2023 Presidency: Pásítọ̀ Tunde Bakare ní òun ṣetán láti díje du ipò Ààrẹ

Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Pastor Tunde Bakare

Alufaa agba ijọ Citadel Global Community Church, Tunde Bakare ti sọ pe oun yoo kede erongba oun lati dije du ipo Aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023 lọṣẹ to n bọ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Bakare sọ pe ọjọ Aje to n bọ, iyẹn ọjọ kẹsan an, oṣu Karun un yii, ni oun yoo fi ikede naa si gbangba walia.

O ni "Lootọ ni ko tii si lawọn oju opo ikansiraẹni Instagram, Facebook ati Twitter wa, ṣugbọn pẹlu ogo Ọlọrun, eku ile yoo gbọ yoo sọ fun t'oko nitori o n bọ o n bọ, o ti wa de bayii."

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

"Lagbara Ọlọrun, ni ọjọ Aje ni a oo kede erongba wa lati dije du ipo Aarẹ, gbangba yoo dẹkun, kedere yoo si bẹ wo."

Irọrun ni ijọba mi yoo ba de fun araalu - Bakare

Ni ti ohun to yẹ ki awọn araalu maa reti ninu ijọba Bakare to ba jawe olubori ninu eto idibio naa, Bakara sọ pe igba ọtun ni ijọba oun yoo jẹ faraalu.

O ni "Logo Ọlọrun, ogo Naijiria yoo pada wa, ilu yoo toro, a ko si ni ri gbogbo awọn wahala ti a n dojukọ yii mọ."

"Ara yoo rọ awọn araalu nitori Ọlọrun ọga ogo yoo tẹdo si Naijiria, yoo si fọwọ si gbogbo ohun ti a ba n ṣe."

"Ẹ jẹ ki awọn araalu lọ fọkan balẹ pe ireti to ti sọnu yoo pada wa."

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Ta ni Tunde Bakare?

Wọn bi alufaa naa ni ọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun 1954, ọmọ ilu Abeokuta si ni.

Oun ni pasitọ agba ijọ Citadel Global Community Church.

Kii ṣe igba akọkọ ti Bakarea yoo gbiyanju lati dije du ipo Aarẹ Naijiria ree, amọ awọn igbiyanju naa lo fori ṣopan ṣaaju.

Lọdun 2011, Bakare ni oludijde sipo igbakeji Aarẹ Naijiria, ti Aarẹ Muhhamadu Buhari si du ipo Aarẹ lọdun naa lọhun, amọ wọn ko jaweolubori.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso