Cubana Chief Priest: Ìdí tí àjọ EFCC fi gbé Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@CUBANA_CHIEFPRIEST
Iroyin to n tẹ wa lọ́wọ́ ni pe ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC ti fi panpẹ ofin mu gbajumọ olowo nni, Pascal Okechukwu ti ọpọ mọ si Cubana Chief Priest.
Ajọ EFCC fi ofin gbe Cubana lori ẹsun to nii ṣe pẹlu lilu owo ilu ni ponpo ati ọrọ owo ori gẹgẹ bi awọn oniroyin ṣe jabọ rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin to n fo kiri, ajọ EFCC gbaa mu ni papakọ ofurufu ni Eko l'Ọjọbọ ṣugbọn wọn ko fihan sita fun awọn eeyan paapaa tori awọn mọlẹbi atawọn ojulumọ rẹ to fi di pe ọr naa fẹ le sii fun awọn mii ti ọrọ naa tun lọ mọ lẹsẹ.
Gbogbo igbiyanju lati gbọ latẹnu agbẹnusọ ajọ EFCC, pabo lo jasi tori naa a ko tii le fi idaniloju rẹ han.
Bakan na, Cubana Chief Priest funra rẹ ko tii kọ ohunkohun soju opo ayelujara rẹ latigba ti iroyin pe EFCC gbe e jade.
Ta ni olowo yii, Cubana Chief Priest gan?

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@CUBANA_CHIEFPRIEST
Orukọ Cubana Chief Priest gangan ni Pascal Chibuike Okechukwu amọ oun funrarẹ maa n pe ara rẹ ni Cerebral barman.
Oniṣowo ni to si ni idokoowo pupọ lagbo awọn olorin, oṣere ati onigbajumọ.
Oun lo ni Club Xhrine to wa ni Omerri, ipinlẹ Imo.
Iṣẹ So-bata lo kọkọ kọ nigba to n dagba gẹgẹ bi abikeji awọn obi rẹ ni ilu Aba ipinlẹ Abia.
Nigba to ya ni Cubana lọ ka iwe sii ni ile ẹkọ giga gbogboniṣe Nekede, Owerri nibi to ti kawe gboye fun igba akọkọ.
Lọdun 2021, o kẹkọ gba imọ oye Ọmọwe ni Fasiti European American university.
Pascal Chibuike Okechukwu ti ọpọ mọ si Cubana Chief Priest ni iyawo o si ni ọmọ.















