Gani Adams: Ìbátan ní Benin àti Yorùbá, a fẹ́ràn ara wa dénú

Gani Adams

Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams, ti gboriyin fun Ọ̣ba ilu Benin, Oba Ewuare II, fun ṣ̣iṣe ayẹyẹ ọdun Ọ̣ranmiyan ni ilu Benin.

Ninu atẹjade ti Gani Adams fi lede lo ti sọ pe, inu oun dun pe Ọba Benin ko fa sẹyin lati fi ajumọṣe to wa ninu itan Yoruba ati ilu Benin han nipa ọdun Ọranmiyan.

O ni ọdun naa ti fi ibaṣepọ to wa laaarin ilẹ Yoruba ati ilu Benin han, ti ko si le si ohunkohun to le ja okun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gani Adams ni Ọba Ewuare ti fihan pe, itan ko parọ lori bi ilẹ Yoruba ṣe san wa ati bi awọn ara Benin ṣe ṣẹ wa gẹgẹ bi itan ṣe sọ.

''Ninu itan ilẹ Yoruba, Ọranmiyan ni o da ilẹ Ọyọ silẹ, ti awọn pe ni Ọranmiyan to tunmọ si Akin Orun, lẹyin to da ilẹ Ọyọ silẹ tan, lo si pada wa jẹ ọba kẹfa, iyẹn Ọọni ti Ile Ifẹ.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Titi di oni, Alaafin ti ilu Ọyọ lo di ipo Ọranmiyan mu ni ilẹ Yoruba, ti awọn ara ilu Ọyọ ati Ọba Lamidi Adeyemi to jẹ Alaafin ti ilu Ọyọ si n ṣe ọdun Ọranmiyan naa ni ọdọọdun.

Ilẹ Yoruba ati ilu Benin ni itan kan naa ati ajọṣepọ kan naa paapaa nipa Ọranmiyan to da ilu mejeeji.

Nitori naa, o pọn dandan fun wa lati ki Ọba Ewuare ku ọdun ati lati gboriyin fun un lori igboya rẹ lati tẹle itan ilu naa"

Àkọlé fídíò, Epe Fish Market: Wá wo oríṣi ẹja tí o rírí lọ́jà ẹja tó tóbi jùlọ ní Nàíjíríà

Aarẹ Ọna Kakanfo naa wa fikun wi pe ibaṣepọ laarin ilẹ Yoruba ati ilu Benin yoo ma lọ deede, nitori ibatan ni wọn, ti wọn si fẹran ara wọn denu.