Iskilu Wakili arrest: Seriki Igangan kàn ń ṣe aláróbọ̀ ni, Wakili gan ní ọ̀gá ńla wọn - Gani Adams
"Ko si ọba to wa ni Ibarapa ti ko bẹru Wakili".
Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti ba sọrọ lori bi wọn ṣe mu afurasi igara apaayan to tun jẹ olori awọn Fulani, Iskilu Wakili.
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Bí ìjọba, ọlọ́pàá, ológun, Amotekun ò bá le gbà wá, àwa mú Wakili láti gba ìran Yorùbá sílẹ̀ ni - OPC
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, afurasí Balógun Fulani tí OPC mú ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ
- Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii
Laipẹ yii ni awọn fidio kan jade lori ayelujara to n ṣafihan bi awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ṣe lọ mu Wakili eleyi ti awọn ọlọpaa si mu àwọn OPC ọhun gangan wọn, gba Wakili lọwọ wọn wọn si gbe e lọ si ile iwosan lori aridaju pe o wa ni ailera.
Ẹwẹ nigba ti Oloye Gani Adams n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni bo tilẹ jẹ pe ilu Eko ni oun wa kii ṣe ibi ti Wakili wa, gbogbo iroyin tawọn n gbọ fihan pe Wakili kan n dibọn lasan ni.
Gani Adams sọ ọrọ o kunlẹ nipa oniruuru alaye nipa ẹni ti Wakili jẹ.

