Kaduna-Abuja Train Attack: Amaechi ní òun kò tiẹ̀ mọ ohun tí ohun fẹ́ sọ fáwọn ọmọ Nàíjíríà mọ́

Oju diẹ lara awọn afurasi to fori sọta ikọlu reluwe to waye loju ọna oju irin Kaduna si Abuja ti jade sita.
Lara awọn eeyan naa la ti ri dokita obinrin kan, agbẹjọro, oludari eto ẹkọ, asaaju ẹgbẹ osisẹ, igbakeji gomina tẹlẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn agbebọn to da reluwe naa lọna lalẹ ọjọ Aje loju na Abuja si Kaduna lo da ẹmi awọn eeyan kan legbodo laipe ọjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ Rahmon Adedoyin tó ní òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́
- Ẹ wo orúkọ àti ojú àwọn èèkànlú tó forí sọta ìkọlù rélùwéè àti ipò tí wọn dì mú
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
- Wo bí òògùn lílò àtàwọn nǹkan mìí ṣe le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́
Ijọba ipinlẹ Kaduna si ti kede pe eeyan mejidinnirinwo lo wa ninu reluwe naa, mejidinlọgbọn farapa, ti wọn si n gba itọju lọwọ.
Eeyan mẹjọ lo ku lasiko ikọlu naa, tawọn agbebọn si ko ọgọọrọ ero to wa ninu reluwe naa lọ lai si ẹni to mọ ibi ti wọn wa.
Wo oju awọn eeyan to se alabapade ikọlu Reluwe naa:

Dokita Chinelo:

Oríṣun àwòrán, Dr Chinelo
Ọkan lara awọn eeyan to jade laye lasiko ikọlu reluwe naa ni Dokita onisegun oyinbo kan, Chinelo.
Ohun to bani ninujẹ nipa iku dokita Chinelo naa ni pe ọjọ Ẹti ọsẹ yii lo yẹ ko rekọja lọ sorilẹede Canada, ko to pade iku ojiji lọjọ Aje.
Ile iwosan St Gerald to wa ni Kaduna lo ti n sisẹ dokita, ki ọlọjọ to de.
Nigba to n tufọ iku rẹ, akọwe apapọ fẹgbẹ awọn onisegun oyinbo nilẹ wa, NMA, ẹka tipinlẹ Kaduna, Aisha Mustapha lo fidi iku oloogbe naa mulẹ.
Ẹgbẹ NMA wa sapejuwe Chinelo bii ẹni to jara mọsẹ, ti awọn yoo si mọ riri adanu iku rẹ lọpọlọpọ.
Koda, ọpọ eeyan lo ti n sedaro iku dokita Chinelo lori ayelujara bayii.

Musa Lawal Ozigi:

Oríṣun àwòrán, BARRISTER OZIGI
Akọsẹmọsẹ agbẹjọro ni Ozigin, oun si ni akọwe apapọ fun ẹgbẹ awọn osisẹ, ẹka ti TUC.
Aarẹ ẹgbẹ TUC, Comrade Quadri Olaleye to fi idi iku agbẹjọro naa mulẹ tun fikun pe ẹgbẹ naa tun padanu alaga wọn nipinlẹ Kwara ninu ikọlu ọhun.
Olaleye fikun pe wọn n lọ silu Kaduna lalẹ ọjọ Aje fun eto kan to yẹ ko waye lọjọ Isẹgun ni.

Abdu Isa Kofar Mata:

Oríṣun àwòrán, ABDU ISA KOFAR MATA
Abdu Isa Kofa Mata ni oludari agba fun ile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ.
Aburo rẹ, Muktar sọ fun BBC pe ọta ibọn ti awọn agbebọn yin mọ lo gba ẹmi rẹ, ti awọn ẹbi si banujẹ lori iku rẹ.
O wa se apejuwe ẹgbọn rẹ bii ẹni to maa nse iranlọwọ fun awọn eeyan miran.

Nuhu Danja:

Oríṣun àwòrán, Nuhu Danja
Kọmisana feto ilera nipinlẹ Katsina ni Nuhu Danja amọ ori ko yọ ninu ikọlu naa.
Ibrahim Almu Gafai tileesẹ ẹka eto ilera nipinlẹ Katsina salaye pe Kọmisana naa fara gba ọta ibọn lasiko ikọlu awọn agbebọn naa.
O ni ẹsẹ ni ọta ibọn naa ti wle si Danja lara, to si fọ ọnọ ika rẹ meji eyi to mu ko padanu awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ naa.
Danja wa nile iwosan nilu Kaduna nibi to ti n gba itọju lọwọlọwọ.

Alhaji Ibrahim Wakkala:

Oríṣun àwòrán, IBRAHIM WAKKALA
Igabkeji gomina tẹlẹ ni Wakkala nipinlẹ Zamfara, to si jẹ igbakeji gomina Abdulaziz Yari.
Oun naa wa lara awọn eeyan ti reluwe naa ko lasiko tawọn agbebọn se ikọlu si.
Amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Yusuf Idris ni ẹsẹ ni wọn ti yinbọn mọ ọga rẹ lasiko ikọlu naa, to si n gba itọju lọwọ nile iwosan.
Bakan naa ni igbakeji gomina tẹlẹ naa ba BBC sọrọ lori ibusun rẹ nile iwosan, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi rẹ si.
O wa sisọ loju rẹ pe wọn yoo se isẹ abẹ fun oun laipẹ lati yọ ọta ibọn to wa ni ẹsẹ oun.

A bá dáàbò bó ẹ̀mí aráàlú tí ìgbésẹ́ ṣíṣe ẹ̀rọ ayàwòrán síbùdókọ̀ rélùwéè kò bá pẹ́ ni - Amaechi
Minisita fun eto irinna ofurufu ni Naijiria, Rotimi Amaechi ti sọrọ soke lori isẹlẹ bi awọn agbebọn se kọlu ọkọ oju irin to n na Abuja si Kaduna.
Ọjọ Isẹgun lo sọrọ lori isẹlẹ naa, eyi to waye lalẹ ọjọ Aiku.
Nigba to se abẹwo sibi isẹlẹ naa, Amaechi lo n fi ika hanu pe o si seese ki awn doola ẹmi awọn ọmọ Naijiria to ku sinu isẹlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:+-````
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Osinbajo ṣe àbẹ̀wò síbi ìkọ̀lù ọkọ̀ rélùwè ní Kaduna, ó ní kí ọmọ Naijiria ṣe ọkàn gírí
- Ghana sọ ìrètí Naijiria láti kópa ní World Cup 2022 di òfo pẹ̀lú 1-1
- Ẹ̀mí 15 bọ́ ní Abeokuta àti Sagamu bí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣe ń ràn kiri l‘Ogun
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
Bakan naa lo kede pe eeyan mẹjọ lo ku ninu isẹlẹ naa, ti eeyan mẹẹdọgbọn si farapa laarin awọn ero mejidinnirinwo ti reluwe naa ko.
Minisita naa ni ọpọ awọn ero in ọkọ oju irin naa lo ti di awati, ti wọn ko si tii mọ iye wọn bayii.

Oríṣun àwòrán, @ChibuikeAmaechi
"A gbọdọ duro diẹ na fun awọn agbofinro ati ijọba ipinlẹ Kaduna pẹlu ileesẹ reluwe lati kan sawọn ti orukọ wọn wa ninu iwe akọsilẹ ero to wọ reluwe naa.
Awọn eeyan kan wa ti orukọ wọn ko si ninu akọsilẹ ero to wa ninu reluwe naa bii awọn osisẹ ọkọ oju irin naa.
Lara wọn si ni awọn osisẹ fun ileesẹ to n tun inu reluwe naa se. Iru awọn eeyan yii ni wọn ko tii ni akọsilẹ nipa wọn."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọkan mi bajẹ, agara da mi lori ohun ti oju mi ri nipa isẹlẹ ikọlu reluwe to waye:
Bakan naa ni Minisita feto irinna naa n tara poro loju opo Twitter rẹ pe ọkan oun bajẹ, ti agara si da ohun lori ikọlu si reluwe naa.
O ni "Mo ti de ibi ti isẹlẹ ikọlu si reluwe to n lọ si Kaduna lati Abuja ti waye, ti ọkan mi si rẹwẹsi.
Ọkan mi ati adura mi si wa pẹlu awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa ati awọn ẹbi wọn.
Bakan naa ni mo n ke si awọn to yẹ ko fi ontẹ lu igbesẹ lilo awọn ẹrọ ayaworan nibudokọ reluwe naa lati tete gbe igbesẹ kanmọnkia lori rẹ."
Amaechi ni oun ko tiẹ mọ ohun ti ohun fẹ sọ fawọn ọmọ Naijiria mọ nitori to ba jẹ pe ilana fifi ẹrọ ayaworan sawọn ibudokọ reluwe ko gun ni, awọn ko ba le daabo bo awọn araalu.
















