BB Naija: ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lágboólé Olanrewaju Malcolm, olólùfẹ́ Bisọla rí

Bisola, ọmọ rẹ̀ àti Olanrewaju Malcolm tó di olóògbé

Oríṣun àwòrán, Twitter/Big Brother Naija 2018

Àkọlé àwòrán, Ilẹ n jẹ èèyan, Ikú ti mú Olanrewaju Malcolm ọkọ Bisola lọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Olanrewaju Malcolm, baba ọmọ Bisola Aiyeola to kopa ninu idije Big Brother Naija ni a gbọ pe o ti ku.

Malcolm to jẹ alakoso oṣere nigba aye rẹ niroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe o ku laarọ oni, ọjọ Abamẹta si ile iwosan kan ni agbegbe Surulere, nilu Eko.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Iroyin naa sọ pe ọgbẹni Malcolm papoda lẹyin ti o ti ba aisan kan finra fun ọjọ pipẹ ni ẹni ọmọ ọdun mẹtadinlogoji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Olanrewaju Malcolm lórí Instagram

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olanrewaju Malcolm

Àkọlé àwòrán, Olanrewaju Malcolm kú lẹ́yìn àìsàn ọjọ́ pípẹ́

Eyi ni ọrọ asọkẹyin oloogbe lori opo Instagram rẹ ni yi pe, iyipada ti de ba oun.

Ilẹ n jeeyan, ko si awaye-ma-lọ.

Àkọlé fídíò, Aarun ọpọlọ kii se idajọ iku
Àkọlé fídíò, Wo fidio ikede iku Hawking to ku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin (76)