fun Yoruba Nation.

''Ẹ ma gba awọn oloṣelu laaye lati da aarin wa ru nitori wọn ko ni ifẹ araalu, ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa kiri.

Ni oju awọn oloṣelu, idibo ọdun 2023 dabi ẹni wi pe ọla ni yoo waye, nitori naa wọn ti n sa gbogbo ipa wọn lati da ijijagbara Yoruba Nation ru.''

O fikun pe ikilọ ni Gani Adams fi lede fun awọn ajijagbara, ki wọn ma fi ọkan tan awọn oloṣelu nitori ọna ati da ijijagbara Yoruba Nation ru ni wọn n wa.

Amin iyasọtọ kan

Ọjọ́ méje ni màá fi ṣépè fáwọn ọ̀dàlẹ̀ inú ìjìjàgbara fún Yoruba Nation - Gani Adams

Aarẹ Gani Adams
Àkọlé àwòrán, Awọn darandaran ti sekupa ogunlọgọ eniyan lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Ààrẹ Ọ̀nà Kàkàǹfò fún ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ni àwọn ogbontarigi olóṣèlú kan ni ìhà gúúsù ìwọ oòrùn, tí rápálá wọ ìjàgbara fun idasilẹ orilẹede Yorùbá.

Ààrẹ Ọ̀nà kakanfo ṣàlàyé pé, ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Yorùbá ni láti pé fún Oodua Republic, ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé pé àwọn olóṣèlú kan tí ja gbà, pàápàá jùlọ ni ìhà gúúsù ìwọ̀oorun.

Iba wa nàka àléébù sì àwọn olóṣèlú kan lásìkò ìpàdé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tó wáyé ní Ikeja nípìnlẹ̀ Eko.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

O ní àwọn olóṣèlú ọ̀hún ni a lè pè ní ọ̀dalẹ̀ àwọn ọmọ Yorùbá.

Gani Adams fikun pe "ó ṣe ni laanu pé àwọn kan ti pinnu nínú ọkàn wọn láti dá omi tútù sì ọkàn àwọn tó ń jijàgbara.

Àkọlé fídíò, Gani Adams: Ẹniyan ma n ra aye gbe ni

Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láti bí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ àti àwọn olóṣèlú tí já ìjàgbara náà gbà, ti àṣeyọrí rẹ kò sì dájú mọ.

Ó jẹ́ ọ̀nà láti da omi tútù sí ni lọ́kàn kúrò nínú àfojúsùn tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ṣùgbọ́n mo n sọ báyìí pé ojúlówó ẹ̀tọ́ ni láti bèèrè fún orile-ede ara ẹni, tí a sì ti pinu láti torí rẹ kú, ààrẹ kò ní mú wa lati gba àwọn ènìyàn wá là lọ́wọ́ ìnira.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣùgbọ́n láti jẹ́ kí èyí wá sí ìmúṣẹ, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ, pé ó ṣe pàtàkì láti kíyèsí àwọn nǹkan mẹta.

A gbọ́dọ̀ fi ọgbọ́n inú ṣe é, a gbọ́dọ̀ mọ bí a ó ṣe máa gbọ bí nǹkan ṣe ń lọ láyìíká wá, ń ó fi ìkẹta pam ọ sọ́dọ̀ mi náà."

Àkọlé fídíò, Atunto Naijiria la n fẹ - Aarẹ Onakakanfo, Gani Adams

Iba Adams wá sepe fún gbogbo àwọn tí wọn dáná ọ̀tẹ̀ àti ìjà ni ilẹ Yorùbá pàápàá julọ laarin awọn ti wọ́n ń pè fún O'odua Republic.

O fi kún pé ọjọ́ méje gbáko ni òun yóò fi máa ṣépè fun awọn adarugudu silẹ naa.