Kwara Hijab Crisis: Ìjọbá ńi akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Mùṣùlùmí le lo ìbòrí gẹ́gẹ́ bó ṣe ń wáyé l‘Eko, Osun, Oyo

Aworan ileewe Kristẹni ni Kwara

Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe kawọn ileewe mẹwa to gbe ti pa tẹlẹ nitori aawọ lilo Hijab di sisi pada.

Atẹjade kan tijọba fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe bi ijọba se fọwọsi ilana pe akẹkọọbinrin to ba nifẹ lati lo Hijab lawọn ileẹkọ ijọba le lo yoo mu ki alaafia jọba, ti ibagbepọ alaafia yoo si wa.

"Igbesẹ alaafia ta gbe yii yoo mu ibọwọfunraẹni, agbọye ati alaafia pada sawọn ileẹkọ, paapaa niwọn igba ti ẹkun ariwa Naijiria ati ọpọ ipinlẹ lẹkun iwọ oorun guusu bii Eko, Osun, Ekiti ati Oyo ti fara mọ pe kawọn akẹkọbinrin maa lo Hijab."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Nibayii tawọn akẹkọ n wọle pada si kilaasi, ijọba n sakiyesi isoro ti ọpọ awọn akẹkọjade to fẹ sedanwo WAEC n koju.

hijabi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

A si ti pasẹ pe kawọn ile ẹkọ ti wọn ti pa tẹlẹ naa maa se afikun lẹsinni wakati meji fawọn akẹkọjade naa lẹyin ti akoko eto ẹkọ ba pari lojoojumọ, tijọba yoo si tun pese ipanu fun wọn."

Ijọba ipinlẹ Kwara wa gbosuba fawọn asaaju Kristiẹni ati Musulumi fun agbọye wọn ati aayan lati jẹ ki alaafia jọba lagbegbe wọn lati ọsẹ diẹ sẹyin ti rogbodiyan naa ti bẹrẹ.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé owó orí ni wọ́n fi n san owó oṣù àwọn olùkọ́ ilé ìwé náà, àwọn ọmọ lẹ́tọ̀ọ́- IEDPU

Ileewe C&S Ilorin

Gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ kan nípìnlẹ̀ Kwwara lo ti n sọ ìwòyè wọ́n lórí rúkèrúdò tó n wáye ní ìpínlẹ̀ Kwara

Sáájú ni égbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kriténi ti sọ èrò wọ́n, bákan náà ni BBC Yoruba bá akọwé ẹgbẹ́ IEDPU nílùú Ilorin sọ̀rọ̀

Ìhà wo ni ẹgbẹ́ Idagbásòkè àti ìtẹ̀síwájú Ilorin (IEDPU) kọ sí ọ̀rọ̀ Hijab Kwara

Lásìkò tó n bá wá sọ̀rọ̀ ó sàlàyé pé ìgbésẹ̀ ìjọba tọ̀nà ó sì bá òfin mú, nítorí pé kò sí ǹkan tó tako òfin nínú ǹkan to ti n wáyé tẹ́lẹ̀.

O ní gbogbo eniyan lo ni ẹtọ lati peju si ibikibi ninu awujọ gẹ́gẹ́ bi ofin se sọ.

Ẹtọ ọmọ Musulumi ni lati lo Hijab nítori ilana lati sin ẹsin to wú wọ́n jẹ́ ọkan lara ẹtọ ọmọniyan, bákan náà ni wọ́n le wọ irú asọ to bá wù wọ́n.

Ọjọgbọn Oba Abdulhamid salaye pe ti eniyan ba ti wa ni iru ẹtọ yii, gbogbo ibi to ba ti jẹ ìta gbpangba ni, wọn lẹtọ lati wọ ibẹ̀.

"Àwọn ilé iwé yìí owó ori ni wọn fi n san owo àwọn olùkọ tó wà nibẹ, nítori naa nkan ijọba ni." Ọ̀rọ̀ Hijab kìí se ǹkan tuntun n\itori náà kò yẹ kí ó jẹ́ ǹkan ti yóò maa dí ọja ọla àwọn ọmọ lọ́wọ́

Kwara Hijab Crisis: Ó jọ bí ẹni pe ọ̀rọ̀ Hijab ní Kwara ti lọ́wọ́ òṣèlú nínú- IEDPU

Oríṣun àwòrán, IEDPU

"Ẹlẹ́sìn méjèèjì ló ti jọ n gbé pọ̀ lálàfíà láti ẹ̀yìn wá tí kò sì sí wàhálà, "láyèé ti ọ̀pọ̀ ń sáré láti gbé àwọn ǹkan mere mere ṣe yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹsin ló yẹ lásìkò yìí"

Ọ̀jọ̀gban náà ni kò pé kí ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ máa dá wà pàápàá jùlọ ni àwọn ilé iwé, ó sọ èyí nítorí àwọn tó n sọ pé ki àwọn tó bá jk musùlùmí máa lọ sí ilé ìwé tí Musulumi bá dá síll kí àwọn Kiristẹ́nì sì má lọ sí ibi tí wọ́n.

Ó ní ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ náà mọ bi à ti 'se n gbépọ̀ láti àsìkò yìí kìí ṣe ìgbà ti wọ́n bá dàgbà tan ni wan yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa gbìyànjú láti bárawọn ṣe. A ni ǹkan ti a fẹ́ kọ́ lọ́dọ̀ ara wa.

"Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ọmọ mi Janet ni orúkọ rẹ̀, emi funra mi a ma bá pé ó sì má n wá sí ilé wa" bí ó ṣe yẹ kí o rí níyẹ̀n.

Ó wá sàlàyé pé, tí àwọn kristẹni bá le gba àwọn ilé ìwé yìí padà lọ́wọ́ ìjọba, ìgbà yẹ ni yóò se gbọ́ nítorí wọ́n le gbé òfin kalẹ̀. Sùgbọ́n títí dí àsìkò yìí, àti ìjọba apapọ àti tí ìpínlẹ̀ kò sí ẹni tó dáhun láti dá ilé ìwé padà fún wọ́n.

IEDPU jẹ́ ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè , ibásepọ àti ìrẹ́pọ̀ ọmọ bíbí ìlú Ilorin to wà ni ìjọba ìbílẹ̀ márùn ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Kwara Hijab Crisis: Báyìí ni àwọn ilẹkùn àwọn iléèwé gírámà Kwara mẹ́wàá ṣe tìpa lórí wíwọ Hijab

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni ipinlẹ Kwara ti fesi si bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan se pejọ si ileewe ti ijọba Kwara sọ pe ko wa ni titi pa nitori wahala wiwọ Hijab.

CAN sọ pe ko si ohun to buru ti ẹnikẹni ba fi ẹhonu han lori lilo Hijab paapa lawọn ileewe Kristẹni nitori ofin faye gba iwọde.

Ẹgbẹ naa sọ pe lopin igba ti ko ba ti mu ija wa ko saburu nibẹ. Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba BBC Yoruba sọrọ lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Aposteeli Sina Ibiyemi to jẹ oludari eto ofin f'ẹgbẹ CAN Kwara ṣalaye pe awọn ko ni ki eeyan kankan ma ṣẹsin tirẹ.

O ni awọn ko ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni fa ọrọ yi ati pe nkan meji pere lawọn fẹ.

Akọkọ, ki ijọba Kwara da ileewe ti wọn gba lọwọ awọn pada ki awọn eeyan si maa lo Hijab nileewe awọn.

''Awọn eeyan kan lo fẹ funkun mọ Gomina ki wọn fi le fofin lilo Hijab lawọn ileewe rinlẹ mọ wa lori.''

Aworan ileewe Kristẹni ni Kwara

O tẹsiwaju pe bi ijọba ti ṣe ti awọn ileewe yi pa, alaafia ni wọn wa ṣugbọn ki wọn ṣe ohun to ba tọ ki alaafia le jọba.

Ibiyemi tẹsiwaju pe olu ilu ipinlẹ Kwara kii ṣe ti ẹnikan nitori naa ko yẹ ki awọn kan maa jẹ gaba lori awọn araalu to ku.

''Ijọba ni lati sayẹwo ẹtọ gbogbo eeyan nipinlẹ yi, ẹnikẹni to ba fẹ ki awọn ọmọ wọn lo Hijab nileewe, ki wọn gbe wọn lọ si Mọdirasa tabi awọn ileewe ti musulumi ba da ni''

Akọroyin BBC to kaakiri awọn ileewe ti ijọba tipa jabọ pe titi pa lawọn ileewe naa wa.

Yatọ si ni ileewe Baptist Secondary School ti awọn kan ti dana sun taya, pupọ awọn ileewe yi ni o wa ni titi pa ti ko si si wahala kankan.

Ẹnu ibode ileewe Ilorin

Báyìí ni ẹgbẹ́ àwọn Krìstẹ́nì ṣe yarí mọ́ ìjọba Kwara lọ́wọ́ lórí òfin wíwọ Hijab láwọn iléèwé Girama

Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe awọn ileẹkọ ti wọn gbe ti pa nitori wahala lilo Hijab yoo ṣi wa bẹẹ nitori aabo.

Ileeṣẹ eto ẹkọ ipinlẹ naa lo fi atẹjade sita lọjọ Aiku.

Ninu atẹjade ọhun ti arabinrin Kemi Adeosun to jẹ akọwe agba buwọlu, wọn ni awọn gbe igbesẹ naa nitori aabo.

Ẹnu ibode ileewe Ilorin
Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹjọ oṣu Kẹta lo yẹ ki wọn ṣi awọn ileewe girama mẹwaa yi pada.

Wahala ọrọ Hijab yi ti n rugbo bọ o to ọjọ mẹta ki ijọba to wa kede pe ki wọn ti awọn ileewe mẹwaa kan ti awọn Kristẹni sọ pe awọn lawọn n ṣe akoso wọn.

Àkọlé fídíò, Mina la voilée, olorin to tun jẹ ajafẹtọ obinri

Lọjọ kọkandilogun Osu keji ni wọn gbe aṣẹ yi jade nitori iwọde tawọn akẹkọọ ati ẹgbẹ musulumi kan ṣe pe awọn alakoso ileewe naa ko jẹ ki awọn ọmọbinrin lo Hijab.

Awọn ileewe ti wọn ti pa naa wa bẹẹ ti ijọba si gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣagbeyẹwo ọrọ naa.

  • Orukọ awọn ile ẹkọ naa ni yi:
  • C&S College, Sabo Oke
  • St Anthony College, Offa Road
  • ECWA School, Oja Iya
  • Surulere Baptist School
  • Bishop Smith Secondary School, Agba Dam
  • St Barnabas Secondary School, Sabo Oke
  • St John School, Maraba
  • St Williams Secondary School, Taiwo Isale ati
  • St James Secondary School, Maraba.

Ki lo tẹyin ipade igbimọ naa wa?

Ileewe St. Anthony, Ilorin

Ababọ igbimọ naa ni pe ijọba paṣẹ pe awọn ọmọ musulumi lẹtọ lati lo Hijab ni eyikeyi ileewe nipinlẹ naa.

Ọrọ yi ko dun mọ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN ti wọn si leri pe awọn ko ni gba ki awọn ọmọ musulumi wọ Hijab nile ẹkọ wọn.

Ileewe C&S Ilorin

Kaakiri loju opo Whatsapp ati loju opo ayelujara awọn ikọ mejeeji, musulumi ati Kristẹni ti n leri leka pe awọn ko ni gba.

Pẹlu ohun ti ijọba wa ṣe yi, o daju pe wọn ko fẹ ki wahala bẹ silẹ nigba ti wọn ba ṣi awọn ileewe yi pada ni wọn fi ni ki wọn ṣi wa ni titi pa.