Kaduna-Abuja Train Attack: Àwọn aṣòfin ní yóò dáa káwọn dara pọ̀ mọ́ ASUU nínú ìyanṣẹ́lódì torí ọ̀rọ̀ àwọn ti sú aráàlú

Ijoko ile asoju sofin

Nibayii ti eto aabo Naijiria tubọ n dẹnu kọlẹ, awọn ọmọ ile asoju-sofin ti kede pe awọn fẹ dasẹ silẹ titi ti ayipada yoo fi ba eto aabo.

Asofin Aminu Sulaiman Goro tiẹ sọ fun BBC pe loore koore ni awọn n joko sile asoju-sofin, ti awọn si n gba iwe abọ nipa ipo ti eto aabo orilẹede yii wa.

O wa n gbara ta pe ipo ti eto aabo ẹkun ariwa Naijiria wa bayii ti buru jai, to si jẹ pe ko sigba kankan ti awọn kii jiroro lori ọrọ aabo lasiko ijoko ile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan ko le rinrin ajo mọ loju popo, lọna reluwe ati loju ofurufu:

"Ohun ibanujẹ lo jẹ pe lonii, wọn pa awọn eeyan nipakupa ni,lọla, wọn n ji ọgọọrọ eeyan gbe bo se wu wọn ni.

To ba si tun di ni ọtunla, wọn yoo dana sun iye eeyan to ba wu wọn lai si ẹni ti yoo ni wọn.

Awọn iwa ika yii ti wa jẹ ki eto aabo dẹnu kọlẹ tan patapata."

Asofin Aminu Goro fikun pe awọn agbesunmọni yii ti le awọn eeyan tan kuro loju popo, ti wọn si tun ti bẹrẹ si ni yin ado iku sawọn ọkọ reluwe bayii.

Bakan naa lo fikun pe ọrọ naa ko tun yọ papakọ ofurufu sil pẹlu.

"Ohun ti eyi tumọ si ni pe ẹka alasẹ ko mọ ohun ti wn n se.

Gẹgẹ bi asofin, ko si ohunkohun ti ijọba gbe siwaju wa lẹka isuna tabi ofin, ta maa n fi akoko sofo le lori ka to buwọlu.

Amọ kaka ki ewe agbọn eto aabo to mẹhẹ naa dẹ, ko ko ko lo tun n le si.

A si ti n ri pe awọn eeyan ta n soju gan ni ọrọ naa ti su, koda, kii se ijọba nikan ni ọrọ rẹ su wọn, awa gan, ọrọ wa ti su awọn eeyan."

Yoo kuku dara ka ko agbada ati ẹru wa, ka gbọna ile wa lọ:

Asofin Goro ni gbogbo igbesẹ tawọn n gbe ni lati mu ayipada rere ba ipo ti eto aabo wa ni Naijiria kan n dabi ọrọ ‘oun lana, oun loni, bii ẹkun apọkọjẹ’.

"Bi ko ba wa si ohun tuntun ta fẹ se mọ, yoo kuku dara ka ko agbada ati ẹru wa, ka gbọna ile wa lọ, ka si fi agadagodo sẹnu ọna ile asoju-sofin.

A ko si ni pada wa sile asofin titi ti ayipada rere yoo fi ba eto aabo, tawọn agbofinro yoo si wa sọ ohun to n sẹlẹ fun wa.

Amọ to ba jẹ pe wọn ti kuna, ki tun ni wn nilo wa fun, ti wọn yoo fẹ ka se fun wọn?"

Asofin naa wa n gbarata pe awọn mọ nipa awọn igbesẹ kan tijọba n gbe lori eto aabo to mẹhẹ naa nigba ti awọn ko mọ nipa awọn miran.

"Nitori naa, ta ba kuku darapọ mọ ẹgbẹ awọn olukọ fasiti Asuu lẹnu iyansẹlodi wọn, o daa ka kuku se bẹẹ.

Ka gbe ilẹkun ile asoju-sofin ti, titi ti ọkan wa yoo fi balẹ pe aabo wa fawọn araalu ta n soju, ti wọn si ran wa wa sile asoju-sofin."

Ki lo waye sẹyin:

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aje ni awọn agbesunmọmi kọlu ọkọ reluwe to n lọ si Kaduna lati Abuja, eyo to mu ẹmi eeyan mẹjọ lọ.

Ọkọ reluwe maa to ko ero mejidinnirinwo ni awọn eeyan to le ni ogoji ti farapa ninu rẹ.

Isẹlẹ yii lo jẹ akọtun ikọlu tawọn agbebọn se ni Naijiria, ti ọpọ ẹmi awn alaisẹ si n bọ ninu rẹ nigba ti wn tun n ba ọpọ dukia j pẹlu.

Amin iyasọtọ kan

Ọ̀rọ̀ Amaechi àti El-Rufai fihàn pé ìjọba lọ́wọ́ nínú ìgbésùnmọ̀mí - PDP

El-Rufai se abẹwo si ọkan lara awọn eeyan to fara gba ọta ibọn ninu ikọlu reluwe

Oríṣun àwòrán, @elrufai

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti ní ọ̀rọ̀ tí gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai àti èyí tí Mínísítà fétò ìrìnnà, Rotimi Amaechi sọ lórí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe sí ọkọ̀ rélùwéè Kaduna siAbuja, ti fi hàn wí pé ìjọba lọ́wọ́ nínú àwọn ìkọlù tó ń wáyé lórílẹ̀ èdè yìí.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Debo Ologunagba ní gbogbo àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ló mọ̀ nípa èrò àwọn agbéṣùmọ̀mí àti ibi tí wọ́n wà ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà lásìkò.

Bẹẹ ba gbagbe, Amaechi, nígbà tó ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìkọlò náà tí wáyé ní àwọn ti mọ̀ wí pé ìkọlù náà yóò wáyé, amọ̀ awọn nílò ohun èlò ààbò ìgbàlódé, a sì bèèrè fún un ṣùgbọ́n tí wọn kò fún wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní tó bá jẹ́ wí pé ohun èlò ààbò wà nínú ọkọ̀ yẹn ni, kò sí ẹni tó le mọ̀ wí pé ènìyàn wà nínú ọkọ̀ náà àti wí pé òun ti ṣe ìkìlọ̀ pé àwọn ẹ̀mí yóò sùn tí àwọn kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna ní tirẹ̀ ní "a mọ ibi tí àwọn agbéṣùmọ̀mí yìí wà, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní nọ́mbà wọn lọ́wọ́, a mọ̀ ohun tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe, kò yẹ kí a fún wọn láyè láti ṣe ìkọlù ka tó máa sáré lé wọn kiri".

Ologunagba ní pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí àwọn méjéèjì sọ yìí fi hàn pé àwọn adarí APC ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Ìjọba kò náání ẹ̀mí àwọn ará ìlú:

Bákan náà, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní kò ya oun lẹnu pé Ààrẹ Muhammadu Buhari kọ̀ láti dá Mínísítà fọ́rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀, Dókítà Isa Pantami dúró, lẹ́ni tó fẹnu ara rẹ̀ sọ wí pé agbéṣùmọ̀mí ní òun, èyí tó lòdì sí ìwà gbígbógun ti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.

Bẹ́ẹ̀ ló ní ẹ ó rántí wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti pè fún mímú àyípadà bá àwọn adarí ilé iṣẹ́ ètò ìbánisọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí ìjọba kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ náà.

Ologunagba nínú àtẹ̀jáde náà tún tẹ̀síwájú wí pé ìjọba ń fi ọwọ́ bo àwọn òótọ́ mọ́lè tí wọ́n sì ń kojú àwọn ọmọ ogun kọ ewu.

Ó ní èyí sì ń fa bí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí ṣe ń kú ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí nítorí tí ìjọba kò nání ẹ̀mí àwọn ènìyàn.

Ó fi kun wí pé èyí gan ló fà á tí ìjọba fi kọ̀ láti bèèrè tàbí gbà àtìlẹyìn ilẹ̀ òkèrè láti gbógúnti àwọn oníṣẹ́ láabi yìí.

Amin iyasọtọ kan

Ẹ fura o! Ètò ààbò Nàìjíríà ti ń dàbí ti Afghanistan - Afenifere lọgun

Awọn agbebọn ati Papakọ ofurufu Kaduna

Oríṣun àwòrán, FAAN

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ẹgbẹ́ Aferenifere ti se apejuwé báwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ya bo pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Kaduna bíi àmì àpẹẹrẹ pé ètò ààbò Nàìjíríà ti burú kọjá bó ṣe yẹ.

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ọdún 2022 ní àwọn agbéṣùmọ̀mí tó lé ni igba yabo pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Kaduna, níbi ti ènìyàn kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn sì farapa léyìí tó sì tún fa ìdádúró àwọn ọkọ̀ òfurufú.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Jare Ajayi fi síta, ẹgbẹ Afenifere wa kọminú pé àwọn agbéṣùnmọ̀mí lé yabo pápákọ̀ náà ní ọjọ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń ṣe àpérò àpapọ̀ wọn ní ìlú Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajayi ní ó ti wá fojú hàn wí pé àwọn kan ń gbèrò láti sọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dà bíi ti Afghanistan pẹ̀lú gbogbo àwọn ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra.

Ó fi kun pé ohun tó le mú àwọn agbéṣùmọ̀mí ní ìgboyà láti yabo pápákọ̀ òfurufú ní ọ̀sán gangan fi hàn pé ètò ààbò orílẹ̀ èdè yìí ti bàjẹ́ kọjá bó ṣe yẹ pẹ̀lú gbogbo ìdánilójú ti ìjọba àpapọ̀ ń fi ojoojúmọ́ pariwo.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Àtẹ̀jáde náà ni ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn wí pé láàárín ọjọ́ Ẹtì àti Àbámẹ́ta nìkan dàbí ẹni pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà lójú ogun pẹ̀lú gbogbo àwọn ìkọlù tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Niger àti Enugu èyí tó ṣokùnfà pípàdánù àwọn ẹ̀mí àti dúkìá àti fífi tipátipá gba àwọn ohun ìní ẹni.

Ìjọba kò jára mọ́ ètò ẹ̀kọ́:

Afenifere tún ní ìjọba àpapọ̀ kò jára mọ́ bí iná ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀ èdè yìí ṣe ń jó àjórẹ̀yìn pẹ̀lú bó se gbàgbọ́ pé àìmọ̀kan ló jẹ́ ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ gbogbo láàsìgbò tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra.

Agbẹnusọ Afenifere ní ó jẹ́ ohun ìwúrí pé Ààrẹ Buhari gbà pé gbogbo ìpèníjà tó ń kojú Nàìjíríà jẹ́ nítorí ètò ẹ̀kọ́ tí kò mọ́yán lórí síbẹ̀ ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ kò rí àtìlẹyìn tó tó látọ̀dọ̀ ìjọba tó wà lóde.

Ó ní ó jẹ́ ohun tó ṣe ni láàánú ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ASUU ń yanṣẹ́ lódí lọ́wọ́lọ́wọ́ tí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ mìíràn náà sì ń dúnkokò láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì.

Ó wa rọ Ààrẹ láti lo ìgbà díẹ̀ tó kù tí yóò lò láti fi wá ojútùú sí àwọn ìpèníjà náà, tó sì tún pàrọwà sáwọn gómínà káàkiri ìpínlẹ̀ láti jí gìrì sí ojúṣe wọn, kí wọ́n yé dúró de ìjọba àpapọ̀ ní gbogbo ìgbà.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante