Saraki: Tinubu fẹ́ di ààrẹ ní 2023, ló se ń tẹ̀lé Buhari

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ti ṣalaye wi pe irọ ni ọrọ ti kan ti wọn ni aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu sọ lori idi ti oun fi fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.
Saraki, ninu atẹjade kan to fi sita gẹgẹ bii esi si ọrọ naa ni bi ''Aarẹ Buhari ati awọn isọmọgbe rẹ ṣe n fi ọwọ idẹyẹsi mu ẹka aṣofin kun ara ohun to mu ki oun ati awọn eekan ẹgbẹ naa kan fi ẹgbẹ silẹ.
Bakan naa ni Saraki ṣalaye pe Tinubu ti ṣalaye fun oun ati awọn eekan ẹgbẹ naa ri pe inu oun ko dun si iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari nitori ẹgbin ti ijọba Buhari ti awọn jọ ṣiṣẹ gbe si ipo fi n kan oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Saraki ni Tinubu ṣọ ọrọ naa l'asiko to fi dari eto ipẹtusaawọ laarin ẹgbẹ oṣelu naa pe "bi aarẹ Buhari di alailera lori kẹkẹ alaisan oun ni oun yoo ti lẹyin nitori ki ipo aarẹ lee tọ si ẹkun Iwọ oorun -Guusu l'ọdun 2023."

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Saraki tun sọọ siwaju wi pe, ko si idi meji ti Tinubu fi n sọ ọrọ ti ko tọ nipa oun ju wi pe oun atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC kan tako erongba rẹ lati di igba keji fun Aarẹ Buhari l'ọdun 2014 lori bi awọn mejeeji ṣe jẹ ẹlẹsin musulumi kan naa.
Amọṣa aarẹ ile aṣofin agba l'orilẹede Naijiria naa ko ṣai rọ awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu APC lati faramọ ipinnu oun lati fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ, niwọn igba ti o jẹ pe ori opo ipinnu ara ẹni ni eto iṣejọba tiwantiwa duro le.









