Agbófinró mú ọ̀dọ́mọkùnrin 57 níbi ètò ìgbaniwọlé fún ìbálòpọ̀ akọ-sí-akọ

Ọkunrin meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ofin Naijiria ko tako ibalopọ laarin ọkunrin s'ọkunrin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbọn ọkan lara awọn ọdọmọkunrin ti awọn ọlọpaa ko ni ọjọ Aiku nipinlẹ Eko, ti wọn fẹsun kan pe wọn n si ibalopọ akọ-si-akọ, ni irọ ni wọn pa mọ aburo oun.

Ọjọ Aiku to kọja ni awọn ọlọpaa mu awọn ọdọmọkunrin mẹtadinlọgọta nilu Eko, ti wọn si fi ẹsun kan wọn pe wọn n ni ibalopọ ọkunrin s'ọkunrin.

Ọkan lara awọn ọdọmọkunrin naa ni Wọle, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun.

Ẹgbọn rẹ, Ojo Ọladele sọ fun BBC pe 'ibi ariya ni aburo oun(Wọle) dagbere pe oun n lọ ni alẹ ọjọ Abamẹta, ko to di wi pe awọn ọlọpaa mu u.

Ọladele ni ''aburo oun ati awọn ọrẹ rẹ kan ni wọn jọ lọ si ibi ariya kan to waye nile itura kan ni agbegbe Ẹgbẹda.

O ni "ko pẹ to de ile itura naa, ni nkan bi aago kan oru, to si n wa awọn ọrẹ rẹ, ni awọn ọlọpaa wọle.

Bi awọn ọlọpaa sẹ wọle ni awọn eniyan to wa nibẹ bẹrẹ si ni salọ.

Awọn ọkunrin to n fẹnukonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ofin Naijiria ko tako ibalopọ laarin ọkunrin s'ọkunrin

Ibi ti oun ti n gbiyanju lati ṣalaye ara rẹ fun awọn ọlọpa ni wọn ti gbe gbogbo wọn ju sinu ọkọ ọlọpaa.''

Ọladele ni ' O damiloju pupọ pe aburo mi ki i ni ibalopọ ọkunrin s'ọkunrin rara, o kan ṣirin ni.''

"Wọn o jẹ ki a sun mọ ibi to wa, wọn o jẹ ka fun un ni ounjẹ, koda inu iporuru ọkan lo wa bayi, ti a ko si mọ nkan ti wọn n ṣe fun wọn ni agọ ọlọpaa."

"Wọn ko ri ẹsun kankan fi lọ wọn, ṣugbọn ile ẹjọ ti gba beeli wọn bayii.''

'Ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ nkan to n ṣe'

Agbẹjọro ọkan lara awọn ọdọmọkunrin naa, Ṣẹgun Awosanya, ti awọn eniyan tun mọ si Segalink, sọ fun BBC pe, ọrọ ọhun ko ye awọn ọlọpaa gan nitori sẹ ni awọn agbẹjọro wọn n jasi ẹni ti ẹjọ naa yoo ja mọ lọwọ ninu wọn.

Awosanya ni 'awọn ni awọn ti gba beeli wọn, titi di igba ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo mọ ẹsun ti wọn fẹ ẹ fi kan wọn."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

"A si gbọ pe awọn kan ni wọn ko ni i fi ẹsun ibalopọ ọkunrin s'ọkunrin kan wọn mọ, pe ki wọn ko wọn pada lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ṣiṣe."

Ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọro kan ti kede pe wọn ti gba beeli awọn ọdọmọkunrin naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹwẹ, Awosanya ni bi wọn ṣe f'oju wọn han sita fun gbogbo eniyan lori ẹsun pe wọn fura siwọn ko b'ojumu.

Báwo ni ọ̀rọ̀ nàá ṣe wáyé gan an?

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ni ko din ni awọn ọdọmọkunrin mẹtadinlọgọta ti awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko fi ofin mu 'lasiko ti wọn n ṣe eto igbaniwọle fun awọn to fẹ maa sẹ ibalopọ ọkunrin s'ọkunrin.'

Eto igbaniwọle ọhun ni iroyin ni pe o waye ni aago kan oru ọjọ Aiku, ni ile itura kan l'agbegbe Ẹgbẹda nipinlẹ Eko.

Kọmiṣọna fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Edgal Imohimi, ni mimu ti awọn mu wọn ko ṣẹyin awọn oṣiṣẹ alaabo abẹle to sin ileesẹ ọlọpa ni gbẹrẹ ipakọ.

O ni eyi lo mu ki awọn ọga ọlọpaa ni agbegbe Shasha ati Idimu nipa asẹ kọmisọna, yabo ile igbafẹ naa lati ṣe iwadii lori eto igbaniwọle naa.

Àkọlé fídíò, Bọde George: Àwọn èèyàn mọ ẹni to yìnbọn pa Adeniyi Aboriṣade

Edgal ni awọn ọdọmọkunrin to le ni ọgọrin ni awọn ọlọpaa ba nibẹ ni nkan bi aago meji oru ti wọn n mu oriṣiriṣi ọti lile, to fi mọ Tramadol ati Shisha ti wọn po igbo mọ.

Wọn ni ni kete ti awọn ọmọkunrin naa ri awọn ọlọpaa ni wọn sa gba ọna ọtọọtọ, amọ ọwọ ọlọpaa tẹ mẹtadinlọgọta lara wọn.

Ṣugbọn awọn ọmọkunrin ti ọwọ ọlọpaa tẹ ọhun ni irọ ni wọn pa mọ wọn, pe awọn ki i ṣe ibalopọ ọkunrin s'ọkunrin.

Ati pe awọn ọlọpaa ko fun awọn ni anfaani lati sọ ọrọ gbe ara wọn lẹsẹ.

Àkọlé fídíò, Ilu Ubang, jẹ ilu kan nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.