Ojodu Kidnapper: Ọwọ́ pálábá afurasí ajọ́mọ́gbé méjì ségi ní Eko, bí wọ́n ṣe fẹ́ jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé lẹ́nu ọ̀nà iléẹ̀kọ́

Temitayo Olafisoye ati oogun omi gọta to n fun awọn ọmọ to ba ji gbe mu

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ilẹ ti dooyi kan afurasi ajọmọ gbe fi se etutu ọla kan nilu Eko, ti asiri rẹ si tu loju araye.

Afurasi ajọmọgbe naa, Temitayo Olafisoye ni ọwọ sinkun awọn araalu tẹ nigba to n gbiyanju lati ji awọn akẹkọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ aladani kan gbe lọ.

Adugbo Omole Estate ni agbegbe Ojodu-Berger nilu Eko si ni isẹlẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fọnran bi afurasi ajọmọgbe naa se ka nipa isẹ ibi to n se lasiko ti ọwọ tẹ ẹ, si ti lu ori ayelujara pa.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Bawo ni isẹlẹ naa se waye:

Olafisoye ati isọmọgbe rẹ, Kayode Akinola ni wọn se abẹwo si adugbo naa lọwọ Aiku, ti wn si n rin gbere gbere kiri yika ọgba ile ẹkọ naa.

Idi si ree ti ara fi fu awọn ẹsọ alaabo to wa ladugbo naa amọ ti awọn afurasi ọhun ko mọ pe oju ti wa ni ara awọn.

Amọ nigba to di ọjọ Aje, ni obinrin kan gbe awọn akẹkọọ wa sile ẹkọ, to si gbe ọkọ rẹ sunmọ ẹnu ọna ile ẹkọ naa pe ki awọn ọmọ naa bọ silẹ, wọnu ọgba ile ẹkọ wọn lọ.

Bi obinrin naa si ti bọ silẹ ninu mọto pe ki oun sọkalẹ wa silẹ fun awọn ogo wẹẹrẹ naa lati sọkalẹ, ni Olafisoye ba fo fẹrẹ bọ sinu ọkọ obinrin naa, lati maa gbe mọto rẹ lọ tọmọ-tọmọ ninu rẹ.

Amọ ofuufu-fẹẹtẹ ni igbinyanju rẹ naa ja si, nitori obinrin naa ti pa ina ọkọ rẹ, to si mu kọkọrọ mọto naa lọwọ rẹ lasiko to n sọkalẹ kuro ninu mọto ọhun.

Idi si ree ti obinrin na se ke gbajare ni kete to ri iwa ti Olafisoye hu, kia si ni awọn ẹsọ alaabo adugbo naa kan lara.

Amọ Akinola, tii se isọmọgbe Olafisoye ti raye salọ ni kete ti ijakulẹ ba igbiyanju wọn lati ji awọn ọmọ naa gbe salọ.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

N ko sẹsẹ maa wa si Eko wa ji ọmọ gbe, etutu ọla la n fi wọn se - Afurasi ajọmọgbe

Nigba ti wọn n fi ọrọ wa afurasi ajọmọgbe naa lẹnu wo ninu fidio to lu ori ayelujara pa naa, Olafisoye ni ilu Ibadan ni oun ati ẹnikeji oun ti maa n wa silu Eko lati wa ji awọn ọmọde gbe fi se etutu ọla.

"Ni kete ta ba ti ji awọn ọmọde naa tan, a ko wọn sinu ọkọ ayọkẹlẹ lati fi wa wọn lọ.

Omi gọta la maa n po papọ mọ oogun oorun ta fi kun awọn ọmọde naa loorun, titi ti a fi gbe wọn de ibi ta n lọ.

Adugbo Apata nilu Ibadan ni mo ti wa, oogun owo si la maa n fi awọn ọmọde naa se.

Ọpọ ọmọ ni mo ti ji gbe lọ ladugbo Berger, Iyana Ipaja, Ikotun, Iyana Iba ati bẹẹ bẹẹ lọ." Akinola lo sọ bẹẹ.

A fa isẹlẹ naa ati afurasi le ẹka ileesẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii to yẹ - Alukoro ọlọpaa

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi idi isẹlẹ naa mulẹ.

Hundeyin ni ileesẹ ọlọpaa yoo gbe afurasi naa lọ si ẹka iwadi ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Yaba nilu Eko.

O ni afurasi ajọmọgbe ọhun si wa ni agọ ọlọpaa to wa ni Ojodu bi o tilẹ jẹ pe afurasi keji ti na papa bora.

Amọ o ni ọwọ yoo papa tẹ lẹyin o rẹyin ni nitori ẹgbẹrun saamu rẹ, ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ.

Amin iyasọtọ kan

Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn

Pasitọ Chapel of Revelation Ministry

Oríṣun àwòrán, Chapel of Revelation Ministry

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe iIeeṣẹ Ọlọpaa ti fi panpẹ òfin mu Pasitọ to jẹ adari ìjọ kan latari ẹ̀sùn gbigba ojú ìdí ẹ̀yìn ni ibalopọ ọkunrin pẹlu àwọn ọkùnrin mẹta lára àwọn ọmọ ìjọ rẹ.

Afurasi ọhun ń dari ìjọ rẹ ni agbegbe Ajegunle ni Ìpínlẹ̀ Eko.

Awọn arákùnrin mẹta ti wọn fẹ̀sùn kan pe Pasitọ ń ba lòpọ̀ yìí si jẹ ọmọ ìjọ rẹ. Ẹni ọdún mẹẹdogun, mejidinlogun àti ogún ni awọn ọkunrin mẹtẹẹta naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Eko ni o ti pe ọjọ marun bayii ti awọn ti fofin mu pasito ọhun.

Bí wọ́n ṣe rí pasito mú

Agbenuso Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC pe ìwádìí fihan pe afurasi naa fipa ba awọn ọdọkunrin yẹn lòpọ̀ "ni ọpọlọpọ igba laarin Oṣù Kínní si Oṣù Kẹta ọdún 2022".

Iroyin taa gbọ́ ni wipe ọkan lára àwọn ọdọkunrin ọhun nìkan lo fi ẹjọ́ nkan to n ṣẹlẹ̀ sún obi wọn pé pasito n ba awọn lòpọ̀ láti ìdí ẹyin.

Ọkùnrin náà lo tún ṣàlàyé pe Pasito máa n la oje to n tu jade lara nkan ọmọkùnrin wọn ṣáájú ati lẹyin ibalopọ.

Iroyin sọ pe pasito sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọdọkunrin ẹni ogún ọdun ọhun to jẹ eyi to dagba ju ninu wọn pe oun fẹ tu u silẹ lọwọ ẹ̀mí jíjà ẹ orí ayelujara tí wọn n pe ni 'yahoo yahoo'.

Nígbà tí yóò sọ̀rọ̀ bákan náà, pasito náà fẹ̀sùn kan pe ohun kan ti oun máa ń ṣe a naa ni riran agbara ti ẹmi sínú ayé wọn.

Awọn ọdọkunrin náà ba ara wọn ń ileewosan

Pasitọ Chapel of Revelation Ministry

Oríṣun àwòrán, CHAPEL OF REVELATION MINISTRY

Nítorí ìmọ̀lára ti wọn n ni ni idi àti bo ṣe ń dùn wọn, awọn ọkunrin náà ń ṣe ayẹwo ara wọn lọwọ.

"Lẹyin ayẹwo lao o to gbe igbesẹ to kan," Hundeyin sọ bẹẹ.

Njẹ Ọlọpaa le ti ìjọ naa pa?

Agbenuso Ọlọpaa sọ pe awọn ko tii mọ boya awọn ọkunrin mẹta yii nìkan ni pasito n ba lòpọ̀.

"Awọn mii ko tii wa fi ẹjọ́ sun pe pasito fipa ba awọn lòpọ̀. Bi iwadi wa bá wa fihan pe o ti pẹ ti o ti n ṣe iru nkan bẹẹ, a o ti ṣọọṣi naa pa ni".

O ni titi di akoko yii, awọn ṣi n tana wadii ọrọ naa pe awọn yoo ṣi gbe e lọ ile ẹjọ́ ni kete ti awọn ba ti pari.