Lateef Adedimeji: Mo ti gba ₦1,000 péré rí láti kópa nínú fíìmù

Oríṣun àwòrán, @adedimejilateef
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Lateef Adedimeji ti tu pẹrẹpẹrẹ bo ṣe kọ ẹyin si oogun owo, igbo mimu atawọn iwa ipa mii to si rọju fun nnkan bii ọdun marundinlogun ki okiki rẹ to tan kari aye.
Adedimeji lo fi ọrọ naa lede lasiko to n sọrọ nibi idanilẹkọọ Ramadan kan to waye ni gbagede ileeṣẹ iroyin NTA Channel 10.
Nigba to n sọrọ nipa idagbasoke awọn ọdọ, Adedimeji to jẹ oṣere ati olukọ ẹsin Musulumi gba awọn ọdọ nimọran lati ma ṣe kọ Ọlọrun silẹ ninu ilepa wọn fun aṣeyọri.
- A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà
- Ìjọba pàṣẹ fún àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti fi òfin de ìpè lórí fóònù àwọn tí kò so NIN mọ́ nọ́mbà wọn
- Ó bọ́ mọ́ Wizkid, Femi Kuti, Burna Boy lọ́wọ́ ní Grammy Awards, wo àwọn tí wọ́n jọ figagbága
- Hafsat Abiola-Costello, o tàbùku àwa táa dìbò fún bàbá rẹ̀ pẹ̀lú bóo ṣé ṣàfiwé Yahaya Bello àti MKO
- 'Àwọn tó yẹ kó yan olùdíje ipò Soun ní ìdílé wa ti fi òjóró bọ̀ọ́, wọn kọ̀ láti fún Oyebode Oyetunde ní fọ́ọ̀mù'
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni, tí ẹnì kan bá sọ pé òun le dá yanjú ìṣòro ètò ààbò ní Naijiria báyìí - Obasanjo
- Bàbá wọ̀ gàù lórí ẹ̀sùn pé ó fún ọmọbínrín rẹ̀ lóyún, ó tún ṣẹ́yún fún un!
- Mi ò tíì lè sọ bóyá ètò ìdìbò ọdún 2023 yóò wáyé - Adeboye
- NDLEA gbẹ́sẹ̀lé Tramadol tí iye rẹ̀ lé ní ₦5b, ọwọ́ tẹ àwọn afurasí
O ni ikoro ni yoo gbẹyin awọn ọdọ to n ṣe oogun owo.
Adedimeji sọ pe "Ọpọ awọn ọdọ to ni okun bii temi bayii lo n ṣe oogun owo laye ode oni."
"Omugọ nikan ni ko ni ṣiṣẹ ti yoo si maa reti owo... Awọn baba kan nibikan yoo sọ fun yin pe ki ẹ po awọn nnkankan pọ lọna ati lowo, iya ni yoo gbẹyin rẹ o."
"Mi o ni okiki ti mo ni loni yii titi di ẹyin ọdun marundinlogun ti mo ti n ṣe iṣẹ tiata, emi na iba ti ṣe awọn nnkankan ti ko ṣee fẹnusọ amọ mo kọ lati ṣe bẹẹ nitori mo ni imọ."
"Lọdun naa lọhun, mo ri awọn ti a jọjọ bẹrẹ ti wọn di gbajumọ ṣaaju mi, ti mo ba jẹ ẹni ti ko ni oye ni, ni ṣe ni mo maa lọ ba wọn fun iranlọwọ."
"Amọ kaka ki n ṣe bẹẹ, ni ṣe ni mo lọ ba afaa mi, ti mo si sọ fun pe adura mi ko tii gba, ṣugbọn o ni ki n ni suuru pe akoko temi yoo de."
Mo ti gba 1,000 lati ṣe fiimu ri
Adedimeji sọ siwaju si pe wọn ti san ẹgbẹrun kan naira fun oun ri lati kopa ninu fiimu, ti oun si lo ọjọ mẹwaa gbako ni ibi ti wọn ya fiimu ọhun.
O fi kun pe adura oun ti gba bayii nitori owo gọbọi ni oun n gba lati kopa ninu sinima.
Oṣere naa pari ọrọ rẹ pe adura oun gba nitori oun duro ti Ọlọrun dipo ki oun maa fa igbo gẹgẹ bii awọn kan ṣe gba oun niyanju lakoko naa lọhun, bẹẹ si ni oun kọ lati da ọgbọn si ṣugbọn oun duro de akoko Ọlọrun.

















