Dejo Tunfulu: Àwọn ọmọ olòógbé ní àwọn dókítà kò kọbi ara sí ìtọ́jú rẹ̀, ló tètè ṣekú pa á

Dejo Tunfulu atawọn ọmọ rẹ

Bi ina ba ku, a fi eeru boju, bi ọgẹdẹ ba ku, yoo fi ọmọ rẹ rọpo, bi oloye ba ku, yoo fi oloye silẹ lọ ni.

Kunle Makinde Adetokunbo, ta tun mọ si Dejo Tunfulu tii se gbajumọ alawada ninu ere tiata to jade laye lọjọ Ẹti, ni wọn ti sin nile rẹ ladugbo Agbowa nilu Ikorodu ni irọlẹ ọjọ naa.

Oloogbe naa si fi ọmọ mẹrin silẹ saye lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Nigba ti BBC Yoruba de ile oloogbe naa, a ba awọn ọmọ to n selede lẹyin rẹ sọrọ, ti wọn si sọ iru ẹda ati baba ti Dejo Tunfulu jẹ si wọn, nigba to wa nile aye.

Akọbi oloogbe naa, Fatai Makinde Adetokunbo Junior salaye pe, oun jẹ ọmọ oniwahala, to maa n yọ baba oun lẹnu pupọ nigba to wa laye.

Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

O ni lọjọ to kẹyin ọdun 2021, ni baba oun pe oun pe ti oun ko ba jẹ ọmọ to daa si oun, ki oun sa daa fun ara oun nitori lẹyin baba oun, oun lo kan gẹgẹ bi akọbi.

"Lati igba yẹn ni mo ti n tiraka lati yi awọn iwa lile mi pada nitori baba to n kara masiki ọmọ nii se.

Kii fi itọju awọn ọmọ rẹ sere, oun nikan si lo da tọju wa, baba daadaa ni.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

Iya wa fi wa silẹ lọ fẹ ọkọ miran, baba wa nikan lo n da tọju wa:

Nigba to n salaye bi Dejo Tunfulu se mu itọju ọmọ lọkunkundun si, akọbi rẹ naa ni kii kuku se pe awọn ko ni iya.

Amọ o ni se ni iya awọn fi awọn silẹ, o kọ baba awọn, to si lọ fẹ ẹlomiran, lati igba naa si ni baba awọn ti n ko ba oju ati imu, lati tọju awọn.

"Tẹ ba mọ aburo mi to jẹ abigbẹyin wa, ọmọ osu mẹjọ ni iya wa gbe silẹ, to fi ba ọkọ mii lọ.

Daddy mi lo maa dana ounjẹ ta jẹ, a maa fun ọmọ kekere naa ni ounjẹ titi to fi dagba.

Bawo ni ko ba se dun to, to ba jẹ pe o duro jẹun ọmọ, ohun to n dun mi, to si n pa mi lẹkun gan ree.

Baba mi ko jẹun ọmọ rara, koda, foonu to sẹsẹ ra fun mi niyi."

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Ti mo ba ri ẹni ran mi lọwọ, maa sisẹ tiata ti baba mi n se:

Fatai Makinde Adetokunbo Junior, ẹni to salaye pe awọn ko fẹ ki orukọ baba awọn parẹ ninu isẹ tiata, wa kede pe oun naa le sere tiata lati mase jẹ ki orukọ Dejo Tunfulu parun.

O ni ti oun ba ri ẹni gbe oun nigbọnwọ, ran oun lọwọ, oun yoo sisẹ tiata daadaa nitori baba oun nigbagbọ ninu oun pe oun le sere tiata daadaa.

"Oju lo maa n ti mi, ara mi ko si balẹ amọ nigba ti baba mi ti ku bayii, mo le sere tiata.

Ti mo ba ri ẹni ti yoo fi mi sinu ere, maa se daadaa.

Baba mi ni ka ma bawọn dokita ile iwosan fa wahala tori bi wọn ko se tọju rẹ daadaa:

Nigba to n sọ fun BBC Yoruba nipa ọrọ ikẹyin ti baba rẹ sọ, ko to mi kanlẹ, Fatai ni ohun to sọ ni pe kawọn mase ba awọn dokita ile iwosan ijọba ni Ikorodu ja.

O ni wọn ko tọju baba oun rara nile iwosan naa, gbogbo ohun ti wọn si ni kawọn se fun itọju wọn, naa lawọn se.

O wa fọwọ gbaya pe awọn osere tiata ti wọn jẹ akẹẹgbẹ baba oun tiraka pupọ, wọn saayan lati tọju rẹ.

"Gbogbo wọn ni wọn dide, mo mọ riri wọn, wọn tiraka agbara wọn lati duro ti baba wa.

Mo ki gbogbo awọn to wa sibi oku baba wa, wọn seun o, a ko ni fi iru rẹ san funra wa.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Sinima baba mi wa nlẹ ti ko tii gbe jade:

Akọbi Dejo Tunfulu naa sisọ loju rẹ pe sinima si wa nilẹ, ti baba oun ti se pari, amọ to ku diẹ ko jade.

O ni baba oun ti ra awọn eroja ere tiata kan silẹ bii ina ati ẹrọ ayaworan.

Ohun to n wu oun bayii ni bi oun yoo se maa jẹ ki ori rẹ wu nibikibi to ba wa, nipa bawọn ti se tun ẹyin rẹ se.

Bawọn dokita ko se tọju baba wa nile iwosan daadaa gan lo seku paa:

BBC Yoruba tun ba ọmọ Dejo Tunfulu lobinrin sọrọ, Pamilerin Adetokunbo ẹni to sisọ loju rẹ nipa bi baba wọn se ku.

O ni aisan iba lo se baba oun, to si jade lọ si igboro ni ọjọru, bo si se de, lo wo lulẹ tori aisan naa.

"A gbe wọn lọ si lọ si ile iwosan ijọba to wa ni Ikorodu amọ wọn ko sa ipa wọn bo se yẹ.

Gbogbo ohun ti wn nilo nile iwosan la pese fun wọn amọ awn osisẹ ibẹ ko kọbi ara si wọn rara.

O fẹrẹ dabi ẹni pe oun to pa wọn gan niyẹn nitori wọn n tọkasi iru abẹrẹ ti wọn fi fa omi si wọn lara.

Gbogbo eroja fun itọju alaisan la ra nibẹ, koda, a sanwo pe baba mi fẹ tọ lasan nibẹ.

Yatọ si pe a sanwo ẹjẹ ti wọn fun baba mi, nigba ti wọn tun ku tan, ile iwosan naa tun gba ẹjẹ lara wa ti ile iwosan naa yoo fi pamọ fun ẹlomiran.

Ile iwosan naa ni ofin awọn ni pe a tun gbọdọ fi ẹjẹ silẹ pada lẹyin ta fi owo ra ẹjẹ tan fun baba wa.

Koda, ka to ri oku baba wa gbe jade nibẹ, oju wa ri to. Wọn tun se ayẹwo oku ni ọna mẹrin, ki wọn to gbe oku wọn fun wa."

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

Igba ikẹyin baba wa:

Pamilerin tun salaye fun BBC Yoruba nipa ọrọ ikẹyin ti baba wọn, Dejo Tunfulu sọ, ko to jade laye.

"Nigba ti Baba wa wa nile iwosan, wọn kan joko sori aga, wọn si sọ fun wa pe ti awọn ba ti gba ẹjẹ yii tan, ki ẹgbọn mi lọ sọ fawọn dokita pe ko fun awọn ni abẹrẹ, ki awọn to sun.

Lootọ lo n pariwo pe ori n fọ oun, paapaa nigba to si wa nile iwosan.

Ma se aaro ohun gbogbo nipa baba mi, awa ọmọ mẹrẹẹrin to bi yoo mọ riri iku rẹ lara.

Were ọlọmọ ni baba mi lootọ, o maa n ko awa ọmọ rẹ kiri ni .

Baba gbogbo aye ni, to si maa n se awada pupọ, wọn kii dibọn amọ bi iwa wọn se ri, ni wọn se n hu u."

Emi ati Dejo Tunfulu jọ wa nibi ọjọ ibi Tinubu lọjọ Isegun ni - Tajudeen Gbadamosi:

Ọkan lara awọn osere tiata to ba BBC Yoruba sọrọ, Tajudeen Gbadamosi ti ọ̀pọ mọ si Coach ninu tiata naa sọrọ nipa iku Dejo Tunfulu.

Coach salaye pe awọn dijọ wa nibi ọjọ ibi agba oselu nilu Eko, Bola Tinubu lọjọ Isẹgun nile Itura Eko Hotel ni.

"Ọmọ to daa, to ni alubarika ni Dejo Tunfulu, ko si ẹni ti ko nifẹ rẹ ninu gbogbo wa, o si wa lọdọ mi lọjọbọ ana.

Kii fun wa ni wahala lagbo tiata, ọmọ jẹjẹ nii, ti kii si fa ijangbọn kankan, mo si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'