Ìpínlẹ́ Katsina ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ẹ́ tú agbésùnmọ̀mí 70 sílẹ̀

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Katsina ti sọrọ sita lori erongba rẹ lati tu awọn afurasi agbesunami aadọrin silẹ kuro ni ahamọ.

Ijọba ṣapejuwe igbesẹ gẹgẹ eyi ti yoo fayegba jiroro alaafia laarin ijọba ati awọn agbesunami.

Kọmisana fun eto aabo nipinlẹ naa, Nasir Muazu ni igbesẹ lo da lori igbiyanju ijọba lati ri pe alaafia jọba laarin awọn agbegbe ti awọn agbebọn n kọlu ati awọn agbebọn to ti ronu piwada.

Muazu, nigba to n ba ikọ iroyin DCL Hausa sọrọ, o ṣalaye ni kunkun lẹyin ti igbesẹ ijọba lati tu awọn agbesunami naa lu sita lori ayelujara .

O ni igbesẹ yii ti jẹ ki eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ti awọn agbebọn jigbe ni ọpọ ilu gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

O tẹsiwaju pe o le agbegbe mẹdogun to lọwọ ninu igbesẹ alaafia yii, ti wọn si pinnu pe ki wọn ṣe pasiparọ awọn ẹlẹwọn laarin ijọba ati awon agbebọn.

Muazu ni ohun to waye dabi ohun to ma n sẹlẹ lasiko ogun.

Lẹta ti ẹka idajọ ipinlẹ Katsina kọ si Adajọ agba ipinlẹ naa, to n pe fun itusilẹ awọn afurasi agbebọn naa.

Lẹta naa ni oludari Public Prosecutions, Abdur-Rahman Umar, buwọlu, to si pe fun ki afurasi mẹjidinlaadọta, ti wọn fi orisirisi ẹsun kan ni wọn fi ransẹ si ẹka idajọ,

Muazu, tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe igbesẹ yii ti jẹ ki alaafia jọba ni ọpọ agbegbe nipinlẹ naa ati pe ọpọ eeyan to wa ni igbekun awọn agbebọn ni wọn ti gba itusilẹ.

O sọ iye awọn eeyan to ti gba itusilẹ kaakiri ijọba ibilẹ bi Sabuwa (310), Bakori (125), Danmusa (60), Dutsinma (62) ati Safana (36).

Kọmisana ni eyikeyi ninu ẹka idajọ ati ile ẹjọ ko tapa si ofin kankan, to si ni ẹyikẹni ti eyi ko ba tẹ lọrun, morilọ ile ẹjọ.

"Ni gbogbo agbaye, lẹyin ogun , pasiparọ awọn ẹlẹwọn ma n waye. Lasiko ogun abẹle Naijiria, iru eyi waye , gẹgẹ bii o ṣe waye pẹlu Boko Haram.

"Ọrọ ko ki n ṣe nipa boya ijọba tapa si ofin ṣugbọn lati ri pe alaafia jọba. Igbesẹ yii ki n ṣe tuntun ninu itan ogun ati alaafia ," o sọ.

'Orukọ awọn afurasi agbebọn ti yoo gba itusilẹ'

Ninu iwe kan to tẹ ileeṣẹ iroyin abẹle kan, Katsina Times, ṣafihan pe obinrin kan wa lara awọn ti yoo gba itusilẹ.

Orukọ diẹ lara wọn ni Hadiza Dije Hauwa'u from Safana, Gambo Zubairu Faskari, Muntari Yusuf Safana, Yakubu Alhaji Ardo, Tukur Amadu (Liman), İdi Salisu Gaddi, Abdulhayatu Jabiru, Ya'u Buhari ati Amadu Rufa'i Anare.

'Ijọba gbọdọ san owo gba ma binu fun awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn'

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Daily Trust sọrọ ọga agba fun ikọ Network for Justice, Abdullahi Hassan Kofar Sauri, ni ijọba ni lati ri pe awọn san owo gba ma binu fun awọn mọlẹbi ti ikọlu awọn agbebọn ṣe ijamba fun nipinlẹ naa.

O ni ṣe ni laanu pe ijọba ipinlẹ Katsina ati ijọba apapọ ti kọ sọ pe awọn ko lọwọ ninu idunadura pẹlu awọn agbebọn.

"Ijọba ipinlẹ n gbiyanju lati gba itusilẹ awọn afurasi agbebọn ti wọn fẹ fi oju wọn bao fin. Eyi jẹ nnkan ti wọn sọ pe awọn ko ki n ṣe ṣugbọn bayii nkọ, awọn eeyan yii wa ni akata wọn.

"Wọ n wa ni ọgba ẹwọn, ti wọn n jẹ iya ẹsẹ wọn ṣugbọn iroyin nipa itusilẹ wọn yii jẹ ohun to kọ wa lominu pupọ. Ọrọ yii ba awọn eeyan lojiji: ki ni idi ti ijọba fi wa bayii pe awọn fẹ tu wọn silẹ."