Buhari: ó wù mí láti kí àwọn èèyàn mi ni Daura lójúkojú.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Aarẹ Muhammadu Buhari salaye idi ti o fi rin irin ẹgbẹrin mita lẹyin to kirun Yidi tan nilu rẹ Daura nipinlẹ Katsina.
Aarẹ sọ loju opo Twitter pe oun ko rin lati fihan awọn eeyan pe ara oun le.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Aarẹ Buhari sọ pe oun gbe igbesẹ lati rin nitori awọn ara ilu oun tu yaaya jade lati ri oun, ṣugbọn wọn ko ni anfani lati ṣe bẹẹ nitori gilaasi ilẹkun ọkọ ti oun wa ninu rẹ ṣe dudu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ ni eleyi gan-an lo ṣe okunfa bi oun ṣe bọ silẹ ninu ọkọ ti oun si bẹrẹ si lọ.
Aarẹ Buhari sọ pe awọn ti wọn mọ oun daadaa mọ pe oun ko rin nitori oṣelu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
O fi kun ọrọ rẹ pe oun ko ni lati rin ki o to di pe awọn eeyan gbagbọ pe ara oun da muṣe lati dije dupo Aarẹ lẹlẹẹkeji.

Oríṣun àwòrán, Omoleye Sowore/Facebook
Ẹwẹ, olùdíje fún ipò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú AAC, Ọmọyẹle Soworẹ, náà ti fi àwòrán sórí ìtàkùn Facebook rẹ̀ níbi tó ti sáré yípo ilẹ̀ New York ká láàrin wákàtí mẹ́rin.
Ó ní ààrẹ rìn ìrìn ẹgbẹ̀rin mítà láti jẹ́ káyé mọ̀ pé òun dángájíá nígbà tí olùdíje míì, Abubakar Atiku náà tún gbé ara rẹ̀ sáyé lórí ìdárayá.
Òṣèlú Nàìjíríà di ti 'eré sísá' àti 'ìrìn rínrìn' báyìí!
Ni ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwòrán Ààrẹ Muhammadu Buhari tó ń fi ẹsẹ̀ rìm láti yídì ìlú Daura lọ sí ilé rẹ̀ gbòdekan; ṣugbọn Abubakar Atiku to figbakanri jẹ igbakeji aarẹ lorilede Naijiria ti tako aarẹ Muhammadu Buhari lórí òṣèlú 'onírìnsẹ̀' àti 'eré sísá' yii.

Oríṣun àwòrán, Twitter\BashirAhmaad\@tiku
Igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria nigbakanri, Atiku Abubakar, ti koro oju si irin ẹlẹgbẹrin mita ti aarẹ Muhammadu Buhari rin nilu Daura ni ọjọ Iṣẹgun pẹlu ọrọ pe ere idaraya kii ṣe ọpakutẹlẹ fun ati ṣe odinwọn bi eeyan ṣe jafafa si lati fi ẹsẹ orilẹede Naijiria le pepele to tọ.
Ninu ọrọ to gbe jade lori ikanni ayelujara Twitter rẹ, Atiku ni oun gan a maa sare ju ibusọ kọn lojoojumọ atipe yoo jẹ ohun idojuti nla gbaa fun oun lati wa maa fi eyi yangan tabi fi ke sawọn ọmọ orilẹede Naijiria lati dibo fun oun.
"Igbagbogbo ni mo maa n sare to le ni maili kan ti mo si n ṣere idaraya, ṣugbọn yoo jẹ ohun ti ko bojumu fun mi lati wa maa fi eyi pe awọn ọmọ naijiria lati dibo fun mi."
Ni ọjọ iṣẹgun ni aworan Aarẹ Muhammadu Buhari to n fi ẹsẹ rin lati yidi ilu Daura lọ si ile rẹ gbodekan lori ayelujara ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ni irin ẹgbẹrin mita ni Baba rin.

Ibeere ti awọn eeyan wa n beere bayi ni pe igbawo ni ipolongo oṣelu lorilẹede Naijiria wa di ti "mole rin ju ọ lọ" tabi "mole goke mo le sọ"
Awọn eeyan kan lori ikanni ayelujara ni owe kokoko lara ọta n le ni aarẹ pa ranṣẹ si awọn alatako rẹ ni igbaradi fun idibo ọdun 2019; ṣugbọn igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar ni "Ohun ti mo fẹ ni ẹgbẹ oṣelu mi-PDP, atawọn ọmọ orilẹede Naijiri o dibo fun mi nitori iṣẹ ti mo lee ṣe, kii ṣe nitori irin ti mo lee rin."

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Nibayii gan aworan igbakeji aarẹ̀ Yẹmi Ọṣinbajo gan ti wa lori ayelujara.
Aworan naa ninu eyi ti igbakeji aarẹ Yẹmi Oṣinbajo ti n juwọ ti ọpọ ero si n wọ tọọ lẹyin naa ti n gbera sọ bayi lori ikanni ayelujara twitter!
Sáájú ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣalaye pe pẹlu bi o ṣe jẹ pe awọn kan n bu ẹnu atẹ lu orilẹede Naijiria, orilẹede Naijiria ti wa ni oju ọna irapada isọdọtun.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Fẹmi Adeṣina fi sita ni ọjọru ni aarẹ ti sọ di mimọ lasiko to fi n kan sara sawọn agbofinro meji kan ti wọn da apo to kun fun ohun alumọni eyi ti arinrinajo kan lati ilẹ Amẹrika sọnu ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed nilu Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ Buhari rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati wawokọṣe awọn agbofinro meji naa nitori iwa wọn naa ṣe afinhan Naijiria tuntun ti gbogbo eeyan n fẹ.
"O ṣeeṣe fawọn agbofinro mejeeji lati ṣe ohun miran to yatọ si eyi ti w ọn ṣe pẹlu iwa ibajẹ didarapọ mọ awọn iwa kotọ gbogbo lawujọ.
Orilẹede Naijiria kii ṣe adape orukọ iwa ibajẹ ati iṣowo ilu baṣubaṣu mọ bayii nitori ọna tuntun ti a ti yan lati maa tọ niyi ti ko si si ẹni ti yoo so wa mọlẹ sinu iwa ibajẹ atẹyinwa mọ."

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Iroyin sọ pe dokita iṣegun oyinbo kan to filu Eko ṣe ibujoko ni o lọ pade awọn mọlẹbi rẹ kan ti wọn tajode lati orilẹede Amẹrika ni papakọ ofurufu naa ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2018.
Ni idunnu ipade ojutunrari wọn ni wọn ti gbagbe ẹru iyawo arakunrin to t'ajo de naa laimọ.
Ni nkan bi wakati kan abọ lẹyin eyi ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ alaabo aladani Halogen Securities kan rii he to si pe wọn lati wa gba apo wọn.
Awọn eeyan naa mu ẹbun to jọju fi ta awọn agbofinro naa lọrẹ ṣugbọn ti wọn kọ; ti wọn si ni iṣẹ awọn lawọn nṣe.












