Iskilu Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje

Oríṣun àwòrán, Topnaija
L'ọjọ Aje ni Isikilu Wakili, ẹni ti wọn fi ẹsun kan lori i ijinigbe to n waye ni ilu Ayetẹ n'ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa ipinlẹ Ọyọ ṣe alaye ohun ti oju ẹ ri lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC yawọ ibi ti o sọ pe oun dubulẹ aisan si.
Wakili ṣe alaye fun awọn oniroyin niluu Ibadan wi pe oun ṣaisan, bẹẹ sini oun lọ gba itọju ni ilu kan ti wọn pe ni Iparaku.
Baba arugbo naa ṣe alaye wi pe ara oun ko mokun lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa de si ibugbe oun pẹlu alaye wi pe awọn obinrin kan to wa pẹlu oun lasiko naa lo ta oun ni olobo.
O ni, "Ara mi ko ya nitori mo ṣẹṣẹ ti ilu Benin republic de ni. Ibi ti mo dubulẹ si ninu ahere mi ni mo ti gbọ ariwo wi pe awọn Amọtẹkun n dira ogun bọ, ṣugbọn mi o le sare nitori ilẹra mi.
Eyii lo mu ki n sọ fun awọn eeyan to n bẹ layika mi lati sa asala fun ẹmi wọn. Wọn mu mi, wọn si wọ mi lọ si agọ ọlọpaa ni Igboọra ki wọn to gbe mi wa si Ibadan."
Wakili fi ẹsun kan wi pe wọn dana sun ile oun bẹẹ sini wọn ṣekupa arabinrin kan nibẹ.
O ni oun ṣetan lati lọ si ibikibi nitori oun ko mọ nnkan nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan oun lori ijinigbe ati iṣekupani.
O ni, "Awọn ajinigbe ti ji awọn ọmọ mi naa gbe ri, ti mo si san ọpọlọpọ milliọnu naira ki n to ri wọn gba pada."
Ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin naa tẹpẹlẹ mọ wi pe oun ko ni akọsilẹ buburu kan, bẹẹ sini oun ko hu iwa ọdaran kankan ri. O ni ki ẹnikẹni ti o ba ni ẹri kan nipa iwa buburu ti oun hu ki o jade wa sọ.


















