Ondo School Bus Fire: Bàbá ọ̀kan lára akẹ́kọ̀ọ́ tó kú ní òun ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà saájú lójúràn, òun sì gbàdúrà si

Meji ninu awọn akẹkọ to wa ninu ọkọ bọọsi ile-iwe to jona lọjọ iṣẹgun nilu Akungba-Akoko nipinlẹ Ondo lo ti padanu ẹmi wọn.
Awọn akẹkọ ọun ti wọn jẹ mọkandinlogoji, ni ẹyọ meji pere ninu wọn, ko ni ipalara kankan ninu ijamba ina naa ni bi wọn ṣe gba oju ferese jade.
Pupọ lara wọn ti ina naa mu kọja ala, ni wọn ko lọ ile iwosan ijọba apapọ to wa nilu Ọwọ, tawọn to ku si n gba itọju nilu Akungba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa Dejo Tunfulu tó jáde láyé
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- Ọ̀rọ̀ Amaechi àti El-Rufai fihàn pé ìjọba lọ́wọ́ nínú ìgbésùnmọ̀mí – PDP
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
- Ìgbésẹ̀ yíyan Olówu di wàhálà, àwọn ìdílé oyè wọ́ ara wọn relé ẹjọ́
- Ọmọ ìjọ kú sí ìpàgọ́ Bíbélì, pásítọ̀ sìnkú rẹ̀ láì sọ fún ẹbí rẹ̀
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
BBc Yoruba de ilu Akungba akoko, nibi ti isẹlẹ naa ti waye, bi eeyan ba si jẹ ori ahun, yoo sunkun nipa ọsẹ ti ijamba naa se.
Ọpọlọpọ awọn idile to ni ọmọ ninu ọkọ ile ẹkọ to jona naa ni ibanujẹ ti gba ọkan wọn, paapaa awọn to padanu ọmọ wọn.
Koda, awọn obi tawọn ọmọ wọn gan fara pa wa ninu iporuru ọkan, ti ohun gbogbo si doju de fun wọn.
Awọn obi tawọn ọmọ wọn fori sọta isẹlẹ naa, to ba BBC Yoruba sọrọ wa n tara poro nipa ipo irora tawọn ọmọde naa wa.

Mo ti ri ijamba ina to pa ọmọ mi tẹlẹ lojuran, mo si ti gbadura si:
Alufa John Oluwaseun, ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ meji to wa ninu ọkọ naa padanu ẹmi rẹ wipe oun nigbagbọ pe amuwa Ọlọrun ni.
Oluwaseun ni oun ti ri ijamba naa lojuran, ti oun si pe fun adura tako irufẹ iṣẹlẹ laabi bẹẹ.
O fikun pe ọmọ oun to jẹ ọmọ ọdun mẹta to padanu ẹmi rẹ lọjọ keji ti wọn gbe de ile iwosan nilu Ọwọ, lakoko ti wọn n gbiyanju lati ṣe iṣẹ abẹ fun, ni wọn ti sinku rẹ.
Ọmọ ọmọ mi mẹrin lo fara pa ninu ijamba bọọsi ileẹkọ to jona, inu iporuru ọna la wa:
Alagba Oloke Festus, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ni mẹrin ninu awọn ọmọ-ọmọ oun lo farapa ninu iṣẹlẹ naa.
O ni oun wa n gbadura kikan kikan wipe ki Ọlọrun mu wọn lara da.
O ṣalaye pe ọkan lara awọn ọmọ naa to farapa julọ wa nile iwosan nilu Ọwọ, tawọn mẹta toku si n gba itọju nilana ibilẹ nilu Akungba.
Alagba Oloke fikun pe ninu iporuuru ọkan ni oun ati awọn mọlẹbi oun wa lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

Asọ awọn akẹkọọ to wa ninu ọkọ naa ti sona, se ni awọ ara wọn n si mọ wa lọwọ:
Omidan Eunice Onigiobi ti iṣẹlẹ naa soju rẹ ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn ara adugbo ni wọn sa gbogbo ipa wọn lati doola ẹmi awọn ọmọde naa.
Onigiobi ni se lawọn fọ awọn ferese ọkọ ọun lati le tete ri awọn ọmọ naa yọ lakoko ti ọkọ ọun n jona bo ṣe jẹ pẹ ọpọ awọn ọmọ naa ni gbogbo aṣọ wọn ti jona, ti ara wọn si n ṣi mọ awọn eeyan lọwọ.
BBC Yoruba kan si ileesẹ ọlọpaa Akungba Akoko nibi ti wọn gbe ajoku ọkọ naa si, a si ri pe gbogbo inu ọkọ ọhun lo fẹ ẹ jona tan.
Koda a foju wa ri diẹ lara bata awọn akẹkọ naa, to si wa ninu mọto naa.
Ọlọpaa ti fi oludasilẹ ile ẹkọ to ni ọkọ to jona naa ati awakọ si ahamọ:
Ẹwẹ, oludasilẹ ileewe ọhun, ọgbẹni Hope Akadiri ati dẹrẹba ọkọ naa ni iwadi fihan pe wọn wa nihamọ awọn agbofinro latigba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.
Alukoro ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ondo, arabirin Funmilayo Odunlami ni irin-ajo rẹ ko jẹ ko le ba ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba sọrọ lakoko abẹwo si ọfiisi rẹ.

Akẹ́kọ̀ọ́ kan kú mẹ́ẹ̀dógún fara pa nígbà tí ọkọ̀ iléẹ̀kọ́ wọ́n gbiná l'Ondo

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe o kere tan, awọn akẹkọọ bii mẹẹdogun lo fara pa yanna yanna, ti ẹmi akẹkọọ kan si bọ sinu isẹlẹ ijamba ina kan to waye nilu Akungba Akoko, nipinlẹ Ondo.
Ijamba ina ọhun waye nigba ti ọkọ ile ẹkọ wọn, to n ko awọn ọmọ naa ninu ile wọn lọ sile ẹkọ, sadede gbina lojiji.
Deede aago mẹjọ aarọ ni isẹlẹ naa waye laarọ ọjọ Isẹgun, orukọ ile ẹkọ to ni ọkọ naa ni Hope of Tomorrow Academy.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìyá kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he nítorí ọrọ̀ ọmọ
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
- Iléèṣẹ́ aṣojú America bẹ̀rẹ ètò físà fún àwọn ọmọ Naijiria láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Kí ló pa dókítà àjọ FIFA tó kú níbí ìdíje Ghana vs Nigeria ní Abuja? Àjọ NFF sọ̀rọ̀
- Portable Zazzu pàdánù eré tó yẹ kó lọ ṣe ní Canada, ìdí rèé
- Ẹ wo orúkọ àti ojú àwọn èèkànlú tó forí sọta ìkọlù rélùwéè àti ipò tí wọn dì mú
- Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ Rahmon Adedoyin tó ní òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
Akẹkọọ̀ọ to jade laye naa ni wọn lo jalaisi nitori pe wọn tete gbe pada lọ sile ni kete ti ijamba naa waye.
Awọn eeyan ti isẹlẹ ijamba ina naa soju wọn ni awakọ mọto naa lo n ko awọn akẹkọọ yii ni ọkọọkan ninu ile wọn.
Amọ wọn ni sadede ni ina sẹyọ lara ọkọ ile ẹkọ naa, ti eefin dudu si gba adugbo ti isẹlẹ ọhun ti waye kan.
Eefin yii gan lo pe akiyesi ọpọ eeyan sibi isẹlẹ naa, ti wọn si ri pe awọn ogo wẹẹrẹ ni isẹlẹ naa kan.
Bi ijamba ina naa si ti bẹrẹ ninu ọkọ ọhun, gbogbo iyanju awọn aladugbo lati silẹkun mọto naa lo ja si pabo nitori wọn ti ti ilkun naa pa mọ awọn akẹkọọ ọhun.
Ọpẹlọpẹ awọn ara adugbo naa to tete fọ gilaasi ẹyin ọkọ naa lati ko awọn akkọ naa sita, bibẹẹkọ ijamba naa ko ba gba ẹmi pupọ lọ.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami ti wa fi idi isẹlẹ naa mulẹ.
Odunlami ni wọn ti ko awọn akẹkọọ to lugbadi ijamba naa lọ sule iwosan fun itọju to peye.



















