French Open: Serena kò gbọdọ̀ wọ aṣọ 'Black Panther' mọ́

Serena àti Venus Williams

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Serena Williams ti gba ife ẹ̀yẹ French Open lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀

'Aṣọ Black Panther ti mo wọ kii ṣe fún oge tabi igberaga'

Awọn alaṣẹ idije French Open ti paṣẹ fun agbaọjẹ agbabọọlu tẹnisi, Serena Williams, wi pe ko gbọdọ wọ aṣọ dudu to dabi ti inu fidio 'Black Panther' mọ lọjọ iwaju ninu idije naa.

Serena to bẹrẹ si maa dije pada lẹyin to bimọ lọdun to lọ, wọ aṣọ dudu iru eyi ti oṣere kan wọ ninu fidio 'Black Panther' nibi idije French Open t'ọdun yii.

Serena ni aṣọ ọhun jẹ ki oun dabi ọmọ-ọba-binrin ologun, bẹẹni ki iṣe fun oge rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Mori ara mi to funfun, mi o mọ pe ẹtẹ ni

Agbabọọlu ọmọ ilẹ Amẹrika naa fi kun ọrọ rẹ pe aṣọ naa tun ran oun lọwọ lati dena ẹjẹ didi eleyi to ti da oun laamu tẹlẹ.

Serena Williams

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Serena Williams bí ọmọbinrin ti orúkọ rẹ̀ ń jọ́ Olympia lọ́dún 2017

Ṣugbọn aarẹ ajọ French Open, Bernard Giudicelli, ni ofin tuntun ko ni gba iru ẹ laaye mọ.

Serena ti ṣetan lati kopa ninu dije US Open ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje to mbọ lorilẹ-ede Amẹrika.

awon agbaboolu obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ko le wọ aṣọ dudu yii mọ
Àkọlé fídíò, Ìdíje ayò ọlọ́pọ́n, ta lòpè?
Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York