Kabirat Kafidipe Araparegangan sọ ìdí tí 'kò fi lè pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sínú fíìmù mọ́

Oríṣun àwòrán, Mainframe Productions
"Èmi àti Aresejabata, Kunle Afolayan ṣì ń sọ̀rọ̀, ẹ̀gbọ́n ní wọ́n jẹ́ sí mi".
Lara ọrọ gbajugbaja oṣere ti gbogbo awọn ololufẹ fiimu Yoruba fẹran gidi gan amọ ti wọn ko ri mọ rara ninu fiimu, Kabirah Kafidipe niyii.
Kii ṣe pe wọn ko fi bẹẹ ri i mọ ninu awọn fiimu Yoruba amọ ni tirẹ, wọn ko ri i mọ rara ati rara ninu awọn fiimu agbelewo Yoruba ni.
"Eyi lo jẹ ki n ṣe aṣeyọri ninu idanwo ti mo ṣe lati kopa ninu fiimu Ṣaworoide".
Kabirah to ti di Alhaja to re Mecca bọ bayii ni nkankan ṣẹlẹ ninu aye oun ti o pe ni ipe.
"Nigba ti eto aye mi tun n lọ siwaju sii, Ọlọrun tun wa pe mi, tẹẹ ba ri i bi mo ṣe wa, ẹ ma ri i pe mo bo ori".
- Òjò èpè! Tá ló dáa lẹ̀ láàrin Lizzy Anjorin àti Granma Florida, ESABOD tí àṣírí títú yìí ṣe ń gún wọn lára?
- "Mo sá fún oògùn owó, igbó mímu, mo tún ní sùúrù fún ọdún 15 kí n tó di olókìkí"
- A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà
- Ọ̀nà kan dí, ọ̀nà míì ṣí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Imáàmù táwọ́n aláṣẹ́ dá dúró ti ríṣẹ́ míì tó ta lẹ́nu
- Láti 110kg ni mo ti já sí 87kg báyìí, ṣùgbọ́n mí ò ṣáàro ọyàn mi ńla tó dínkù - Ronke Oshodi Oke
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Èmi ní mo fún Afeez Abiodun ní orúkọ 'Ọwọ' tó ń jẹ́ -Yemi My Lover
- Ta ló ní kí Adebimpe Oyebade bóra nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ Nollywood?
Kabirah ni ni ti awọn ololufẹ oun ti wọn n sọ pe awọn ko ri oun mọ ninu fiimu, "ẹ o ri mi pupọ nitori laarin akoko kan mo le sọ wipe Ọlọrun pada pe mi t mo si kọ ẹkọ pupọ".
Gbajugbaja oṣere yii ni oun kii ṣe ẹni to n bori tẹlẹ toun si maa n bi ara rẹ pe nibo lo ti ri ibori kiri. Koda o maa n ya awọn ti wọn jọ n ṣe ere ori itage tẹlẹ lẹnu pe oun ko le ṣi ori silẹ mọ.
"Koda mo ṣẹṣẹ fẹ gbe fiimu tuntun kan sita nigba ti mo gba ipe ni eyi ti mo pe akle rẹ ni Bintu amọ ọrọ fiimu Bintu ti di igba aimọ fun mi bayii".
Arapa ni nitori ipe ti oun pe, oun ko pada gbe fiimu naa jade mọ.
"Lootọ ni ẹ yọlẹ ri mi lori itage ti wọn ti n ṣe fiimu Ayinla Ọmọ Wura ti Baba Tunde Kelani ṣẹṣẹ fẹ gbe jade, mo lọ gba ẹtọ mi gẹgẹ bii ọmọ si baba ni".
Lori bi ede Yoruba ṣe rọrun fun un o ni lati ileewe alakọbẹrẹ loun ti le fi ami sori ọrọ ti wọn kọ oun ti oun si mọ ọ.

Oríṣun àwòrán, Kabirah Kafidipe
Ki ni Arapa-re-gangan n ṣe nibayii?
"Mo ṣẹṣẹ gbe fiimu tuntun kan jade ni to maa jade laipẹ". O ni "a tadi mẹyin ni lati lọ mu agbara wa".
Alhaja Kabirah ni kii ṣe pe oun fi ere ori itage silẹ amọ ni ilana ẹsin Islam ni oun ti gbe gbẹ ori itage tuntun mii sil
O ni o wa lati maa kọ awọn eeyan ni ẹkọ ẹsin Islam nipasẹ ere ori itage.
Ati pe oun ko kabamọ pe oun yẹra fun kikopa ninu fiimu Yoruba pẹlu awọn akgbẹ rẹ to ku. "ko sohun kankan to kere lati yọnda fun Ọlọrun.
Araparegangan ni oun tun ṣe iṣẹ riran ati tita awọn aṣọ asiko.

Oríṣun àwòrán, Mainframe Productions
Ṣé ajọṣepọ to dan mọnran ṣi wa laarin Arapa ati Arẹsẹ ti wọn jọ ṣere ninu Saworoide?
"Ẹẹmẹwaa ni ẹgbọn mi tẹẹ darukọ yẹn maa n ni, iwọ ọmọ yii ki lo n ṣe ẹ, o jẹ lọ yọ gele ẹ yii danu, abi ọkunrin wo lo jẹ koo maa bori yii".
O ni kii ṣe Kunle Afolayan nikan o.
Koda, to fi mọ gbogbo awọn ti awọn jọ maa n ṣere nigba yẹn naa maa n bi oun pe ta lo ran niṣẹ hijab ti oun a si ni "emi kọ, lọrun ni".
Torinaa, Kabirah ni ko si ọrọ ifẹ kankan laarin oun ati Kunle Afolayan rara tori oun tilẹ gbọ awọn ahesọ kan pe Kunle Afolayan ti fẹ oun si Ibadan pe koda oun ti bi ọmọ meji fun un.
O ni gbogbo iru ọrọ bayii ti di mọliki mọ oun lara. "Koda ko sohun to jọ pe emi ati Kunle Afolayan tabi ẹnikẹni fẹnu ko ara wọn lẹnu rara nigba toun ṣi wa ninu ere tiata Yoruba.
"A n ki sira wa lẹyin, a n ba ara wa lajọṣepọ, tabi fẹnu ko ara wa lẹnu ko ba sin tiwa mu rara ati rara, awọn to ba ti nifẹ ara wọn ki wọn lọ fi ara wọn han ki wọn si fẹ ara wọn.
Fun gbogbo awọn to fẹ beere boya Arapa ti wa nile ọkọ, o fi oruka rẹ han gbogbo eeyan bẹẹ si ni o tun jẹ ko di mimọ pe oun ti pe ẹni ogoji ọdun.
Ta ni Tunde Kelani jẹ si Arapa?
"Lati igba ti mo ti n ba Baba TK ṣe ere ni wọn ti jẹ baba si mi, koda awọn ni baba mi ikẹta".
Arapa tẹsiwaju pe awọn ti awọn jọ jẹ ọmọ si Tunde Kelani ṣi n bi baba pe ko jẹ ki oun wa kopa ninu awọn ere rẹ
amọ o ni Baba funrarẹ jẹ ki wọn mọ pe oun ti yọnda Kabirah fun iṣẹ ẹsin ati ipe tuntun to gba tori naa ki wọn ma yọ ọ lẹnu mọ.
Ṣe Arapa naa ti ni ija pẹlu akẹgbẹ rẹ ri gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ lori ayelujara?
"Iwa aburu gbaa ni ki ija maa ṣẹlẹ laarin oṣere meji titi titi yoo tun fi de ori ayelujara". Arapa ni ailoye to lo n da awọn to n ṣe bẹ laamu.

O ni bi wọn mu ẹsin ni pataki ni oye a ye wn pe wn o nilo iwa tẹmbẹlẹkun, owu jij tabi jijẹ ara ẹni lẹsẹ.
Kabirah ni oun ko ni iru iriri yii rara lati igba ti oun ti n ṣere.


















