Lagos Rape: Bàbá fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fún ọmọbínrín rẹ̀ lóyún, ó tún ṣẹ́yún fún un!

Ọmọde kan ni India

Oríṣun àwòrán, iStock

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fẹsun kan ọkunrin kan, Akin Isaac loi ẹsun pe o fun ọmọbinrin rẹ ẹni ogun ọdun ni oyun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko tan sibẹ o, niṣe ni baba arabinrin naa tun fi ipa ṣẹ oyun naa fun ọmọ rẹ.

Wọn ni asiko isemọle to waye nigba ti ajakalẹ arun Coronavirus n ja ranyin ni Naijiria ni iṣẹlẹ naa waye ni ọdun 2020.

Agbẹjọro ijọba, Y.A Alebiosu ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọmọbinrin naa wa nigba ti baba rẹ fun ni oyun.

''Ọmọdebinrin yii n gbe pẹlu iya rẹ agba ni ki baba rẹ to kan an ni ipa fun lati kuro nibẹ wa maa gbe ni ọdọ rẹ.''

"Ọmọbinrin naa sọ fun ileẹjọ pe kete ti oun pada si ile baba oun to ti ni iyawo meji lo ti bẹrẹ si ni fi ọwọ kan oun ni ọna aitọ."

Aworan ọmọde ti wọn ba lopọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀mọbinrin naa ni ẹru ba oun ti o si bẹ baba rẹ ko fi silẹ amọ o lọ ra ẹgba to si ma fi n na oun lati fi ipa ba oun lopọ."

Bakan naa ni o fikun un pe baba oun dunkoko mọ oun wi pe ti oun ba sọ fun ẹnikẹni oun yoo gba ẹmi oun.

Lẹyin ọpọlọpọ ifipabanilopọ ni ọmọ naa ri pe oun ko ri nkan osu rẹ mọ, ti o si sọ fun ọrẹ rẹ obinrin to mu u lọ si ọdọ nọọsi to sọ fun pe o ti loyun.

Amọ o ni baba rẹ gbe e lọ si ibi kan ti ko si ina ijọba, ti wọn si yọ oyun naa fun.

Nibayii, adajọ ti sun igbẹjọ naa di Ọjọ Kẹtala, Osu Kẹrin, ọdun 2022.