Orílẹ̀èdè Niger gba ìwé àṣẹ padà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ tó kọ̀ láti gbé epo lọ sí Mali nítorí ìkọlù agbésùnmọ̀mí

Ọkọ epo mẹrin ati ọkunrin to wa nilẹẹlẹ, nigba ti ọkunrin keji n nawọ silẹ lati inu ọkọ

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun bi wọn ko ṣe fẹ gbe epo lọ si orilẹede Mali nitori ikọlu awọn agbesunmọmi, orilẹede Niger ti gba iwe aṣẹ ti awọn awakọ kan fi n ṣiṣẹ pada lọwọ wọn lorilẹede naa.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹsan-an ni awọn ẹgbẹ alakatakiti kan ti wọn yapa lati ara al-Qaeda, gbegi dina gbigbe epo wọ Mali, ti wọn si n da awọn ọkọ epo lọna ni awọn ọna nla to jẹ marosẹ.

Epo ti wọn n gbe wọle lati ilẹ okeere yii naa ni Mali gbe ẹmi le, nigba to si di oṣu Keje ni wọn tọwọ bọwe adehun kan pẹlu Niger, pe Niger yoo maa fun wọn lepo lita 85 million.

Adehun naa yoo ju oṣu mẹfa lọ bi wọn ṣe jọ sọ, wọn yoo si maa gbe e lọ si apa aṣalẹ Ariwa, nibi ti awọn ẹgbẹ agbesunmọmi oriṣiiriṣii ti n ṣọṣẹ.

Latilẹ ni orilẹede Niger ni tiẹ ti jẹ ilu to n pese epo, wọn si jẹ ọrẹ Mali – wọn jọ n koju ikọlu awon agbesunmọmi ni.

Ṣugbọn oju awọn ikọ to n gbe epo naa lọ lati Niger maa n ri kisa loju ọna, irinajo naa si to 1,400km (870 miles), koda, pẹlu bi awọn ologun ṣe n tẹle wọn lọ to, wọn ṣi maa n ko awọn alakatakiti naa lọna.

Awọn awakọ epo yari

Loṣu Kọkanla to kọja, tanka epo mejilelọgọrin (82) ni Niger gbe lọ si Mali,eyi ni orilẹede naa lo bo ṣe gba, nigba ti awọn alakatakiti tun kọlu ikọ to n bọ lati Senegal ati Ivory Coast.

Mali n reti pe wọn yoo tun gbe epo si i wa lati Niger loṣu to tẹle e, ṣugbọn ko ri bẹẹ, awọn awakọ epo kọ lati lọ.

Idi si niyẹn ti ẹka eto irinna Niger fi gba iwe iṣẹ ileeṣẹ ọlọkọ mẹrinla, ati ti awakọ mọkandinlogun, fun pe wọn kọ lati gbe epo lọ si Mali.

"Bi wọn ṣe kọ yii tako aṣẹ to yẹ ki wọn tẹle."

Minisita eto igbokegbodo ọkọ ni Niger, Abdourahamane Amadou, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni yii.

Atẹjade naa fi kun un pe awọn ti ọrọ yii kan gbọdọ tun ko gbogbo iwe ọkọ wọn wa si ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ.

Bẹẹ ni wọn si tun fi ofin de ọkan ninu wọn fun ọdun kan.

Ẹgbẹ́ wo lo n daamu awọn awakọ?

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹgbẹ Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM) ni wọn lo wa nidii idena epo gbigbe wọle naa.

Ẹgbẹ JNIM ni wọn fẹ sọ igbesunmọmi di ogun ọrọ aje.

Awọn JNIM yii ti ji awọn awakọ epo gbe, wọn si ti digbo lu tanka wọn naa daadaa.

Lọdun to kọja, wọn ti awọn ile ẹkọ pa fungba diẹ ni Mali nitori ai si epo ti ilu naa yoo lo.

Koda, ilẹ America kilọ fawọn eeyan rẹ loṣu Kọkanla ọdun to kọja lati ma ṣe lọ si Mali.

Bẹẹ ni France naa sọ fun awọn eeyan rẹ to wa ni Mali lati fi ilu naa silẹ.

Ijọba ologun lo n dari Mali, Gen Assimi Goïta,ni adari ibẹ lẹyin to fipa gbajọba ni 2020.