Akẹ́kọ̀ọ́ rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he lẹ́yìn tó ná $1m tó ṣèèṣì wọ àpò àsùnwọ̀n rẹ̀

Sibongile Mani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin ọmọ orilẹ-ede South Africa kan ti di eero ẹwọn bayii lẹyin to na lara owo to to miliọnu kan Dọla to ṣeeṣi wọ apo asunwọn rẹ.

Ẹgbẹrun kan ati irinwo owo Rand t ti ijọba orilẹ-ede naa ma n fun loṣooṣu gẹgẹ bi akẹkọọ lo yẹ ko wọ apo asunwọn rẹ, ṣugbọn miliọnu mẹrinla Rand lo wọle, to si bẹrẹ si ni na owo naa lẹsẹkẹsẹ.

Iroyin sọ pe ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2017, lasiko to fi jẹ akẹkọọ ni Fasiti Walter Sisulu, ni ajọ to n mojuto iranlọwọ fun awọn akẹkọọ, National Student Financial Aid Scheme (NSFAS) , ṣeeṣi fi owo naa ranṣẹ si.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ
Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Ṣugbọn dipo ki Arabinrin Mani sọ fun ajọ naa pe owo to wọle fun oun pọju iye to jẹ lọ, niṣe lo bẹrẹ si ni na owo laarin wakati meji to gba a.

Nigba ti wọn o si fi gbẹsẹ le apo asunwọn rẹ nile ifowopamọ, o ti na bi ẹgbẹrun lọna aadọrin.

Eyi waye nie itaja mejidinlaadọta jakejado orilẹ-ede naa laarin ọjọ mẹtalelaadọrin.

O ra irun obinrin (weave on), oriṣiriṣi ẹrọ ibanisọrọ, ọti lile, aṣọ ori ibusun, ati awọn nkan olowo iyebiye miran.

Ninu idajọ to ṣe, adajọ ile ẹjọ majisireti to wa ni ẹkun East London, Twanette Oliver, sọ pe manigbagbe ni bi Arabinrin Mani, ṣe na owo naa.

O ni ọpọlọpọ akẹkọọ ni iya o ba jẹ, kani ileeṣẹ to fi owo naa ranṣẹ, IntelliMali, ko ba san owo to na fun wọn ni apo ara rẹ.

Adajọ naa sọ pe kii ṣe aini tabi òṣì lo mu ko ṣe bẹẹ, biko ṣe ojukokoro.

Ṣugbọn ṣa, ọpọ ọmọ orilẹ-ede South Africa lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu idajọ ẹwọn ọdun marun-un ti adajọ fun Mani.

Wọn ni ileeṣẹ to ṣeeṣi san owo naa lo yẹ ki ijọba da lẹbi.

Bẹẹni awọn kan n sọ pe nkan ti Mani ṣe ko buru, nitori pe iṣẹ, iya ati iwa jẹgudu-jẹra pọ lorilẹ-ede naa.